EndSARS Protest Update: Aisha Yesufu ní Buhari jẹ́wọ́ pé òun kò láànú aráàlú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀

Aisha Yesufu

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Usman

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 12

Ọkan lara awọn oju to gbajumọ julọ lasiko iwọde #EndSARS, Aisha Yesufu ti ṣe apejuwe aarẹ Muhammadu Buhari, gẹgẹ bi aṣiwaju ti ko laanu ọmọ Naijiria loju.

Aisha Yesufu sọrọ yii loju opo Twitter rẹ, nigba to n sọrọ lori ọrọ apilẹkọ ti aarẹ Muhammadu Buhari ba awọn ọmọ Naijiria sọ lalẹ Ọjọbọ.

Buhari sọrọ naa lẹyin wakati mejidinlaadọta ti iroyin sọ pe, awọn ọmọogun kan lọ ṣina ibọn bolẹ fawọn oluwọde lagbegbe Lekki nilu Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni o ṣeni laanu pe aarẹ Buhari "ko laanu awọn ọmọ Naijiria ti wọn pa."

Aworan nkan tawọn ọdọ Naijira fẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ni ibanujẹ nla lo jẹ pe aarẹ lee ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lai darukọ awọn eeyan ti wọn pa kaakiri orilẹede Naijiria lasiko iwọde naa.

O fi ẹsun kan ijọba pe, awọn gan an lo ko awọn tọọgi wọ inu iwọde naa, bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba ti ṣalape lọpọ igba pe, ko sootọ kan ninu ọrọ bẹẹ.

O fi kun un pe, ohun to dun mọ oun ninu julọ lasiko iwọde naa ni pe, awọn ọdọ ti ri okun ati agbara lati sọrọ soke, wọn si ti n sọrọ soke bayii.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

"O fihan pe awọn ọdọ Naijiria ti dide, wọn ti ṣetan pẹlu itara ọkan pe ohun gidi yoo ti ara rẹ jade wa.

Aworan nkan tawọn ọdọ Naijira fẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

O si ti han gbangba bayii pe ọwọ araalu ni agbara wa."

O ni oun ko si lara awọn to gbe iwọde naa kalẹ tabi ṣiwaju rẹ, oun kan lo anfani ti oun ni lati fi ṣe koriya fun awọn ọdọ naa ni.

Ǹkan kò bá má burú tó báyìí ká ní Aàre Buhari tètè bá àwọn ọmọ Nàìjíríà- PDP

aṣia PDP ati APC

Oríṣun àwòrán, Pdp/apc

Egbe oselu PDP lorileede Naijiria ti ni aare Buhari to dake lo fa rogbodiyan to gbode kan lorileede Naijiria.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn soja ṣe da ibọn bo awọn afẹhọnuhan ni agbegbe Lekki, ni ilu Eko lasiko ti wọn ṣe ifẹhọnuhan lọwọọwọ tako ifiyajẹni awọn ọlọpaa.

Akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade ti ẹgbẹ oṣelu naa fi lede.

Ologbondiyan ni aiṣoro Aarẹ Buhari burujai nitori oun ni ọgagun orilẹede Naijiria, ti gbogbo aṣẹ si wa ni ọdọ rẹ.

''Ọrọ ti Aarẹ Buhari ba sọ yoo fi ọkan awọn eniyan balẹ, eleyii ti aarẹ fi faye gba ipaniyan ati biba dukia awọn eniyan jẹ.''

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

Ologbodiyan ni: 'Ibanujẹ lo jẹ fun wa lati ri orilẹede to wa ni iṣọkan nigba ti Aarẹ Buhari gba ijọba, ti wa da yẹpẹyẹpẹ bayii, ti wọn si bẹrẹ si ni pa awọn eniyan.''

'' Ni ilu to lofin, to si ni Aarẹ to jọju, wọn yoo ti ba awọn eniyan sọrọ lati le tu wọn ninu lasiko rogbodiyan yii, amọ aarẹ ati igbakeji dakẹ, ti wọn si n woran.

Ẹgbẹ oṣelu PDP fikun pe fidio to safihan awọn ọkọ ijọba ti wọn fi n ko awọn madaru fihan pe ijọba lọwọ si rogbodiyan to n ṣẹlẹ kaakiri ipinlẹ Eko ati Naijiria lapapọ.

