EndSARS Protest Update: Ẹgbẹ́ àgbà Yorùbá ní ọwọ́ alágbarà ẹ̀yìn odi ló wà nídi ìkọlù tó wáyé l'Eko

Oríṣun àwòrán, @_el_aaameen/via reuters
Aṣiwaju ẹgbẹ Yoruba lagbaye, Yoruba World Congress, YWC, Alagba Banji Akintoye, ti koro oju si bi aarẹ Muhammadu Buhari ṣe foju rena iṣẹlẹ to waye ni Lekki.
O wa ṣapejuwe bi awọn ologun se kọju ibọn sawọn ọdọ to n sewọde ni Lekki Eko gẹgẹ bi ikọlu si ilẹ Yoruba.
O ni bi aarẹ Buhari ṣe dakẹ lori iṣẹlẹ naa fihan pe iṣẹlẹ naa lọwọ kan awọn araata ninu lati da oju ilẹ Yoruba de'lẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọba tí wọ́n bá gbé ọ̀pá àṣẹ rẹ̀ lọ nílẹ̀ Yorùbá
- ₦147m la rí kójọ fún ìwọ́de, a kò fẹ́ owó mọ́, ìwọ́de ti parí - Feminist Coalition
- Wo ìròyìn, àwòrán àti fídíò èké nípa ìwọ́de EndSARS
- Super Eagles, ẹ máṣe gbá bọ́ọ̀lù fún Nàìjíríà mọ́ nítorí ìhà tí ìjọba kọ sí ìwọ́de EndSARS - John Ogu
- Ará Eko, ẹ pariwo ó tó gẹ́ẹ́ lórí làásìgbò tó gbòde torí ìwọ́de EndSARS - Sanwo-Olu
- Ọ̀tá Yorùbá ló lo ìwọ́de láti dojú ogun kọ wá - OPC
- "Àwọn ọ̀tá Nàíjíríà tó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS"
- Ó parí ni ohùn tó gbẹnu ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Buhari
Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti, Akintoye ni asiko wa to bayii ki ajọ iṣọkan agbaye, ajọ orilẹede Yuroopu, ajọ iṣọkan ilẹ Afirika, AU, orilẹede Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi, lati dide wa fun atunto asopọ Naijiria ti wọn ṣe ni ọdun 1914.

Oríṣun àwòrán, EPA
Atẹjade naa, to fi sita lẹyin ipade ẹgbẹ naa lowurọ ọjọ Ẹti, aarẹ ẹgbẹ YWC ni o kọ ni lominu pe, awọn ikọlu to waye fun wakati mejidinlaadọta laidakẹ, lee waye ni Naijiria yii, lai si pe ijọba ka awọn to n ṣiṣẹ laabi naa lọwọ ko.
O ni ọrọ ti aarẹ ba awọn ọmọ Naijiria sọ ko jọ bi eyi to ti inu ọkan rẹ wa, afi bii pe n ṣe ni wọn kan an nipa fun un.
Ọ̀tá Yorùbá ló lo ìwọ́de láti dojú ogun kọ wá - OPC
Ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC, ti bu ẹnu ẹtẹ lu bi awọn ọmọ ologun Naijiria ṣe ṣina ìbọn fun awọn ọdọ to ṣe iwọde#ENDSARS ni Lekki nipinlẹ Eko.
Alẹ ọjọ Iṣẹgun ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti àwọn ọdọ naa ti n ṣe iwọde kaakiri Naijiria pe ki ijọba fi opin si aṣilo agbara awọn ọlọpaa.
Ninu ọrọ ti ẹgbẹ OPC sọ, o kilọ fun awọn janduku to n lo anfaani rogbodiyan to waye ọhun lati ma a fi ja ole, to si tun n ba dukia ijọba jẹ, lati mase ṣọ Iwọ-oorun Gusu Naijiria di ibudo ogun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Àwọn ọ̀tá Nàíjíríà tó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS"
- Ó parí ni ohùn tó gbẹnu ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Buhari
- Ìwọ́de EndSARS kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ara ti kan àwọn èèyàn ni - Afenifere
- Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka
- Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
Akọwe ẹgbẹ naa, Amofin Yinka Oguntimehin, to fi atẹjade sita lorukọ ẹgbẹ sọ pe "iwa ẹranko gba a ni iṣẹlẹ to waye ni Lekki".
O ni "o han gbangba pe awọn ọta Iwọ-oorun Gusu Naijiria, to jẹ ilẹ Yoruba, lo awọn iwọde alaafia to waye naa, lati doju ogun kọ ẹkùn naa".

