Increased DSTV tariff: MultiChoice ní àfikún owó epo, owó iná pẹ̀lú owó orí VAT ló jẹ́ káwọn fowó kún tàríìfù DSTV

Oríṣun àwòrán, Twitter/Super Sport
Ti ko ba nidi, obinrin kii jẹ ikumolu. Ileeṣẹ MultiChoice Group to ni ileeṣẹ amohunmaworan DSTV ti ṣalaye fawọn ọmọ Naijiria ohun to ṣe okunfa bi wọn ti gbowo le tariifu ẹrọ amohunmaworan naa.
Ileeṣẹ MultiChoice Group bi ijọba apapọ ti ṣe afikun owo ori VAT, epo rọbi ati ina mọnamọna lo jẹ kawọn naa gbowo le DSTV.
Oludari ileeṣẹ MultiChoice Group, John Ugbe lo sọrọ yii niwaju igbimọ ile aṣoju-ṣofin to ṣe iwadii afikun owo tariifu DSTV.
- Mo fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ mi- Baba ọmọ ti SARS pa
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
- Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
- EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde
- Ìfẹ́hònúhàn 'End SARS' ń tẹ́síwájú láì jẹ́ pé Buhari ṣe.....
O tun fesi lori bi awọn eeyan kan ti n sọ pe ileeṣẹ naa ko ṣe eto iranwọ fawọn ọmọ Naijiria lasiko coronavirus, MultiChoice Group ni ohun ti gbe biliọnu kan naira fun ijọba apapọ gẹgẹ bi owo iranwọ.
Ileeṣẹ MultiChoice Group ṣalaye siwaju si pe bi ọrọ aje to dẹnu kọlẹ ṣe n ṣakoba fawọn ọmọ Naijiria lo n ṣe akoba fun ileeṣẹ ọhun naa.
Lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹta 2020 yii ni ile igbimọ aṣoju-ṣoju gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe iwadii afikun owo tariifu DSTV ni Naijiria.
Bakan naa ni ile tun pinnu lọjọ keji oṣu kẹfa pe ki ileeṣẹ DSTV wa wi tẹnu rẹ lori ọrọ tariifu naa.
Ninu ọrọ rẹ, alaga igbimọ to n ṣe iwadii ileeṣẹ DSTV, Unyime Idem sọ pe ile bẹrẹ iwadii lẹyin tawọn ọmọ fi ẹhonu han lori afikun owo tariifu DSTV.
Ile ti sun ijoko lori ọrọ naa siwaju lai lọjọ lẹyin ijoko ọjọ Aje.
- Ìdí márùn ún tí agbára Covid 19 ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò fi tó tí àwọn ilẹ̀ àgbáyé míràn
- A máa ná N10.2 bílíọnù fi tún wáyà iná àti inú ilé Aso Rock ṣe- Buhari
- Wo ìdí tí Tẹni, ọ̀dọ́mọdé olórin obìnrin kìí fi ń ṣí ìhòhò rẹ silẹ̀
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- Wọ́n kò pa ẹnikẹ́ni sí ààfin Ṣọun Ogbomosọ, òkú tí àwọn ọdọ́ gbé wa ni ọlọ́pàá wọ́ jáde- Agbẹnusọ Ṣọ̀un
