Bakan naa ni wọn kesi ijọba aarẹ Buhari lati gba wi pe awọn lo fa rogbodiyan to n ṣẹlẹ lorilẹede Naijria, ki wọn si ṣe ojuṣe wọn fun awọn eniyan.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP naa ba awọn eniyan kẹdun, ti wọn si gbadura fun awọn eniyan to sọ ẹbi ati ara nu ninu iṣẹlẹ naa, ki Olọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere

PDP si fikun wi pe awọn yoo ṣe ohun gbogbo to wa ni ikawọ awọn lati ri wi pe ajọ lorilẹede lagbaye dide si iṣẹlẹ Naijiria, ki alaafia ati oṣelu tiwantiwa le pada sipo ni Naijiria.

SARS

Oríṣun àwòrán, @Auntyadaa

Ohun tí ojú ìyàwó mi rí lọ́wọ́ SARS kò ṣe é fẹnusọ- Poju Oyemade

Awọn òṣìṣẹ́ SARS ti fi panpẹ́ òfin mú ìyàwó mi rí láì nídìí- Poju Oyemade

Oluṣọ agutan agba ijọ Covenant Christian Centre, Poju Oyemade ti ṣalaye ohun ti oju iyawo rẹ ri lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ SARS ki ijọba apapọ to tu wọn ka lẹyin iwọde End SARS.

Oyemade sọ pe awọn agbofinro naa fi panpẹ ofin mu iyawo oun, Toyin, lọdun 2019 lai si idi kan pato.

Gẹgẹ bo ṣe sọ pe ọpẹlọpe pe oun jẹ gbajumọ lawujọ lo jẹ ki wọn fi obinrin naa silẹ, anfaani iru eyii ti ọpọ awọn ọdọ Naijiria miran ko ni, eyii to mu ki wọn maa jiya ẹṣẹ ti wọn ko ṣẹ.

Oyemade lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ, nibi to ti rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati fi imu awọn agbofinro ti aje iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori fọn feere.

Pasitọ naa ṣalaye pe "Ẹ jẹ ki n bẹrẹ pẹlu iriri temi tikalara mi lọwọ awọn oṣiṣẹ SARS, ninu ọdun to kọja ni iyawo mi pe mi pe awọn ọlọpaa ti mu oun, oun si ti wa ni agọ wọn."

Poju Oyemade

Oríṣun àwòrán, @NewsOvert

"Mo n lọ sibi ipade kan lọjọ naa ni, ṣugbọn mo tete tẹkọ leti lọ si agọ awọn ọlọpaa ọhun, ti mo si ri pe ohun ti wọn mu iyawo mi fun ko lẹsẹ nilẹ titi di oni yii."

Oyemade ni iyi ati ẹyẹ ti awọn eeyan fi n ki ohun ni agọ naa lo jẹ ki oun tete ri iyawo oun yọ ninu ahamọ ti wọn fi si.

Pasitọ naa sọ pe kii ṣe ẹbi awọn ọdọ to n gunle iwọde End SARS nitori ohun ti oju wọn n ri lọwọ awọn ọlọpaa ko ṣee fẹnusọ.

O ti lé ni ọsẹ kan ti awọn ọdọ naijiria ti gunlẹ iwọde End SARS, eyii ti wọn fi n bere fun opin si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale, SARS.

Iwọde naa ti mu ki ijọba apapọ tu ẹka naa ka, to si ṣagbekalẹ ẹka tuntun miran to pe ni SWAT, ṣugbọn awọn ọdọ naa ni ko tẹ wọn lọrun.

Àkọlé fídíò, End SARS, End SWAT: Ó pé mi bí SARS kò ṣe sọ mí dolówọ́- Fulani Kwajafa

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

SWAT Police: Wo bí ikọ̀ ọlọ́pàá Special Weapons and Tactics yóò ṣe má a ṣiṣẹ́ wọn

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe ko ni si ẹnikẹni lara awọn ọlọpaa SARS ti wọn ṣẹṣẹ tuka ninu awọn ti yoo wa ninu SWAT ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ lọjọ kẹtala, oṣu Kẹwa.

Eyi jẹyọ ninu ikede ti ileeọẹ ọlọpaa fi sita nipa bi iṣẹ ẹka SWAT yoo sẹ ri.

Ọga agba awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, NPF

Nkan pataki marun-un nipa SWAT to yẹ ki o mọ

Ọmọ ikọ SARS kankan ko ni i si ninu SWAT

Iṣẹ ikọ SWAT ni lati ṣe akojọpọ akọsilẹ nipa eto aabo

Awọn ọmọ ikọ SWAT ko ni aṣẹ tabi ẹtọ lati yẹ foonu, kọmputa agbeletan 'laptop' ati awọn ẹrọ ayarabiaṣa igbalode, ẹnikẹni wo lọna aitọ.