Oríṣun àwòrán, Twitter/Oluwaseunfunmi
O fi kun ọrọ rẹ pe, labẹ isejọba ologun ti oloogbe Sani Abacha dari, ni nkan ti ri bayii ni Naijiria kẹhin.
Bakan naa lo rawọ ẹbẹ si ajọ agbaye, United Nations, lati finna mọ ijọba Naijiria, ko le ṣe iwadii iṣẹlẹ naa.
"O jẹ ibanujẹ pe ijọba apapọ kuna lati dahun ibeere awọn oluwọde naa, eyi to mu ki iwọde alalaafia di itajẹ silẹ, didana sun dukia ati kiko sọọbu awọn eeyan.
" Mo tun n sọ ọ lẹẹkan si pe, ki ijọba apapọ dẹ́kun titan awọn oluwọde to n fi ẹ̀mí wọn wewu lati beere fun igbe aye idẹrun.

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
O ni iru igbesẹ bẹẹ yoo koba irufẹ ijọba bẹ ẹ to jẹ pe ara ilu lo dibo yan an sipo, paapa nilẹ Iwọ-oorun Gusu Naijiria ."
O ni oun kẹdun pẹlu awọn ẹbi oluwọde to ku sinu iṣẹlẹ naa, o si gboriyin fun awọn ọdọ Naijiria fun bi wọn ṣe" fi igboya ati iduro ṣinṣin polongo fun àtúnṣe nileesẹ ọlọpaa, ti aisi isejọba gidi ba jẹ".
Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adoration Ministry Enugu
Ojisẹ Ọlọrun kan ninu ijọ Aguda, Fada Ejike Mbaka ti sọrọ lori iwọde EndSARS, to si ni ipo ti awọn ọdọ wa ni Naijiria ko dara rara.
Mbaka, ninu fidio kan to fi soju opo Facebook ijọ rẹ, Adoration Ministry, ni ọpọ igba loun ti maa n ke sawọn ọdọ lati taji loju oorun wọn.
O ni ti ajaga ba ti wuwo ju bose yẹ lọ, ti ko si se fara da mọ, awọn eeyan yoo ja lati bọ ninu rẹ, pẹlu afikun pe, igbe aye awọn ọdọ Naijiria ko wu ni lori rara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
- Wo díẹ̀ lára dúkìá tí jàǹdùkú sun níná l‘Eko torí ìwọ́de EndSARS
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- "Jàǹdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfò la wà"
- Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
Ojisẹ Ọlọrun naa ni kii ẹbi Buhari ni awọn isẹlẹ to n waye yii, nitori ko to de ipo ni atako sawọn ọlọpaa SARS ti n waye, paapaa lati aye awọn ijọba to ti kogba wọle.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adoration Ministry Enugu
"SARS kọ ni isoro kansoso taa ni, lẹyin isoro SARS yii, awọn isoro wa yoo si maa tẹsiwaju, abi bawo ni awọn ọdọ ko se ni risẹ oojọ se.
Awọn Sẹnatọ wa n joko le aimọye biliọnu naira, bo si se wa ree lati ọjọ ti alaye ti daye, eyi si kọja ọrọ Buhari."
Mbaka wa gbe imọran kalẹ pe ohun to yẹ ko jẹ wa logun bayii ni eto ti Naijiria ni fawọn ọdọ rẹ ati ipese awọn ohun eelo amayederun.
O ni ọpọ awọn oju popo wa ni ko se rin nitori koto ati gegele, ta ba si ni ka maa pariwo nikan ni, ariwo laa pa titi ti ewu yoo fi hu lori wa, sugbọn awọn ọdọ ko gbọdọ dakẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adoration Ministry Enugu
Ojisẹ Ọlọrun naa tun salaye pe ibeere to yẹ ka maa bi awọn asaaju wa ni pe ki ni wọn n fi owo epo wa se, se wọn kan fi n ra dukia silu Dubai ni.
O ni ẹtahoro ọmọ Naijiria lo n na owo wa, ti eyi ba si tẹsiwaju, ewu si n bẹ loko longẹ.
Àwọn oníjàgídíjàgan kọlu aàfin Oba ìlú Eko àti iléesẹ́ ìròyìn LTV

