Oke Obi-Enadhuze:, Lekkitollgate, EndSars: Mọ̀ síí nípa Oke Obi

Oke Obi-Enadhuze

Oríṣun àwòrán, @DanielOE16

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gẹgẹ bi akọsilẹ nipa rẹ to wa ni oju opo ayelujara LinkedIn rẹ, Oke kekọọ gboyè imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ kọmputa ni Fasiti eto ọgbin ti ijọba apapọ to wa niluu Abeokuta, nipinlẹ Ogun laarin ọdun 2016 si 2020.

O maa n sisẹ lati ṣe agbekalẹ ìrísí ọjà 'product design'.

Oke si ti ṣe iṣẹ fun awọn ileesẹ bi i Lifebank Nigeria, ileesẹ kan to wa fun fifi ẹjẹ silẹ lori ayelujara.

Bakan naa lo darapọ mọ ile ifowopamọ Sterling ni oṣu Karùn-ún, ọdun 2020, ibẹ lo si ti n sisẹ titi di akoko iku rẹ.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn akẹẹgbẹ rẹ nileesẹ naa, Temie Gíga-Bosun ṣe sọ loju opo Twitter rẹ, ọlọpọlọ pipe ni Oke, to si jẹ onitiju eniyan.

Bakan naa lo sapejuwe Oke gẹgẹ bi eeyan daadaa.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

"Jàńdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn pa, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfo la wà"

Àbúrò' olóògbé ní kìí ṣe àsìta ìbọn ló pa ẹ̀gbọ́n òun, jàǹdùkú ni

A kii gbe inu ile ẹni, ka fọrun rọ, ase irọ patapata ni.

Idi ni pe onimọ kan nipa agbekalẹ oju opo ayelujara, Oke Obi-Enadhuze ni wọn ti kede pe asita ibọn ti dẹmi rẹ legbodo.

Oloogbe naa si lo se oju opo ti wọn ti lee fi ẹjẹ silẹ fun idoola ẹmi lori ayelujara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oke, ẹni ti ọrọ iku rẹ n ja rainrain lori ayelujara lọwọ lọwọ, lo jade laye lẹyin to fi ọrọ kan siju opo Twitter rẹ pe "Ko ni tan fun Naijiria."

Oke, to kẹkọọ nipa imọ nipa ẹrọ ayarabiasa, ni iroyin kan sọ pe ibọn ba nile rẹ to wa lopopona Paul, Mafoluku-Oshodi nilu Eko.

Agọ ọlọpaa ti wọn sun nina

Oríṣun àwòrán, @odolz

Bi o tilẹ jẹ pe ko si ẹni to tii le sọ ẹkunrẹrẹ iroyin nipa iku rẹ lori ayelujara, amọ awọn kan ni asita ibọn lo lọ ya ba Oke ninu ile, ẹni to si wa loju opo Twitter titi di aago meji ku isẹju mẹfa lọsan Ọjọru.

Wọn kọkọ ni ọta ibọn kan to wa lati agọ ọlọpaa Makinde lo ran ọdọkunrin naa sọrun lori ayelujara, lasiko tawọn janduku ya bo agọ ọlọpaa naa lati sun nina.

Wọn ni o seese ko jẹ pe ọta ibọn lo seese ba ọkunrin naa lasiko tawọn ọlọpaa n le awọn janduku sẹyin, ki wọn maa ba sisẹ ibi wọn.

Awọn jankuku ni aafin Oba Eko

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

Sugbọn ẹni kan to pe ara rẹ ni aburo oloogbe naa, Daniel Obi-Enadhuze, ti wa kede loju opo Twitter pe awọn janduku lo wọle wa pa ẹgbọn oun, kii se asita ibọn rara.

Daniel, lasiko to n salaye bi isẹlẹ naa se waye ni lẹyin tawọn janduku yege lati jo agọ ọlọpa Makinde naa nina, ni wọn ya wa si baraki ilegbe awọn ọlọpaa, ti oun ati iya oun n gbe.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ni wọn bẹrẹ si ba gbogbo mọto to wa nibẹ jẹ, to fi mọ ọkọ meji ti iya oun ni, ti wọn dana sun.