Wọn ko si ni i ma lọ kaakiri igboro.

Awọn to wa ninu ikọ SWAT ko gbọdọ lọwọ ninu iwa ọdaran, paapa eyi to ni i ṣe pẹlu lilo ibọn bi ko ṣe yẹ, tabi titẹ ẹtọ ọmọniyan loju.

Bawo ni ikọ SWAT yoo ṣe ma a ṣiṣẹ?

Ilana iṣẹ mẹrin ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe sita fun awọn ọlọpaa ti yoo wa ninu ajọ SWAT

Wọn yoo ma a gbogun ti idigunjale, ijinigbe

Awọn ọmọ ikọ yii ni agbara lati lọ sibikibi ti iwa ọdaran ba ti n waye pẹlu ohun ija oloro

Iṣẹ idoola ni ojuṣe wsn kẹta

Eyi to kẹhin ni akanṣe iṣẹ, to ni i ṣe pẹlu awọn iwa ọdaran to lagbara pupọ.

Àkọlé fídíò, Àwọn jàndùkú ṣe yabò àwọn olùwọ́de #ENDSARS ní Alausa l'Eko

Wo ìlànà ìgbani síṣẹ́ márùn-ún fún àwọn ọlọ́pàá SWAT tó rọ́pò SARS

Ọjọ Aje ni Ọga Agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Adamu Muhammad kede ikọ ọlọpaa tuntun Speacial Weapons and Tactics (SWAT) lati rọpo ikọ ọlọpaa Special Anti-Robbery Squad ,SARS, ti wọn tuka.

Bo tilẹ jẹ pe ikọ tuntun naa tun ti fa awuyewuye laarin awọn ọmọ Naijiria, diẹ re e lara eto ti yoo waye ki wọn o to o le gba ẹnikẹni si iṣẹ ninu ikọ ọlọpaa SWAT:

1. Awọn ti yoo ba di ọlọpaa SWAT yoo lọ fun ayẹwo ilera ọpọlọ ati ilera ara wọn, lati le mọ bi wọn ṣe pojuowo si fun isẹ tuntun naa.

2. Ọsẹ to n bọ ni awọn ọmọ ikọ SWAT yii yoo bẹrẹ idanilẹkọ, ni awọn ile ẹkọṣẹ ọlọpaa kaakri Naijiria.

Àkọlé fídíò, Sotitobire: Ọkọ mi kò mọ̀ Jegede PDP rí, kódà kò fa ẹnikẹ́ni kalẹ̀ dípò Akeredolu- Bisola

Bi idanilẹkọ naa yoo ṣe ti niyii:

  • Awọn ọlọpaa lati ẹkun Ila oorun Gusu ati Gusu-Gusu Naijiria yoo gba idanilẹkọ ti wọn ni Counter Terrorism College, to wa ni Nonwa-Tai, ipinlẹ Rivers.
  • Awọn ọlọpaa to wa ni ẹkun Ariwa yoo ṣe ti wọn ni Police Mobile Force Training College, Ende, nipinlẹ Nasarawa.
  • Awọn to wa ni Iwọ oorun Gusu yoo gba idanilẹkọ ni Police Force Training College, Ila-Orangun, nipinlẹ Ọṣun.

3. Ọga Agba ọlọpaa tun paṣẹ fun gbogbo awọn ọlọpaa SARS ti wọn tuka, lati wa si olu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Abuja, fun ayẹwo ilera ara ati ọpọlọ wọn.

4. Ayẹwo naa yoo waye labẹ amojuto igbimọ oludanilẹkọ - Police Counselling and Support Unit (PCSU. Igbimọ yii ni yoo ma a mojuto idanilẹkọ, atilẹyin ati imọra fun awọn ọlọpaa to ba n ṣe akaṣe iṣẹ.

5. Awọn onimọ nipa ilera ọpọlọ, eleto ilera, pasitọ ati imaamu, ara ilu, ati awọn ajafẹtọ ọmọniyan, ni yoo wa ninu igbimọ naa.

SWAT

Oríṣun àwòrán, @google

SWAT ni orúkọ tuntun ti SARS yóò máa jẹ́- IGP Adamu

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijira ti ni ki awọn oṣiṣẹ SARS ti wọn tuka yọju si Abuja lati wa ṣe ayẹwo ọpọlọ ṣaaju ki wọn to pin wọn si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa mii.

