Ondo police accident: Ọlọ́pàá mẹ́sàn án tó farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ Akure t'éèyàn méjì ti kú sì wà nílé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Facebook/AIT Online
Awọn ọlọpaa mẹsan an to farapa ti wọn farapa ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lọjọ Iṣẹgun si n gba itọju lọwọ nile iwosan.
Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bolaji Salami lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba.
O ni awọn ọlọpaa naa ni o ba iṣẹlẹ naa lọ, yatọ si awọn to farapa.
- Àjọ DSS tú gbogbo pátá mi wò pé wọ́n ń wa ọmọ- Bisola aya Woli Alfa
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà
- Mo ṣèlérí láti ṣe ju ohun tí mo ti ṣe lọ fún ẹbí àwọn tó kú torí EndSARS - Seyi Makinde
- Ìwọ́de 'End SARS' lè tan àjàkálẹ̀ arùn coronavirus lẹ́ẹ̀kejì ní Nàìjíríà- Ọjọ̀gbọ́n Faduyile
- Ẹ lo ìfẹ̀họ̀núhàn #EndSARS lati fí tún gbogbo ohun tó bàjẹ́ ṣe ní Naijiria- Pásítọ̀ Sam Adeyemi
Amọ, kọmiṣọnna Salami ṣalaye siwaju sii pe oun ko le sọ gbogi ohun to ṣe okunfa iṣẹlẹ ọhun.
O ni iwadii si n lọ lọwọ lori ohun to fa iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa lopopona papakọ ofurufu niluu Akure.
Awọn kan sọ pe ere aṣaju lo fa a nigba ti awọn miiran taya ọkọ ti wọn wa ninu lo fọ lori ere eyi to mu ki ọkọ naa bẹrẹ si ni gbokiti.
Awọn ọlọpaa ọhun ti wọn jẹ mọkanla ninu ọkọ n bọ lati ọfiisi ajọ eleto idibo INEC nibi ti wọn ti fun Gomina Rotimi Akeredolu ni iwe ẹri moyege lẹyin to wọle ibo gomina Ondo nigba ti ijamba naa ṣẹlẹ.
Ọlọ́pàá méjì dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Akure lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbi tí Akeredolu ti gba ìwé-ẹ̀ri moyege
Ọlọpaa meji ti dero ọrun ninu ijamba ọkọ to ṣelẹ lopopona papakọ ofurufu ilu Akure lonii ọjọ kẹtala oṣu kẹwaa ọdun 2020 yii.
Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bolaji Salami lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@femi_desmond
Ọga ọlọpaa naa ni awọn ọlọpaa ọhun ti wọn jẹ mọkanla ninu ọkọ ti wọn n bọ lati ọfiisi ajọ eleto idibo INEC nibi ti wọn ti fun Gomina Rotimi Akeredolu ni iwe ẹri moyege lẹyin to wọle ibo gomina Ondo nigba ti ijamba naa ṣẹlẹ.
- Ẹ wo èrò bìbà níbi ìwọ́de #EndSARS ní ìlú Ibadan
- Ìfẹ́hònúhàn 'End SARS' ń tẹ́síwájú láì jẹ́ pé Buhari ṣe.....
- Àfikún owó epo àti owó iná pẹ̀lú owó orí VAT ló jẹ́ ká fowó kún tàríìfù DSTV- Ọ̀gá MultiChoice
- Mo fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ mi- Baba ọmọ ti SARS pa
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
- Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
Ọgbẹni Salami ni awọn ọlọpaa ọhun n pada si ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ni ijamba naa ti ṣẹlẹ.
Ọga ọlọpaa Ondo ni oun gbọ pe taya ọkọ ti wọn wa ninu rẹ lo fọ lori ere ti ọkọ naa si bẹrẹ si ni gbokiti.
O fikun ọrọ rẹ pe oun n lọ si ile iwosan tawọn ọlọpaa mẹsan an to mori bọ ti n gba itọju.
















