Ogbomosho shooting, End Sars, End SWAT: Isiaka Jimoh fi ọmọbìnrin kan àti ìyàwó tó lóyún sínú sílẹ̀ ló- Òbí Isiaka
Mo jiya pupọ lori Isiaka Jimoh ṣugbọn aye ko jẹ ki n jẹun ọmọ- Ramota, iya Isiaka Jimoh
Nibi iṣẹlẹ iwọde End Sars / End SWAT to gba gbogbo igboro Naijiria kan yii ni aṣita ibọn ti lọ ba Isiaka Jimoh ni ilu Ogbomosọ ni ipinlẹ oyo to wa ni guusu ila oorun Naijiria.
- Omijé fẹ́ bọ́ lójú mi tí mo bá ṣàfiwé SARS tí mo dá sílẹ̀ àti SARS tó wà níta báyìí- Fulani Kwajafa
- Ohun tí ojú ìyàwó mi rí lọ́wọ́ SARS kò ṣe é fẹnusọ- Poju Oyemade
- Kìí ṣe gbogbo ohun tí dókìtà ni kí n má jẹ torí àìsàn jẹjẹrẹ ni mo tẹ̀lé- Soyinka
- Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS / end SWAT lárinrin àti ìtumọ̀
Iya Isiaka, Ramota Jimoh ke si araye lati ṣaanu oun ki iku Isiaka ma ja si asan lori iwọde titako iwa ifiyajẹni lọna aitọ awọn agbofinro.
Baba Isiaka, Jimoh atanda ṣalaye pe gbogbo awọn lawọn fi ẹjẹ silẹ fun Isiaka ni ile iwosan fasiti Bowen ko to di pe ọlọjọ mu u lọ.
Wọn ni ibi iṣẹ ni Isiaka ti n bọ nirọle o ku ọla to maa gba ominira lẹnu iṣẹ ina to n kọ ni Ogbomoso.
Wọn ni Isiaka fi omobinrin kan ati iyawo to wa ninu oyun silẹ lọ.
Akowe Oba soun Ogbomosho, Ogbeni Toyin Ajamu naa sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ gangan lọjọ yẹn.
O ni Sunday Dare to jẹ minista ọrọ ọdọ naa wa si aafin fun ipade lori ọrọ iwọde yii naa ni.
Ki Olorun tu ẹbi Isiaka Jimoh ninu lo ku bayii.
- Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram
- Ìdí táwọn olùwọ́de EndSARS fi kọ oúnjẹ àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí MC Oluomo gbé wá rèé
- Wo nọ́mbà tí o le è pè láti gba owó gbà-má-bínú tí ọlọ́pàá bá fìyà jẹ ọ́ lọ́nà àìtọ́ l'Eko
- Tola Oyediran ọmọ Obafemi Awolowo ti jáde láyé
- Àwọn olùwọ́de ṣetán láti bá mínísítà FCT Abuja wọ̀ ṣòkòtò kan lórí àṣẹ má ṣe ìwọ̀de
