EndSARS Protest Update: Ọwọ́ pálábá àwọn tó fọ́ ShopRite fún ìgbà kejì ségi

Shoprite Ilorin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Awọn janduku to kọlu ile itaja ShopRite ladugbo Fate, ni ilu Ilorin ko fi ti isede ti ijọba kede ṣe, eyi to bẹrẹ lọjọ Abamẹta.

Se ni awọn janduku tun pada lati ji nnkan nile itaja naa.

Àkọlé fídíò, Ẹ wo ojú àwọn jàndùkú tí ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ nígbà tí wọ́n lọ kó ọjà ọlọ́jà ní Shoprite Ilorin

Amọ ikọ ọlọpaa kogberegbe ati awọn ẹṣọ oju lalakan fi n ṣọri n gbiyanju lati ri pe wọn ko tun ji nnkan kò níbẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akọroyin BBC to wọ inu ile itaja naa ni, ṣe ni awọn janduku ba ọpọ dukia jẹ nibẹ.

Awọn eeyan kan n ko apo iresi

Sugbọn ọwọ palaba awọn eeyan naa segi nitori ati ọkunrin ati obinrin ni awọn agbofinro mu l'owurọ ọjọ Abamẹta.

Awọn eeyan naa ni won gba ọna ẹyin wọ inu ile itaja naa laarọ ọjọ Satide lati ko ẹrun nibẹ fun igba keji.

Arabinrin kan ti wọn mu sọ wipe, ọmọ oun tẹle oun wa nitori naa, ki wọn jẹ ki oun gbe ọmọ lọwọ lọ agọ wọn lẹyin ti ọwọ ba a tan.

Shoprite Ilorin

Yatọ si ile itaja Shoprite ti wọn kọlu, awọn janduku yii tun lọ ṣọsẹ ladugbo Taiwo, nibi ti wọn ti yabo ile itaja Fonemart.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile itaja ọhun sọ fun BBC pe, ọja ti awọn jnanduku na ji ko, fẹẹ to ọgbọn miliọnu naira.

Ìjọba ìbílẹ̀ kan péré ló kù kí a pìn oúnjẹ tí wọ́n jí gbé fún ní Ilorin- Ijọba Kwara

Abdulrahman Abdulrazaq

Oríṣun àwòrán, Abdulrahman Abdulrazaq

Ijọba ipinlẹ Kwara bu atẹ lu awọn to ja ile igbeohun ini Covid-19 si

Won ni: ''Ijọba ibilẹ kan lo ku ki a pin awọn ounjẹ iranwọ Covid-19 ti awọn eniyan jigbe lo fun''

Ijọba ipinlẹ Kwara ti ni iwa buruku ni awọn janduku to ja ile igbe ohun ini iranwọ Covid-19 si hu ni ilu Ilorin.

Ninu atẹjade ti kọmisọnna fun eto iroyin, Harriet Afolabi- Oshatimehin fi lede awọn ijọba mẹrindinlogun lo ni ohun iranwọ ti awọn eniyan jigbe lọ naa.

Ati wi pe ijọba ibilẹ kan lo ku ki awọn gbe awọn ohun iranwọ naa fun , nitori marundinlogun ninu wọn ti gba ohun iranwọ ti wọn.

Ijọba ni Ajọ CACOVID ati ifọwọsowọpọ ijọba ipinlẹ naa ni wọn ti bẹrẹ si ni pin awọn ohun elo ounjẹ naa fun awọn alaini nipinlẹ naa, ti wọn si ti bẹrẹ lati oṣu diẹ ṣẹyin.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Ọjọ Kẹtalelogun, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2020, ni ijọba ipinlẹ Kwara pẹlu iranwọ Ajọ CACOVID ṣe ifilọlẹ awọn ohun iranwọ naa, ati bi wọn yoo ṣe pin ti yoo kari gbogbo eniyan.

Nibayii, ijọba ti ni awọn ti ọwọ tẹ nibẹ yoo foju wina ofin, eleyii ti yoo ko awọn yoku lọgbọn.

Bakan naa ni wọn kilo fun awọn janduku lati ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ, nitori awọn ko ni gba ki ẹnikẹni da rogbodiyan silẹ nipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

Àwọn kan ní ìpínlẹ̀ Kwara já ilé ìkó-ǹkan-sí wọ́n pín " CaCovid Palliative" fáwọn èrò ní Ilorin

Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ẹ̀sọ́ aláà[bò àwọn Jàǹdùkú tún yabo ilé tí "Covid 19 Palliative" waà

Ọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ alaabo, awọn janduku tun yabo ile igbe ohun iranwọ Covid-19 si ni Ilorin

EndSars Protest: Aworan lori ayelujara safihan ọgọọrọ eniyan to n gbe igbe ohun iranwọ Covid-19 si ni Ilorin

Ijọba Kwara ni awọn ti gbọ pe awọn janduku naa n bọ wa ko ohun iranwọ Covid -19

Ẹṣọ alaabo nipinlẹ Kwara ti bori awọn janduku to ṣekọlu si ile igbohun iranwọ Covid-19 si ni agbegbe Ilorin Cargo nipinlẹ Kwara.