Ikede yi to wa lati ọfiisi ọga agba ọlọpaa, Muhammad Adamu ṣalaye pe wọn ti ṣe agbekalẹ ikọ tuntun ti yoo rọpo SARS.

Orukọ ti wọn yoo maa pe ni Special Weapons and Tactics (SWAT).

Ikọ tuntun yi ni yoo gba iṣẹ SARS ti wọn tọkaabuku si laipẹ yi to si fa ifẹhonuhan loriṣiiriṣii

Adamu ni gbogbo awọn ti yoo ba gba iṣẹ labẹ ikọ yi yoo ni lati ṣe ayẹwo ọpọlọ ti wọn yoo si bẹrẹ igbaradi ni ọṣẹ to n bọ.

O ni ikọ alayẹwo arun ọpọlọ yoo maa ṣe iranwọ fawọn ti yoo ba gba iṣẹ labẹ SWAT.

Àkọlé fídíò, EndSars, EndSwat: Ọlọ́pàá ti fi ìbọn lù mí láyà rí torí mó ní 'extra tyre' méjì- afẹ́hònúh

Ṣaaju nijọba orile-ede Naijiria ti juwọle fawọn afẹhonuhan ENDSARS nipa gbigba lati mu awọn ẹdun nkan marun un ti wọn lawọn fẹ lọkunkundun.

Lọjọ Iṣẹgun ni ikede yi jẹ yọ lati ọdọ Femi Adesina oludamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari.

Ninu atẹjade naa, o ṣalaye pe lẹyin ipade awọn ajafẹtọmọniyan pẹlu ọga ọlọpaa ati ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ọlọpaa ni wọn pinnu lati ṣamuṣẹ ohun tawọn oluwọde n beere.

Lara ohun ti ipade naa ni ki wọn ṣe ni kiakia lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa tu SARS ka ni:

  • Mimu opin ba lilo ipa lati koju awọn oluwọde
  • Titu gbogbo awọn ti ọlọpaa ba mu lori iwọde silẹ ni kiakia
  • Ṣiṣi oju opo ibaraẹnisọrọ laarin ọlọpaa ati ara ilu ki wọn ba le ni igbagbọ ninu wọn.
Àkọlé fídíò, Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní

Ẹwẹ, ipade naa ni awọn faramọ aba lati ṣe agbekalẹ igbimọ iwadii ti yoo tọpinpin gbogbo aṣemaṣe ti SARS ti ṣe ati awọn ẹka ọlọpaa miran.

Ipade ọhun tun sọ pe awọn faramọ agbekalẹ igbimọ iwadii yii laarin ọsẹ kan ti wọn yoo si pe fun iwe ẹhonu lati ọdọ ara ilu ti SARS ti tẹ oju ẹtọ wọn mọlẹ.

Aworan nkan tawọn ọdọ Naijira fẹ

Ni itẹsiwaju bakan naa atẹjade ipade yi daba ṣiṣe ayẹwo ọpọlọ fawọn oṣiṣẹ SARS ti wọn ba da silẹ to fi mọ idanilẹkọ ṣaaju ki wọn to pin wọn si ẹka ọlọpaa mii.

Gbogbo awọn nkan wọn yi lo wa lara ẹdun ọkan marun un ti awọn oluwde ENDSARS ni awọn fẹ ki ijọba mojuto.

Lara awọn ti wọn wa nibi ipade yi ni:

  • Dr Kole Shettima-MAC Arthur Foundation
  • Innocent Chukwuma -Ford Foundation
  • Jude Ilo-OSIWA
  • Segun Awosanya(segalinks)-End Sars Movement
  • Yemi Adamolekun-Enough is Enough
  • Folarin Falana Falz
  • Auwwal Rafsanjani- CISLAC
  • Kemi Okonyedo- PWAN

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Pẹlu ikede yi, ohun to ku ni boya awọn oluwọde yoo fọwọ wọnu dẹkun iwọde tabi ki wọn ṣi tẹsiwaju.

Kete ti ikede naa jade loju opo Twitter lawọn ọmọ Naijiria kan ti n sọ ero ọkan wọn nipa rẹ:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Twitter

Kò gbọdọ̀ sí ìfẹ̀họ́núhàn EndSARS ní ìpínlẹ̀ Rivers - Gomina Wike

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti fofin de gbogbo ifẹhọnuhan nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade to fi si oju opo Twitter rẹ, Wike ni ko si idi ti awọn eniyan yoo fi fi ẹhọnuhan nipinlẹ naa nitori Ọga Agba Ọlọpaa, Mohammed Adamu ti tu ikọ SARS.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Nitori naa ko si idi ti awọn eniyan yoo fi ma a wọde lẹyin ti wọn ti tuka.

