Lekki Shooting: Ohun tó ṣẹlẹ̀ kò sí nínú ìlànà ológun, Buhari gbọ́dọ̀ ṣèwádìí

Bode George ati oluwọde to fara gbọgbẹ ni Lekki
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oloye Ọlabọde Ibiyinka George to jẹ ajagunfẹyinti, oloṣelu ati alakoso to lorukọ nilẹ yii, ti ke si aarẹ Buhari lati gbe iwadii kalẹ lori iṣẹlẹ ipaniyan Lekki.

Bode George ni iwa ti ko tọ fun ologun ni lati kọju ibọn si awọn eeyan ti ko di ihamọra ogun, paapaa julọ nigba tawọn ti wọn n dojukọ jẹ ọdọ orilẹẹde ti wọn jẹjẹ lati maa daabobo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bode George woye ọrọ yii nigba to n fesi si isẹlẹ isekupani to waye ni Lekki lọ̀jọ Isẹgun.

Bakan naa, ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ati orilẹede agbaye lo n kerora lori wahala to ṣẹlẹ ni agbegbe Lekki Tollgates.

Eyi ko si sẹyin iroyin ibọn yinyin awọn ṣọja si awọn oluwọde nibẹ, ti ọpọlọpọ si n fi ero wọn han lori iṣẹlẹ naa atawọn ohun gbogbo to tẹle.

Awọn ọdọ to n se iwọde

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba lori isẹlẹ yii, Bode George ṣalaye pe wọn ko gbọdọ gba ọrọ naa sori akitan lai jẹ pe wọn wadii gbogbo bi iṣẹlẹ naa ṣe jẹ, ki wọn si fi awọn to ba ṣẹ jofin.

'Bawo la ṣe maa kọju ibọn sirawa? To ba wa lati ita ni ọta ti wa wa nkọ, ki la maa kọ si wọn?

Alagba George ni ara ere ijọba awarawa naa ni ilana ipẹtu-saawọ dipo lilo ibọn.

O fi kun un pe, ara ohun to yẹ ki ijọba ṣe bayii ni ifikuluku, ipẹtu-saawọ ati ifidaniloju pe nnkan yoo di ṣiṣe lori ẹhonu wọn.

Ọjọ́ Ìsẹ́gun di ọjọ́ ìbànújẹ́ fún ọ̀pọ̀ ìdílé ní Nàíjíríà torí òkú tó ṣùn

Awọn ọdọ to n se iwọde

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Yika orilẹede Naijiria ni awọn araalu ti n se ọfọ awọn eeyan wọn to dagbere faye lojiji lati ipasẹ iwọde EndSARS to di rogbodiyan.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn alasẹ ko ti se akojọpọ iye eeyan to faye silẹ, sibẹ awọn akojọps awọn isẹlẹ to waye lawọn ipinlẹ kọọkan fihan pe, nnkan ko fara rọ.

Lati aarọ ọjọ Isẹgun ni rogbodiyan ti gbode kan lawọn ipinlẹ kan bii Eko, Oyo, Osun, Ekiti, Ondo, Plateau ati Kano.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nilu Eko, Ibadan ati Plateau, awọn janduku to ja iwọde gba mọ awọn oluwọde EndSARS lọwọ dana sun awọn agọ ọlọpaa kan.

Awọn ọdọ to n se iwọde

Agọ ọlọpaa Iganmu nilu Eko, Ọọjọ nilu Ibadan ati ti Plateau ni wọn jo kanlẹ, ti ẹmi awọn ọlọpaa kan si bọ lasiko isẹlẹ naa.

Ko tan sibẹ, awọn araalu naa fara gba ninu isẹlẹ yii, ti awọn eeyan si ku nilu Eko, Ibadan ati Plateau.

Koda, ilu Akure, Osogbo ati Ado Ekiti ni rogbodiyan ti fọnna soju, tawọn gomina lawọn ipinlẹ yii si kede pe kawọn ile ẹkọ wa ni titipa.

Bakan naa ni ipinlẹ Edo, Eko, Plateau , Ondo ati Ekiti.

Awọn oluwọde

Sugbọn eyi to pabambari ninu awọn isẹlẹ naa, to fi mu ki ọjọ Isẹgun ana jẹ ọjọ buruku, esu gbomi mu ni bi awọn sọja ati ọlọpaa se da si iwọde to n waye ni Lekki, nipinlẹ Eko.

Iroyin ni ọpọ ọdọ to n se iwọde lo jade laye, ti akọsilẹ ko si tii salaye iye wọn ni pato, nigba ti ọpọ eeyan wa nile iwosan, ti wọn n gba itọju lati ipasẹ ọgbẹ ti wọn ni.

Bakan naa, ni awọn ọdọ bii ọgbọn ti n gba itọju lọwọ nile iwosan nitori ọgbẹ ọta ibọn.

Awọn ọdọ to n se iwọde

Sugbọn ileesẹ ologun ilẹ wa ti fesi lori ẹsun naa, to si ni oun ko mọ ohunkohun nipa rẹ.

Nigba to n sẹ lori awọn ikede kan tawọn araalu fi soju opo Twitter ni alẹ ana, ileesẹ ologun Naijiria ni iroyin ede gbaa ni iroyin naa.

O fikun pe ko si ọmọ ologun kankan to wa nibi isẹlẹ naa.

Àwọn ṣọ́jà ṣíná ìbọn bolẹ̀ ni Lekki Tollgate

Ina ibọn n sọ lala ni agbegbe Lekki Tollgate ni ipinlẹ Eko lalẹ ọjọ Iṣẹgun nibi ti awọn ologun ti yin ibọn ati eroja iṣere fireworks lati tu awọn oluwọde ka.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe awọn oluwọde naa ṣi peju babi sibi iwọde ni iloro Lekki Tollgate naa lai naani aṣẹ konile o gbele ti ijọba pa bẹrẹ lati agogo mẹrin irọlẹ ọjọ Iṣẹgun kan naa.

Wahala bẹ silẹ nigba tawọn oluwọde naa bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn ni kikankikan ti ọrọ naa si di boo lọ o yago.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ko si ẹni lee sọ iye awọn eeyan to fara kaasa ninu idarudapọ naa.

Akọroyin BBC to wa nibẹ ṣalaye pe ohun ti iro rẹ jọ iro ibọn ni awọn ṣọja naa kọkọ fi bẹrẹ ki wọn to bẹrẹ si ni yin iṣere ọdun Banga lati tu wọn ka.