Awọn janduku naa lo ṣe ikọlu sibẹ lasiko ti ijọba bẹrẹ si ni pin awọn ohun iranwọ naa fun awọn eniyan to wa ni agbegbe naa.

Ijọba ipinlẹ Kwara ni awọn ohun iranwọ Covid-19 naa wa nibẹ nitori ijọba apapọ ṣẹṣẹ fi sọwọ si wọn ni ipinlẹ naa ni.

Ijọba ni saaju igba ti awọn janduku naa ṣekọlu si ibẹ, awọn ti gbọ wi pe awọn n bọ lati wa hu iwa ipa si wọn ni agbegbe naa.

Ti wọn ṣi ṣetan lati kọ awọn ohun iranwọ ti wọn fẹ fun awọn ti ojo arọrọda ṣọṣẹ si agbegbe wọn, to si ba awọn ohun ini wọn ka.

Ni asiko ti wọn n fi iroyin yii lede, ijọba ni awọn ṣi n tiraka lati kapa awọn jagidijagan naa.

Amo, aworan to n jayin lori ayelujara fihan gbangba bi awọn eniyan ṣe n gbe awọn ohun elo ounjẹ kuro ni ibẹ, ti aẉọn ẹsọ alaabo ko si se wọn ni ijamba.

Àwọn Janduku ya bo Ede wọ́n pin ohun eelo idera ajakale arun Covid 19.

Ase bo ṣe wa ni liki naa lo wa ni gbanja.

Lẹyin ti okiki iroyin kan lọjọbọ pe, awọn eeyan kan kọlu ibudo iko nnkan awọn ohun elo iranwọ lasiko ajakalẹ arun COVID-19 pamọ si nilu Eko, awọn eeyan kan naa tun ti ṣe bẹẹ nipinlẹ Osun bayii.

Iroyin sọ pe lojumọ ọjọ Ẹti lawọn eeyaEde gbàlejò jàńdùkú tó fọ́ ilé ẹrù ìjọba n kan tun ya bo ibudo iko nnkan awọn ohun elo iranwọ lasiko ajakalẹ arun COVID-19 pamọ si nilu Ẹdẹ, ni ipinle

Awọn eroja idẹrun

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Jàǹdùkú ya bo ilé ẹrù ìjọba Osun, wọ́n kó èròjà ìdẹ̀rùn Covid-19 lọ

Ni ile kan ti wọn n pe ni Hocoa house ni ilu Ẹdẹ ni wọn ko awọn ohun irọrun COVID-19 naa si.

Awọn ọdọ atawọn araalu naa ya bo ile nla naa ni nnkan bii agogo mejila ku ogun i'sẹju lowurọ ọjọ Ẹti ti wọn si ko awọn ounjẹ bii noodles, irẹsi, ṣuga, garri atawọn ounjẹ miran ti wọn gbe pamọ fun irọrun COVID-19 ni ipinlẹ naa.

Awọn kan laera awọn ọdọ naa gbe kẹkẹ, ọkada, ọkọ bọọsi lati fi ko awọn ounjẹ ti wọn n ji ko nibẹ naa.

Àwọn Jàǹdùkú yabo ilé ìkó-ǹkan-pamọ́ sí, wọ́n kò 'Covid 19 Palliative" lọ ní Eko

Awon janduku ti sekolu si ile ikohunpamọsi nilu Eko nibi ti wọn ko awọn ohun amayedẹrun Covid -19 si.

Iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Mazamaza ni ijọba ibilẹ Amuwo Odofin ni ipinlẹ Eko.

Lara awọn to wa ni agbegbe naa ni awọn janduku ja ile igbe nkan pamo si naa, ti wọn si ko gbogbo awọn ohun eelo amayederun Covid-19 to wa nibẹ.

''Agogo mẹjọ aarọ ni iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ, nigba ti awọn janduku naa si ko ohun ti wọn nilo tan, wọn pe awọn ara adugbo lati wa bẹrẹ si ni ko awọn ohun elo naa.

''Ohun ti a kọkọ gbọ ni iro ibọn, ti wọn si jawọ ile igbohunsi naa, lẹyin naa ni wọn pe awọn ara adugbo lati wa ma a ko awọn ounjẹ naa lọ́fẹ̀ẹ́

''Awọn ohun eelo ounjẹ ti awọn eniyan n ko naa jẹ eleyii ti wọn kọ orukọ Covid-19 si lara.''

Kini Ijoba sọ?