Ọkunrin naa ni lẹyin eyi ni wọn tun bẹrẹ si yẹ gbogbo ile awọn wo, ti wọn si n ko ohun gbogbo ti ọwọ wọn ba ba, ti wọn si gun ẹgbọn oun ni ọbẹ lọrun.

Ọkan lara oluwọde to gbọgbẹ

Oríṣun àwòrán, @Jidesanwoolu

Wọn tiẹ tiraka lati gun emi naa lọbẹ lọrun, amọ ọwọ wọn yẹ, ti wọn si fi ọbẹ ya mi ni agbọn.

Emi ati iya mi saayan lati gbe ẹgbọn mi lọ siwaju agọ ọlọpaa lati wa iranwọ amọ awọn janduku si n soro lọwọ.

Ọmọlanke la papa fi gbe ẹgbọn mi lọ sile iwosan lẹyin o rẹyin, nibi to ti dakẹ."

Daniel ni gbogbo ohun tawọn sisẹ fun laye awọn ni oun ati iya oun ti padanu bayii, wọn jo ile awọn nina, ti ẹgbọn oun si tun fi ẹmi rẹ di.

"Emi ati iya mi ti di alainile lori bayii amọ a wa ni alaafia, a si n dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan to wa ba wa kẹdun lasiko ọfọ yii."

Jàǹdùkú pà ọlọ́pàá méjì, jó àgọ́ wọn mẹ́wàá, báńkì mẹ́ta, jí ọ̀pọ̀ owó l'Eko - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

end SARS

Oríṣun àwòrán, @Odolz_

Ileeṣẹ ọlọpaa ti ke sita lori bi awọn janduku to fi iwọde End SARS boju, ṣe n kọlu awọn ọọfisi atawọn oṣiṣẹ wọn ni ipinlẹ Eko.

Ileeṣẹ ọlọpaa kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin, eyi ti alukoro ileeṣẹ naa ni ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejobi, buwọlu.

O ni awọn janduku naa pa ọlọpaa meji ni agọ wọn to wa ni Orile, bẹẹ ni wọn tun ṣe ogunlọgọ ọlọpaa leṣe, ki wọn to dana sun awọn agbegbe mẹwaa mii, ti awọn ọlọpaa maa n korajọ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn agọ ọlọpaa ti ọrọ naa kan ni ti Igando, Layeni, Denton, Ilenbe Hausa, Ajah, Amukoko, Ilasa, Cele labẹ Ijesha.

Bakan naa ni wọn tun kọlu ọọfisi SARS to wa ni Ajegunle, Ebute-Ero Mushin nibi ti wọn ti ṣina ibọn fun ọlọpaa meji, pẹlu Ojo ati Ajegunle nibi ti wọn ti jo ọkọ ọlọpaa meji-meji.

end SARS

Oríṣun àwòrán, @Harforbaje1

Ko tan sibẹ, atẹjade naa ni "Awọn janduku ọhun tun dana sun banki mẹta, ti wọn si ji ẹgbẹlẹgbẹ owo ko lọ, ṣugbọn a ri diẹ lara mu ti a si gba ohun ija oloro ati owo ti wọn ji ko lọwọ wọn."

Ni Ajegunlẹ, wọn dana sun ọfiisi ijọba ibilẹ Ajeromi Ifelodun ti wọn si tun ba awọn dukia jẹ nibẹ.

Awọn janduku naa tun ṣakọlu si afin ọba ilu Eko, ile itaja Shoprite, ileeṣẹ ọkọ oju omi ni Marina ati ile iya Gomina ipinlẹ Eko to wa ni Akerele.

Ile iya Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @Chinasanworu

Bakan naa ni wọn tun jo ọọfisi awọn VIO ni Ojodu, ile ẹjọ magisireti ni Igbosere, ileeṣẹ iroyin TVC ati The Nation, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa naa fi kun pe, ọpọ eeyan lo dagbere faye nitori ikọlu awọn janduku naa, ti awọn mẹrin kan si farapa yanayana.

Lẹyin naa lo ni bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan lẹtọ labẹ ofin lati ṣe ifẹhonuhan, ileeṣẹ ọlọpa ko ni faye gba iru rogbodiyan bayii mọ.