ENDSARS Protest: Akẹ́kọ̀ọ́ àti ọ̀gá iléèwé ń kérora torí ìdánwò NECO tó ṣún síwájú

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic
Awọn akẹẹkọ ati ọga ileewe to n kopa ninu idanwo NECO, ti ke gbajare sí ijọba lati wa ojutu si ọrọ iwọde ENDSARS to gbòde.
Ẹbẹ yii ko sẹyin bi ajọ onidanwo NECO ṣe sun ọjọ idanwo to n lọ lọwọ siwaju nitori iwọde ENDSARS.
Lọjọ Abamẹta ni NECO kede pe, idanwo Kọmputa to yẹ kó waye ni ọjọ Aje oni, ni ko le waye mọ, wọn si sun siwaju di ọjọ kẹrindinlogun oṣù Kọkànlá.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀rọ̀ ajé dẹnu kọ̀lẹ̀ yíká Nàíjíríà, àkẹ́kọ̀ọ́, olókoòwò àti òṣìṣẹ́ ọba jókòó sílé
- Ẹlẹ́wọ̀n 200 sálọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Benin lásìkò ìwọ́de EndSars
- Ìjọba da ológun sí Abuja láti dẹ́kun ìwọ́de
- Mo fura pé ẹ fẹ́ da Nàíjíríà rú, ń kò ṣe ìwọ́de mọ́ - Segalink, agbátẹrù ìwọ́de yọwọ́
- Ìwọ́de EndSARS gboró n‘Ibadan, kò sẹ́ni tó le wọlé tàbí jáde
- "Buhari, ìwọ́de yóò yíwọ́, tó gbá jẹ́ káwọn ológun bá bẹ̀rẹ̀ ‘Operation Crocodile Smile’ "
- Ìjọba Eko pàdánù ₦234m láàrín ọ̀sẹ̀ kan torí ìwọ́de End SARS
- Bí o bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tí yóò rọ́pò SARS, wo àmúyẹ tí o gbọ́dọ̀ ní
Ẹbẹ ni ki ẹ ba wa bẹ ijọba:
Olukọ ati oludari ile ẹkọ girama kan nilu Ibadan, ti BBC Yoruba ba sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Ọmọwe Ayoyinka Babatunde ni awọn ko le da awọn oluwọde lẹbi.
Ọmọwe Babatunde ni nitori ki ọjọ iwaju awọn akẹkọọ to n kọ idanwo lọwọ, baa le dara, ni wọn ṣe n se iwọde.
" Awọn to n ṣe iwọde ni ohun ti n won fi sun, ko si ohun to da ti ko ni idakeji nitori naa, ẹ ba wa bẹ ijọba ki wọn yanju ọrọ yii"

Oríṣun àwòrán, @Omojuwa
Amọ o wa woye pe isunsiwaju gbogbo igba yii ti mu irẹwẹsi ba ọkan olukọ ati akẹkọọ.
" Ijọba ko sọrọ, awọn oluwọde ko sọrọ nitori naa eleyi n ṣe ipalara nla fun idanwo NECO, ipalara nla ni iwọde n ṣe fun idanwo NECO"
O ni adura ati ọrọ iyanju láwọn n ṣe fawọn akẹkọọ nitori o ti ṣu ọpọ ninu wọn.
Ninu oro tirẹ, akẹkọọ kan Yinusa Mutiat, to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ De Ayo International college Ibadan, ni ki ijọba ṣe aanu fawọn, ki wọn ba le ṣe idanwo asejade lasiko.

Oríṣun àwòrán, @Equityoyo
Mutiat ni o ti ṣu oun lati maa reti ọjọ ti awọn yoo le kọ idanwo.
"Mo ti kawe kawe, o ti ṣu mi. Ẹ ba wa bẹ ijọba ki wọn dá àwọn oluwọde lohun"
Jakejado Naijiria ni iwọde ENDSARS ti n ṣe idiwọ fun lilọ bíbọ ọkọ nitori bi wọn ti ṣe di gbogbo oju ọna.
Nítorí iwọde yii, NECO ni awọn ko ribi ko iwe idanwo lọ bá awọn akẹkọọ to fẹ kọ idanwo naa.
Ṣaaju ni ajakalẹ arun Coronavirus ti ṣe akoba fun idanwo awọn akẹkọọ jade gírámà, ti wọn si sun lati oṣù kẹfà di oṣù Kẹwa.
Wo ohun tí ìwọ́de ENDSARS ṣé fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ ṣèdánwò NECO