Amọ, ijọba ipinlẹ Eko ninu atẹjade ti ko si ẹni to buwọlu sọ wi pe, ile ikohunsi to jẹ ọkan lara ti ijọba ni awọn janduku lo ṣe ikọlu si naa,

Ati wi pe awọn ohun eelo naa wa fun awọn ti nkan ko lo deede fun ni awujọ.

Bakan naa ni wọn fikun un wi pe Ajọ awọn aladani CACOVID lo fun ijọba ni awọn eelo ounjẹ naa,

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ki wọn le e pin fun araalu lati Ọjọ Kejilelogun, Oṣu Kẹsan, odun 2020, ko to di wi pe awọn eniyan ṣekọlu si agbegbe naa.

Ohun eelo bii, Irẹsi, garri, suga, indomie to to ọna ọgọrun un lọna ẹgbẹrun o le ni awọn fẹ fun awọn ara Eko gba ọwọ ajọ CACOVID.

Awọn eeyan kan n ko apo iresi

Oríṣun àwòrán, Twitter/oluwaseunfunmi

Awọn ọdọ to n se iwọde

"Buhari, ìwọ́de yóò yíwọ́, tó ba jẹ́ ki ológun bẹ̀rẹ̀ 'Operation Crocodile Smile' "

Operation Crocodile Smile: Ọmọ Nàíjíríà ní àsìkò ìwọ́de kọ́ ló yẹ kí ológun ṣe àkànṣe ètò

Awọn oluwọde ri ikede ileesẹ ologun lati bẹrẹ operation Crocodile Smile bii ara ọna lati da awọn ologun sita, ki wọn lee bomi pa ina iwọde to n lọ lọwọ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n fesi si ikede ileesẹ ologun lati bẹrẹ akanse eto igbogun tiwa ọdaran ti wọn pe ni Operation Crocodile Smile.

Awọn ọdọ to n se iwọde, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan atawọn agbẹjọro ti wọn tako igbesẹ naa ni awọn fura pe o seese ki ejo lọwọ ninu lori igbesẹ ologun yii.

Bakan naa ni wọn n fa ijọba leti pe ko tun ero rẹ pa lori ikede ologun naa, paapaa lasiko yii ti iwọde n waye yika Naijiria lati tako iwa ika awọn ọlọpaa, ti wọn si n beere fun ifopin si ọlọpaa SARS.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan tun wa n kọminu lori igbesẹ ologun lati bẹrẹ akanse eto naa lasiko yii ti arun Coronavirus si wa lode.

Gomina Sanwo-Olu laarin awọn ọdọ to n se iwọde

Wọn wa n fewe ọmọ mọ aarẹ Buhari leti pe bawọn ologun ba tun bẹrẹ akanse eto lasiko yii, ọrọ naa lee yiwọ pupọ.

Ọjọ Satide nileesẹ ologun kede pe oun fẹ bẹrẹ akanse eto igbogun tawọn agbesunmọmi ati ọdaran lawujọ ni ori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Blind Couples: Pẹ̀lú ìpèníjà ojú, tọkọtaya bímọ mẹ́ta, tí wọn sì tún ń ṣiṣẹ́ olùkọ́

Koda, awọn oluwọde ri ikede ileesẹ ologun lati bẹrẹ operation Crocodile Smile bii ara ọna lati da awọn ologun sita, ki wọn lee bomi pa ina iwọde to n lọ lọwọ.

Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ 'Operation Crocodile Smile' yíká Naijiria fún oṣù méjì

Operation Crocodile Smile

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/ Twitter

Ileesẹ ologun Naijiria ti kede pe oun fẹ gunle akanse eto operation Crocodile Smile fun ọdun 2020 jake jado orilẹede yii.

Atẹjade kan ti adele oludari ẹka alarina nileesẹ ologun, ọgagun Sagir Musa fisita lọjọ Satide lo sísọ loju ọrọ yii.

Atẹjade naa ni ọjọ Isẹgun, ogunjọ oṣù kẹwaa ọdun 2020 ni eto naa yoo bẹrẹ, ti yoo si pari l'ọjọbọ, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣù Kejila.

Ileesẹ ologun ni akanse eto ni Crocodile smile ọdun yii nitori ogun nla lo fẹ gbe ti iwa ọdaran lori ayelujara.

Akanse eto naa, to jẹ akọkọ tileese ologun kan yoo ṣe nilẹ Afirika, lo wa lati ṣe awari awọn eeyan to n kede iroyin aṣọdun lori ayelujara.

Bakan naa ni iroyin naa ni akanse eto yii yoo seranwọ lati sedamọ awọn ọmọ ikọ Boko Haram to n sa kuro lẹkun ila oorun ariwa Naijiria, lọ sáwọn agbegbe miran nitori báwọn ọmọ ologun ṣe n finna mọ wọn.

Ileesẹ ologun wa fọwọ sọya fun ifẹsẹmulẹ aabo ati alaafia to peye yika Naijiria, to si n beere atilẹyin araalu fun aseyọri akanse eto naa.