EndSars Protest: Ìjọba àpapọ̀ ní ká ṣọ́ra fún ìpéjọ èrò àti àlejò láti Amẹrika, UK, India, Rusia ati France

end sars

Oríṣun àwòrán, @kabenny_

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbimọ amusẹya ti Aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ lori ajakalẹ arun Covid-19, PTF, ti kilọ fun awọn oluwọde End SARS, lati ṣọra ṣe nitori itankalẹ arun naa ninu iwọde wọn.

Bakan naa lo tun kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra fun gbigba alejo tabi ṣiṣe abẹwo si awọn orilẹ-ede bii Amẹrika, ilẹ Gẹẹsi, India, Rusia ati France.

Oludari agba PTF, Sani Aliyu lo kede bẹẹ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aliyu sọ pe "A ti n fimu finlẹ lori ipa ti iwọde to n lọ lọwọ le ni lori iburẹkẹ ajakalẹ arun Covid-19, a si ti n woye bi a ṣe maa ṣe ayẹwo."

Awọn ọdọ to n se iwọde

"A o tẹsiwaju lati maa kilọ fun fun awọn eeyan lati ṣọra ṣe, nitori apejọpọ elero pupọ lee jẹ ki ajakalẹ arun ọhun burẹkẹ sii.

Dokita naa ni kii ṣe ohun to bojumu ki awọn eeyan jade lọ sita lati ko arun ba awọn mọlẹbi ti wọn fi silẹ ninu ile.

Nigba to n da si ọrọ naa, alaga igbimọ amuṣeya naa, to tun jẹ akọwe ijọba Naijiria, Boss Mustapha sọ pe, o yẹ ki awọn eeyan ṣora fun apejọpọ elero pupọ nitori Covid-19 ṣi wa lode.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

O ni "A rọ gbogbo awọn to ti kopa ninu ipejọpọ elero pupọ tabi ti wọn ba n ṣafihan apẹrẹ Covid-19 lati lọ ṣayẹwo."

Mustapha fi kun pe akoko ti to fun awọn olufẹhonuhan lati ba ijọba ni ijiroro nitori ewu to wa ninu iwọde elero pupọ.

O pari ọrọ rẹ pe ki awọn eeyan ṣora fun orilẹ-ede France ati ilẹ Gẹẹsi lasiko yii nitori awọn orilẹ-ede naa ni Covid-19 ti burẹkẹ ju ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2020 yii.

Àwọn ọlọ́pàà yin afẹ́fẹ́ gáàsì #EndSARS lu àwọn olùwọ́de ní Abuja

ABUJA

Oríṣun àwòrán, Channels

Ọlọpaa nipinlẹ Abuja ti fin tajutaju si awọn afẹhọnuhan #EndSars ni ilu Abuja loju.

Awọn afẹhọnuhan naa n beere opin si ifiyajẹni awọn ọlọpaa lagbegbe John Kennedy nibi ti wọn ti n wọde ni ayika Ile aarẹ.

Awọn ọlọpaa naa fin tajutaju lọna ati tu awọn afẹhọnuhan to pejọ si Power House ni Asokoro ka ni Ọjọ Aje.

ABUJA

Oríṣun àwòrán, Channels

Ki eleyii to waye ni awọn sọja ti kọkọ di ọna to wa ni Aya ni ilu Abuja, ki awọn afẹhọnuhan naa ma ba a kọja.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa to wa ni iwaju banki apapọ Naijiria naa wa nibẹ ni pẹsẹpẹsẹ lati koju awọn oluwọde naa.

Ìjọba da ológun sí Abuja láti dẹ́kun ìwọ́de

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti kede pe ijọba apapọ ti fi awọn ọmọ ologun ransẹ si igboro ilu Abuja lati dẹkun iwọde EndSARS to n lọ lọwọ.

Bakan naa, awọn ọmọ ologun yii ni wọn ti pasẹ fun lati mu awọn eeyan to n sewọde yii si ahamọ.

Awọn ologun n da ọkọ duro

Oríṣun àwòrán, Channel

Iroyin naa ni iwọde naa ti n gbọna miran yọ, to si seese ko jẹ pe awọn janduku ti gba akoso iwọde ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin kan tiẹ ni wọn gun ọkan lara awọn oluwọde ni ọbẹ, to si ku sile iwosan.

Awọn ologun n da ọkọ duro

Oríṣun àwòrán, Channel

Koda, awọn afẹhonu han ọhun la gbọ pe wọn ti gbe igi da sna to wọ papakọ ofurufu ilu Abuja, tawọn arinrin ajo ko si le wọ baalu.

Ìwọ́de EndSARS gboró n'Ibadan, kò sẹ́ni tó le wọlé tàbí jáde

Ibadan

Awọn afẹhọnu fun opin ifiyajẹni ati iṣekupani awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria, ti ti gbogbo opopona to wọ ilu ibadan ni ipinlẹ Oyo pa.

Akọroyin BBC Yoruba to wa ni ibi ifẹhọnuhan naa fi lede pe, gbogbo ọna to wa ni agbegbe Challenge, New Garage ati Tipper Garage ni awọn ọdọ to n sewọde, ti tipa patapata.

Awọn ọdọ naa ko jẹki ọkọ lọ tabi ki wọn kọja lọ si ibi kankan, oju kan naa ni gbogbo wọn fi ọkọ wọn silẹ loju popo.

Bakan naa ni awọn ọlọkada naa fi ọkada wọn di oju ọna, ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni kọja.

IBADAN

Awọn sọọbu naa wa ni titipa ni awọn agbegbe wọnyii, ti awọn afẹhọnuhan naa si gbe tabili wọn, to fi mọ awọn ohun elo mii lati fi ṣe ifẹhọnuhan.

IBADAN

''Gbogbo ọna to wọ agbegbe Challenge, Orita, Toll gate ati New Garrage ilu Ibadan ni awọn ọdọ to n ṣe ifẹhonuhan #ENDSARS ti di pa lati owurọ oni, lilọbibọ ọkọ si ti dawọ duro pẹlu.''

IBADAN

''Ati ero inu ọkọ, ati ẹni to gun ọkada lo n bọọlẹ ti wọn si n fi ẹsẹ wọn rin lọ si ibi ti wọn n lọ.''

Ibadan

Bakan naa ni Ọjọ Aiku, awọn ọdọ ni aimoye wọn jade lati sẹwọde pẹlu adura fun odidi wakati mẹta, ti wọn si n bẹbẹ si Olorun pe ki ayipada ba orilẹede Naijira.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Ninu awọn akọle ti wọn gbe dani sọ wi pe orilẹede Naijiria nilo adura, nitori oogun ti ohun n ja Naijiria kii ṣe oju lasan mọ.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Awọn ọdọ naa tẹnumọ wipe ninu adura ni awọn yoo ti sọrọ soke ki ayipada le deba orilẹede Naijiria.

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 4