Nigeria SWAT team, EndSars, End SWAT: Àfiwé owó oṣù ọlọ́oàá Nàìjíríà pẹ̀lú akẹgbẹ́ wọn lókè òkun

Oríṣun àwòrán, @NPolice
Se ileeṣẹ Ọlọpaa Naijira dabii gbogbo ileeṣẹ to ku ni?
Bii gbogbo ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri agbaye, iṣẹ nla l'awọn ọlọpaa Naijiria pẹlu n ṣe lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.
Bẹẹni kii ṣe owo oṣu kekere lo n ba iṣẹ yii wa l'awọn orilẹede miran lagbaye.
Titi di oṣu kewaa, ọdun 2020 ti a wa yii, eyi l'awọn orilẹede marun un to jẹ pe awọn ọlọpaa wọn lo n gbowo julọ lagbaye.
- Buhari, Makinde, Sanwo-Olu kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí Tola Oyediran, àkọ́bí lóbìnrin tí Obafemi Awolowo bí tó papòdà
- Báwo ni Donald Trump ṣè ń rí ọwọ́ mú sí nínú àkójọ èrò àwọn olùdìbò?
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 181 pẹ̀lú Olùkọ́ lùgbàdì Covid 19 níléèwé aláàdáni kan nípinlẹ̀ Eko
Bayii si ni ileeṣẹ ayelujara gẹgẹbi salaryexpert.com ṣe laa kalẹ.
1.Canada
Awọn ọlọpaa ni Canada lo gbowo julọ lagbaye.
Bii, ẹgbẹrun lona ọgọrun dọla owo ile Amẹrika, eyi to n ja si bii ogoji miliọnu naira lowo osu wọn lọdun.
Gigara ti owo osu wọn gara ko ṣẹyin awọn owo ajẹmọnu fun akanṣe iṣẹ bii ṣiṣe ẹsọ kaakiri fawon eeyan tabi ileeṣẹ.
Ọlọpaa to ba ṣẹṣẹ gba iṣẹ a maa gba owo osu to to aadọta ẹgbẹrun lọdun eyi to tumo si bii ogun miliọnu owo naira lọdun.
2.Switzerland:
Owo t'awon ọlọpaa n gba ni Switzerland le ni ẹgbẹrun lọna aadọrin dọla to tumọ si bii miliọnu mọkandinlọgbọn o le diẹ naira owo Naijiria.
3.United States:
Ni orilẹede Amẹrika, bii ọgọta ẹgbẹrun dola to jasi ẹgbẹrun mẹtalelogun naira l'awọn olopaa n gba bi o tile jẹ pe eyi a maa yatọ lati ipinlẹ si ipinlẹ ati bi iriri wọn lẹnu iṣẹ ba ti ṣe pẹ sii.
Awọn ọlọpaa ni ipinlẹ New York, California ati New Jersey lowo wọn gbe pẹẹli julọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
4.United Kingdom:
Bii ẹgbẹruun mọkandilogun si mẹtalelogun pọun owo ilẹ Gẹẹsi, Wales ati Northern Ireland lawọn Kọnstebu ọlọpaa n gba lodun ni ilẹ Gẹẹsi, Wales ati Northern Ireland.
Eyi to tumọ si bii miliọnu mẹsan abọ si mọkanla abọ naira.
Amosa, lapapọ, ni egbẹrun mọkanlelọgbọ̀n pọun iyẹn …..owo Naira, ni wọn n gba lọdun; iṣẹ wọn kii sii ju ogoji wakati lọlọsẹ.
5.Australia:
Lorilẹede Australia, nnkan bii ẹgbẹrun mejilelogoji dola lawọn ọlọpa n gba, wọn kii sii ṣe iṣẹ ju ogoji wakati lọ.
Bi iṣẹ ba wa gbomimu to fi kan pe ki wọn ṣe kọ ogoji wakati yii, o ṣeeṣe ki owo wọn tun gbe ẹnu soke ju eyi lọ
- Ìdí táwọn olùwọ́de EndSARS fi kọ oúnjẹ àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí MC Oluomo gbé wá rèé
- Wo nọ́mbà tí o le è pè láti gba owó gbà-má-bínú tí ọlọ́pàá bá fìyà jẹ ọ́ lọ́nà àìtọ́ l'Eko
- Ẹfunsetan Aniwura, ọmọ Ẹ̀gbá tó di akíkanjú obìnrin nílẹ̀ Ibadan
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de #EndSARS
Elo wa ni owo osu awọn ọlọpaa Naijiria?
Ọlọpaa Naijiria lo n gba owo to kere julọ
Ẹẹdẹgbẹsan dọla owo Amẹrika, iyen ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin o din diẹ Naira ni wọn fi n yanju bukata ile aye wọn lodun.
Eyi jasi dọla merin, ẹgbẹrun meji o din irinwo Naira lojumọ.
Igba o le aadọta ẹgbẹrun ni iye ọlọpaa to wa ni Naijiria lọwọlọwọ.
- Toyin Abraham tú àṣírí ohun tí ọlọ́pàá Náìjíríà sọ mọ́lẹ́bí rẹ̀ kan dà
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 181 pẹ̀lú Olùkọ́ lùgbàdì Covid 19 níléèwé aláàdáni kan nípinlẹ̀ Eko
- Ìdí táwọn olùwọ́de EndSARS fi kọ oúnjẹ àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí MC Oluomo gbé wá rèé
- Sọ̀rọ̀ sókè! Odunlade, Toyin, Ijebu dásí ìwọ́de #EndSARS, Mercy Aigbe gbébọn