Oríṣun àwòrán, LAGOS STATE GOVERNMENT
Àwọn oníjàgídìjágan kọlu aafin Oba ìlú Eko àti iléesẹ́ ìròyìn LTV
Ileeṣẹ iroyin ipinlẹ Eko ti wa ni titi pa bayii lẹyin ti awọn onijagidijagan yabo ileeṣẹ naa.
Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ni ijọba ti fun awọn laṣẹ lati kuro ni agbegbe naa, ti wọn ko si si ni ori afẹfẹ lọwọlọwọ bayii.
Ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni awọn onijagidijagan naa ṣekọlu si awọn ileeṣẹ naa, ti wọn si ba awọn ohun ini wọn jẹ.
O fikun pe ileeṣẹ iroyin LTV, Eko FM, Traffic Radio, ati Radio Lagos ni wọn ti tipa bayii lati dẹkun biba awọn ohun ini awon eniyan jẹ ati ti ijọba.
Bakan naa ni wọn yabo aafin ọba ilu Eko to wa ni agbegbe Iga Idugaran, ni agbegbe Lagos Island, nibi ti wọn ti n ba awọn ọkọ ati dukia jẹ.
Aworan fidio to n ja ranyin kaakiri ṣe afihan awọn onijanduku ti wọn gbe ọpa aṣẹ ọba naa, ti wọn si n salọ.
Olugbe agbegbe Lagos Island sọ wi pe awọn to ṣekọlu si ile iya gomina Sanwo-Olu naa lo ṣekọlu si ile ọba naa.
''Nigba ti awọn janduku naa n lọ si ile baba Sanwo-Olu, awọn ọlọpaa ko wọn lọna, ti wọn si yinbọn fun wọn, amọ wọn bori awọn ọlọpaa naa, ti wọn si salọ fun wọn.
Eleyii lo mu wọn lọ si ile Oba ilu Eko, ti wọn si yabo ibẹ pe ọba naa pẹlu ijọba, nitori awọn ileeṣẹ ijọba ni awọn n ṣekọlu si.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Aisha Buhari polongo àwo orin tó ní Nàíjíríà ń ṣun ẹ̀jẹ̀ lásìkò ìwọ́de
EndSars: Aisha Buhari kígbe kí ìjọba gba àwọn ará Àríwá lọ́wọ́ ètò ààbò tó mẹ́hẹ
Iyawo aarẹ Naijiria, Aisha Buhari ti kesi ijọba lati gbe igbesẹ ni kiakia, nidi ipese eto aabo to mẹhẹ ni ẹkun iwọ oorun Ariwa orilẹede yii.
Aisha Buhari se ikede naa loju opo Facebook rẹ, lẹyin ti awọn ọdọ yika Naijiria fariga pe, ifiyajẹni ati iṣekupani lọwọ awọn ọlọpaa gbọdọ dopin ni Naijiria.
Iyawo aarẹ Buhari se eyi nipa fi fi ara awo orin ti oṣere tiata kan lede Hausa, Adam Zango gbe jade soju opo Twitter rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Láàrin wákàtí mẹ́ta, wọ́n dá ₦4m fún àkàndá ẹ̀dá tó kópa nínú ìwọ́de
- 2015 ni mo ti ń kígbe pé gudugbẹ̀ máa já ní Nàíjíríà - Oyedepo
- Lizzy anjorin ń kiri àgọ́ ọlọ́pàá láti gba àwọn ọ̀dọ́ afẹ̀hónúhàn, tó wà láhàámọ́ sílẹ̀
- Àwọn ọ̀dọ́ se ìrẹsì jọ̀lọ̀ọ́fù ní márosẹ̀ Benin sí Ore láti fẹ̀hónú hàn
- Afárá Marina àti Eko yóò di ṣíṣí padà lọ́la
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ 'Operation Crocodile Smile' yíká Naijiria fún oṣù méjì
Akọle awo orin naa ni "Arewa na kuka", eleyii to tun mọ si pe ''Ariwa Naijiria n sun ẹkun''.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Pẹlu orin naa ni Aisha Buhari kọ atẹjade to fi pe fun ki opin de ba eto aabo to dẹnukọlẹ ni Ariwa orilẹede Niajiria naa.
Pẹlu Hashtag, ti iyawo aarẹ kọ ni ede Hausa, to si pe ni "#AChechijamaa", eyi to tunmọ si ipe fun itusilẹ awọn eniyan.
Igba akọkọ kọ ni yii ti Aisha Buhari yoo sọrọ tako isejọba ọkọ rẹ, nitori bi ilana isejọba aarẹ naa ko mu idagbasoke ba orilẹede Naijiria.
Fidio orin naa lo ṣe afihan aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammed Buhari, nibi ti o ti n ṣe ipade pẹlu awọn adari eto aabo lorilẹede Naijiria.
Lara awọn ohun ti orin naa sọ ni pe:
''Ni orukọ Olorun, a bẹyin ki ẹ tẹti silẹ si awọn eniyan yin, a nilo iranlọwọ, Ariwa orilẹede Naijiria n sunkun/ Ẹjẹ ti wọn ta silẹ, awọn eniyan n ku/dukia si n bajẹ.''
Ikọ Agbẹsunmọmi Boko Haram ti pa ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan ni Ariwa orilẹede Naijiria, ti ọpọlọpọ si ti di alairile gbe.
Fun igba diẹ bayii, ni awọn ọdọ ti bẹrẹ si ni ṣe ifẹhọnuhan kaakiri orilẹede Niajiria, lati tako iṣekupani ojoojumọ lati ọwọ awọn ọlọpaa Niajiria paapaa ikọ SARS.
Bakan naa ni ijọba fi lede wi pe, awọn ti tu ikọ SARS naa ka, ti wọn si gbe ikọ ọlọpaa SWAT dide lati koju iwa ọdaran lawujọ.
Amọ, awọn ọdọ lorilẹede Naijira ni irọ ni igbeṣẹ ijọba, nitorinaa awọn kọ ikọ SWAT kaakiri Naijiria.