Gomina Wike wa rọ awọn obi lati ri wi pe ọmọ wọn ko bọ sita lati tapa si aṣẹ oun.

Bakan naa lo kesi awọn agbofinro lati ri wi pe ifofinde naa fi ẹsẹ mulẹ lọkunkundun.

End Sars Police shooting: Babajide Sanwo Olu ti pàṣẹ pé kí Ọ̀gá Ọlọ́pàa tú àwọn afẹ̀hónúhàn sílẹ̀ ní kíákíá

Lori ọrọ iwọde fifopin si ifiyajẹni ati iṣekupani lọna aitọ lati ọdọ awọn agbofinro Naijiria ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo Olu naa ti paṣẹ.

Saaju ni oriṣiriṣi iwọde ti bẹrẹ lati ipinlẹ eko ni eyi to si ti ran kaakiri Naijiria lori ọrọ #End SARS to gbode kan.

Gomina Sanwo olu

Oríṣun àwòrán, @Sanwo olu

Ninu awọn iwọde yii ni awọn agbofinro ipinlẹ Eko ti mu awọn afẹhonuhan kọọkan si atimọle.

Bayii Sanwo Olu ti kede pe ki wọn lọ tu wọn silẹ ni ẹyẹ o sọka.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Saaju ni Aarẹ Buhari ti kede pe ki wọn tu ikọ olọpaa kogberegbe SARS ka ni Naijiria lẹyin ti iwọde naa ti n de awọn orilẹ-ede miran.

Sugbọn awọn ọmọ Naijiria yari pe aṣẹ " Executive order" ni a\won fẹ ko fi ṣe nitori ijọba ti kede ifopin si ati atunṣe ọlọpaa lẹẹmẹrin tẹlẹ ṣugbọn to ja si pabo.

Ọga Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police

Ọlọ́pàá f'ẹsẹ̀ fẹ́ẹ l'Eko lẹ́yìn tó yìnbọn fún ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lẹ́nu

Ọlọpaa kan ti wọn n wa bayii ni a gbọ pe o ti juba ehoro lẹyin to yinbọn fun ọrẹbinrin rẹ ni ibudokọ Salvation Bus Stop ni Ikeja niluu Eko.

Ọlọpaa naa ni a gbọ pe o fi ọrẹbinrin rẹ naa silẹ lọ lẹyin to da ọran ọhun tan.

Àkọlé fídíò, EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde

Fọnran kan to lu ayelujara pa ṣafihan bi awọn alaanu kan ṣe gbe obinrin naa digba digba lọ sile iwosan nigba to n jẹ irora ni ibudokọ ọhun.

Fidio tun ṣe afihan bi ọta ibọn ṣe ya obinrin naa ni ẹnu ati ẹrẹkẹ.

Fọnran ọhun tun ṣafihan bi obinrin naa ṣe n ke irora nigba to n duro de awọn dokita nile iwosan.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Eko, Muyiwa Adejobi ṣalaye pe awọn ti da ọlọpaa to ṣiṣẹ ibi náà mọ ṣugbọn ko si labẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko.

Adejobi ni otitọ ni pe ọrẹkunrin obinrin naa ni ọlọpaa ọhun.

Àkọlé fídíò, coronavirus prevention badge update: Wo òótọ́ àti irọ́ tó wà nínú báàjì àyà náà

Amọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo ṣa gbogbo ipa lati mu ọlọpaa naa.

O ni o ṣeeṣe ko jẹ pe ede-aiyede lo mu ọlọpaa naa yinbọn.

Ọgbẹni Adejobi ni awọn ọlọpaa ti lọ ṣabẹwo si obinrin naa nile iwosan to wa fun Iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, ''Ẹ gbudọ̀ ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyí lọ́jọ́ ìdìbò gómìnà l'Ondo bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ...'

Afurasí kan yin Oloruntoba níbọn nítorí èdèàìyedè nílé oní Sharwama

Afurasi kan ti ko si ẹni to tii mọ ọ ni wọn fẹsun kan pe o yin ọkunrin kan to n jẹ Kayode Oloruntoba nibọn ni ikun nile oni Shawarma kan lagbegbe Alagbado nipinlẹ Eko.

