Dolapo Badmus: Abayomi Shogunle, Dolapo Badmus ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá-PSC

Oríṣun àwòrán, Pulse.ng
Iroyin kan jẹyọ lori ayelujara pe awọn ọlọpaa kan ti padanu iṣẹ wọn eleyi to ti wa di kale n kako lori ayelujara.
Ko si idi meji ti iroyin naa fi lu oju opo ayelujara pa ju pe orukọ awọn ilumọọka ọlọpaa meji kan wa nibẹ.
Abayọmi Shogunlẹ to jẹ olori ikọ agbohungbaroye (Police Public Complaint Unit) nileeṣẹ ọlọpaa tẹlẹ ati Dọlapọ Badmus to figbakan ri jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ati ni ẹkun keji, Zone II wa lara orukọ awọn mẹtadinlogoji ti wọn da oruks wọn sinu iwe naa.
- Buhari, Makinde, Sanwo-Olu kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí Tola Oyediran, àkọ́bí lóbìnrin tí Obafemi Awolowo bí tó papòdà
- Ẹ foríjìn wá ọmọ Nàìjíríà, mó mọ̀ pé ẹ̀ ń bínú tórí a kò tètè gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ EndSARS- Osinbajo
- Ìjọba Nàìjíríà ti gbà láti san N30b owó àjẹmọ́nú fún ASUU
- Wo ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí Gómìnà Obiano gbé lórí ọ̀rọ̀ SARS ní Anambra
Iroyin naa jade loju opo twitter @AyooAkanji ṣugbọn arakunrin A.A to ni oju opo Twitter naa ti jade lati ṣalaye pe aimọọsọ oun ni ko jẹ kawọn eeyan mọọ gbọ nitori pe kii ṣe awọn ti wọn le lẹnu iṣẹ ọlọpaa nikan lo wa ninu orukọ ti oun gbe sita.
O tubs yannana rẹ siwaju sii pe, Abayoọmi Shogunlẹ ati Dọlapọ Badmus ko si lara awọn ti wọn le lẹnu iṣẹ ọlọpaa, ara awọn ti wọn gba ni ikilọ atawọn ti wọn ja okun wọn ni awọn mejeeji yii wa.
Ẹwẹ, ajọ akoso ileeṣẹ ọlọpaaloriulẹede Naijiria, PSC naa ti ṣalaye pe awọn ko le ọlọpaa meji yii o.
Alukoro ajọ naa, Ikechukwu Ani ṣalaye fun awọn iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria pe iroyin ofege ni iroyin naa nitori pe ajọ naa ko tii joko ṣe ipade debi ti yoo maa le ẹnikẹni ni iṣẹ.








