Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ ọkùnrin kan pẹ̀lú orí ọmọdé nílé aṣòfin àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọlọpaa ti ko mamugarri si ọwọ arakunrin kan ni ẹnu iloro ileegbimọ aṣofin orilẹede naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Uganda ka apo kan mọ arakunrin naa lọwọ ninu eyi ti wọn ti ba ori ọmọde kan ti wọn ge nibẹ.
Ko tii si ẹni to lee sọ ni pato ohun gan ti ọkunrin naa fẹ ṣe to fi gbe ori ọmọde wa si ile aṣofin naa, bakan naa ni ko tii si ẹni to mọ ibi to ti ri ori ọhun.
- Ọmọkùnrin tó ya 'Blue film' nínú igbó Osun Osogbo ti bayé ara rẹ̀ jẹ́ - Yemi Elebuibon
- Ìbẹ̀rù-bojo dé l'Ado Ekiti! Àwọn agbébọn pa ọ̀gá àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀
- Ó yẹ kí Sotitobire gbọ́ ìdájọ́ lónìí ṣùgbọ́n ẹ wo bí ilé ẹjọ́ ṣe tún ṣe é
- Lai Mohammed, Ayo Fayose, Afẹnifẹre, Ndigbo, Arewa dá sí ọ̀rọ̀ Buhari àti Obasanjo
Nibayii, iroyin sọ pe o ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa nibi ti wọn ti n fi ọrọ wa a lẹnu wo.
Eeyan kan ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn gba ipe pajawiri pe ọmọ kan sọnu lootọ lati agbegbe Masaka, iyẹn apa gusu ilu Kampala to jẹ olu ilu orilẹede naa. Awọn si ri oku ọmọde kan ti wọn ti ge ori rẹ lagbegbe naa ni ọjọ kan naa. Awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣi n wadii bi iṣẹlẹ mejeji naa ṣe so pọ mọ ara wọn.
Lawọn ọdun diẹ sẹyin, ọwọja ijinigbe ati iṣekupa awọn ọmọde gogo sii lorilẹede Uganda, ti igbagbọ ọpọ si da lori pe wọn fi wọn ṣetutu ọla ni.
Bakan naa ni iṣẹlẹ awọn ajafẹtọ to n gbe ẹbọ ka iwaju ile aṣofin naa pẹlu ti n waye lati tako iwa ijẹkujẹ ati aisi iṣẹ fun awọn ọdọ.









