Cardi B leaked video: Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/IAMCARDIB
Onkọrin, ọmọ ilẹ America, Cardi B ti fesi lẹyin to ṣe e ṣi fi fọto ihoho rẹ sori ayelujara Instagram rẹ.
Akọrin takasufe naa to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejidinlọgbọn rẹ lọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, sare lati yọ fọto naa kuro lori ayelujara.
Ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, nitori pe nigba ti yoo fi yi oju foonu rẹ pada si ibi to yẹ, fọto naa ti lọ sori Instagram, awọn ololufẹ rẹ to ju miliọnu mẹrindinlọgọrin lọ, si ti ri ihoho rẹ.
Niṣe ni Cardi B sare pa fọto naa rẹ, to si gba pe oun ṣe aṣiṣe.
Lẹyin naa lo sọ pe oun ko ni i gbe ẹnikẹni lọ sile ẹjọ lori fidio ihoho naa, nitori pe ọwọ oun ni aṣiṣe naa ti wa.
Bakan naa lo ni oun ko ni tori rẹ bara jẹ.
Ko tan sibẹ o, akọrin takasufe naa ṣalaye pe oun ati ọkọ oun, Offset, lo jọ n ya fọto nigba ti oun ṣe e ṣi tẹ bọtini miran, to si gbe e lọ sori ayelujara Instagram.
O gbiyanju lati yara pa foonu naa lati da fọto naa duro, ṣugbọn o ti pẹ ju.
Yoruba bọ, wọn ni isọrọ nigbesi. Cardi tun fun ẹnikan to gbiyanju lati bu ẹnu atẹ lu irisi rẹ ninu fọto naa, l'esi pe "ori ọyan mi tobi, nitori pe mo fun ọmọ mi, Kulture l'ọmu fun oṣu mẹta".
Awọn ololufẹ Cardi B si ti bẹrẹ si ni i ṣe atilẹyin fun un lẹyin iṣẹlẹ naa.
Awọn kan ti ẹ tun n fi fọto ihoho wọn sita pẹlu #BoobsOutForCardi.
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Mi ò mọ̀ nípa àwọn tọ́ọ̀gì tó da ìwọ́de EndSARS Alausa rú, mo ṣì wà lẹ́yìn yín digbí! - Sanwoolu
- Ìjọba kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn àgùnbánirọ̀ sí ìpàgọ́ lẹ́yìn Covid 19- Sunday Dare
- Àjọ elétò ìdìbò kéde ọjọ́ tí ìdìbò aàrẹ Nàìjíríà 2023 yóò wáyé
- Àbádòfin ìṣúná 2021 ré kọjá ìpele ìkejì nílé aṣòfin àgbà