Oríṣun àwòrán, The guardian nigeria
Ajọ idanwo aṣekagba ẹkọ girama lorilẹede Naijiria, NECO ti sun idanwo, rẹ siwaju nitori iwọde awọn ọdọ kaakiri orilẹede Naijiria to n lọ lọwọ.
Atẹjade kan ti alukoro ajọ naa, Azeez Sani fi sita lọjọ Aiku ṣalaye pe niwọn igba ti lilọ bibọ ọkọ ti n fara gba ninu iwọde to n lọ kaakiri naa o ti ṣe idiwọ pẹlu fun awọn igbesẹ lati ko awọn ohun elo idanwo kaakiri lọ si ibi gbogbo to yẹ.
O fi kun un pe wọn ti sun idanwo ẹkọ nipa kọmputer to yẹ ko waye ni ọjọ Aje ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹwa si ọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla.
Ìjọba Nàìjíríà ti kéde pé kí ilé ìtura ṣí padà, kí ìlé ìwé máa palẹ̀mọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, @GarShehu
Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti fi ọjọ kun isede coronavirus jakejado Naijiria.
Ẹ wo àwọn ilànà tuntun tí ìjọba Nàìjíríà kéde lẹ́yìn tó fi kún ìséde Covid-19
Ni bayii, dipo aago mẹwa alẹ si mẹrin idaji, aago mejila oru si mẹrin idaji ni isede yoo fi ma wa.
Ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2020 ni aarẹ kọkọ kede isede ni ipinlẹ Eko, Ogun ati ilu Abuja, nibi ti coronavirus ti kọkọ n gbilẹ.
Alaga igbimọ amuṣẹya fun amojuto coronavirus ni Naijiria, Sani Mustapha, lo kede aṣẹ tuntun yii lọjọbọ.
- Ìdí tí ìjóba ìpínlẹ̀ Eko fí ṣí àwọn ilé ìwé kan padà
- Ṣé Nàìjíríà lẹ́mìí nkan tí Ghana ń ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ "Secondary" tí yóò wọlé ní October yìí?
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ tí ìdánwò NECO, NABTEB àti BECE yóò bẹ̀rẹ̀
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
O ṣalaye pe anfaani ti wa fun awọn ile sinima, ibudo ti wọn ti n sẹ ere idaraya, ati awọn ibudo faaji to ku, lati bẹrẹ isẹ pada.
Bakan naa lo sọ pe awọn ileewe le ma a mura silẹ fun wiwọle pada.
Musatpha sọ pe kọkọrọ kan to ba eyin aja jẹ ni awọn ti ko tẹle ilana ijọba fun aarun Covid-19.
Ẹ wo àwọn ilànà tuntun tí ìjọba Nàìjíríà kéde lẹ́yìn tó fi kún ìséde Covid-19

Oríṣun àwòrán, @Buhari
Awọn nkan to tun wa ninu aṣẹ tuntun ti ijọba kede
- Awọn ile itura ti le ṣi ilẹkun wọn
- Ile sinima, ibi ti wọn ti n ṣe ere idaraya le ṣi pada, ṣugbọn ero wọn ko gbọdọ ju ida aadọta lọ
- Awọn gbọngan ayẹyẹ le ṣi pada, ṣugbọn ko gbọdọ ju ida aadọta lọ
- Awọn ile ounjẹ ko gbọdọ gba ki ẹnikẹni joko jẹun lọdọ wọn
- Awọn ile ọti ati ile ijo ko gbọdọ ṣilẹkun
- Ajọ NYSC yoo bẹrẹ imurasilẹ fun igba ti awọn ileewe yoo di ṣiṣi pada
- Ajọ INEC yoo ri daju pe o tẹle ilana lori coronavirus- ẹni ti ko ba lo ibomu ko gbọdọ dibo.
- Bakan naa ni wọn o tun ma a ṣe ayẹwo bi ara awọn eeyan ṣe gbona si, lo sanitaisa, ati titakete sira ẹni.