Gbogbo igbiyanju awọn oninuure layika to fi mọ ọrẹ rẹ, Kazeem Okikiola lati doola ẹmi ọmọkunrin naa lo ja si pabo nitori o pada gbẹmi mi.

Iroyin sọ pe Okikiola lọ si ile ọti Avid ni Alagbado lọjọ Eti, ọjọ kọkanla lati ra Sharwama to si pe Oloruntoba lati sin oun lọ.

Bi wọn ṣe n duro ki ẹni to n ta Shawarma da wọn lohun, a gbọ pe ede aiyede bẹ silẹ laarin Okikiola ati onibara miran ti oun naa fẹ ra Sharwama.

Ede aiyede naa ko ju pe tani o yẹ ki wọn kọkọ ta a fun, eyi to di ija laarin wọn, eyi si ni afunrasi naa fi binu ko sinu ọkọ rẹ to si lọ fa ibọn yọ.

Lẹyin iṣẹju diẹ Oloruntoba duro ti Okikiola ri wọn si n reti ki wọn ta Sharwama ti wọn fun wọn ni afurasi naa ba pada de, o fa ibọn yọ lo ba yin in lu ibi ti awọn mejeeji suro si.

Awọn ti ọrọ soju wọn sọ pe ikun ni ibọn ti ba Oloruntoba nigba ti afurasi naa si fẹsẹ fẹẹ.

Ọkan ninu awọn olugbe adugbo naa to pe ara rẹ ni Chinedu ni afurasi naa ṣeeṣi yin ẹni ọdun marundinlogoji ọhun nibọn ni.

Sharwama

"O ro pe Okikiola ti oun pẹlu rẹ ni gbolohun asọ ni ṣugbọn o ṣeni laanu pe ọtọ ni ẹni ti ibọn ba. Ni kia naa lo pada sinu ọkọ rẹ to si salọ"

Aladugbo miran Seyifunmi Akinola, salaye pe baba alawo kan tilẹ gbiyanju lati yọ ọta ibọn naa kuro lara Ọlọruntoba, ṣugbọn o ku nigba ti wọn n gbe e lọ fun itọju nile iwosan.

Akinola ni ni kete ti ọrọ naa ṣẹlẹ ni wọn ti gbe e lọ si ile iwosan Merit ti wọn si kọ ọ nibẹ pe ki wọn lọ mu iwe wa lati ọdọ ọlọpaa.

Wọn pada ni ki wọn maa gbe e lọ si ile iwosan gbogboniṣe ti Otta nipinlẹ Ogun nibi ti wọn ti toju rẹ diẹ ti wọn si ni ki wọn maa gbe e lọ si ile iwosan gbogbonise ni Abeokuta.

"Kaka ki wọn gbe lọ si Abeokuta, wọn gbe e lọ si ọdọ oniṣegun ibilẹ kan pe ki o yọ ọta to wa lara rẹ, lẹyin naa ni wọn gbe e pada lọ si ile iwosan gbogboniṣe Otta sugbọn wọn kọọ nibẹ. O ku nigba ti wọn n gbe lọ si ile iwosan miran."

Àkọlé fídíò, Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí

Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa nipinle Eko Olumuyiwa Adejobi ni awọn adurasi mẹfa to fi mọ Okikiola ni awọn n fi ọrọ wa lẹnu wo lọwọlọwọ lori iṣẹlẹ naa

Agbẹnusọ Ọlọpaa ni Okikiola to jẹ ọrẹ rẹ to lọ pe e nile ko wa fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ kaka bẹẹ, o gbe lọ si ile Baba alawo lati lọ yọ ọta ibọn lara rẹ.

"Lěyin naa lo tun pada gbe Oloruntoba lọ si ile ẹgbọn rẹ ni Ipaja nibi ti o ti pada wa ku."

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

Kọmisọna Ọlọpaa Ipinlẹ Eko Hakeem Odumosu ti awọn ọlọpaa lati ṣe awari afurasi to ṣiṣẹ ibi naa.

"Lasiko iwadii, wọn ti mu ẹni to ni sọọbu Sharwama Chimezie Amaechi, ọrẹ oloogbe Kazeem Okikiola, alabojuto ile ọti naa, Olayinka Oyedokun ati awọn ọrẹ rẹ Femi Victor, Taiwo Morokola ati Omole Wasiu.

Àkọlé fídíò, 'Aràrá bíi tèmi, kó má rò pé kò sì ǹkan tó lè ṣe láyé ju iṣẹ́ agbe lọ'