Lagos, Delta Curfew: Sanwo Olu ní kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba padà sẹ́nu iṣẹ́ ní Eko, Delta sọ tirẹ̀ dí aago mẹ́jọ alẹ́ sí mẹ́fà ìdájí

Sanwo olu ati Okowa

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Gomina Bababjide Sanwo Olu to n tukọ ipinlẹ Eko ti kede pe ki awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko pada sẹnu iṣẹ lọjọ keji, oṣu kọkanla.

Eyi tumọ si pe awọn oṣiṣẹ ipele kini si ikejila to ti wa nile tẹlẹ latari ọna lati dẹkun itankalẹ ajakalẹ arun coronavirus ni iṣẹ ti bẹrẹ pada fun bayii.

Lati oṣu kẹta ni awọn oṣiṣẹ yii ti n ṣiṣẹ lati ile nitori Covid 19.

Iwe aṣẹ ipadabọ sẹnu iṣẹ naa to ni nọmba Ref. No: CIR/HOS/'20/Vol.1/115, ni adari awọn osise nipinlẹ Eko, Muri Okunọla fi ọwọ si.

Kini Gomina Okowa kede ni ipinlẹ Delta lori konileogbele?

Ijọba ipinlẹ Delta naa ti dẹwọ okun isede ti wọn naa.

Lọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii ni Gomina Okow kede isede latari biba nkan ilu jẹ nipinlẹ naa.

Saaju ni isede naa wa l;ati aago mẹfa irọle si aago mẹjọ aarọ ṣugbọn ijọba ti dẹwọ rẹ bayii si aago mẹjọ alẹ si aago mẹfa idaji.

Kọmiṣọnna fun ifitonileti ni ipinlẹ Delta, Charles Aniagwu lo kede asiko tuntun naa lẹyin to dupẹ lọwọ awọn olugbe ibẹ si bi wọn ṣe tẹle ofin isede fun aabo ẹmi ati dukia.

Àkọlé fídíò, John Amanam: Ìfẹ́ tí mo ní sí àbúrò mi ló sọ mi dí ẹni tó ń ṣe 'Prosthetic' báyìí

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin:

Gómìnà Sanwo-Olu dẹ okùn ìséde l'Eko, ó gbé ìlànà tuntun jáde:

Aago mẹ́wàá alẹ́ sì mẹ́fà àárọ̀ ni ìséde yóò ma wáyé

Ijọba ipinlẹ Eko tun ti dẹ ọwọ okun ofin konile o gbele to n waye nipinlẹ Eko.

Atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Eko fisita lọjọ Etí kede pe ofin konile o gbele naa yoo maa mulẹ bayii lati aago mẹwa alẹ si mẹfa owurọ.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Atẹjade naa, ti Kọmisana feto iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso fọwọsi, wa rọ awọn ara Eko lati maa ba ọrọ aje wọn lọ ni alaafia lai fa ijangbọn rara.

Bakan naa lo ni Gomina Babajide Sanwo-Olu gboriyin fáwọn olugbe Eko fun bi wọn ṣe tẹle asẹ konile o gbele naa, eyi to mu ki alaafia pada sipinlẹ naa lẹyin rogbodiyan iwọde EndSARS.

Gomina Sanwo-Olu tun rọ araalu ta kete sáwọn iroyin eke to le da omi alaafia ipinlẹ naa ru.

Ọjọ Aiku to kọja ni ijọba ti kọkọ dẹ okun aṣẹ konile-o-gbele to n ṣiṣẹ lọwọ ni ipinlẹ naa.

Ninu ikede to fi sita lori ayelujara Twitter, Akọwe ikede fun Gomina Babajide Sanwo-Olu, Gboyega Akosile, sọ pe aago mẹjọ alẹ si mẹfa idaji ni isede yoo ma a wa bayii.

Ọjọ Iṣẹgun to kọja ni ijọba kede isede ataarọ di alẹ, nitori rogbodiyan iwọde #ENDSARS.

Lẹyin naa lo kede ni ọjọ Ẹti pe isede naa ti yi pada si aago mẹfa irọle si mẹjọ owurọ.

Ṣugbọn ṣa, Akosile kede pe awọn ileewe ijọba yoo ṣi wa ni titi pa.

Gomina Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Twitter/gboyega akosile

Wo àwọn ìpínlẹ̀ tó ti dẹwọ́ ìséde lẹ́yìn ìwọ́de #EndSars

Awọn ipinlẹ meji ni o ti paṣẹ ki ofin konile o- gbele rọlẹ lagbegbe wọn lẹyin ti wọn paṣẹ ofin naa lasiko ti rogbodiyan gbode kan nitori ifẹhọnuhan EndSars to gbode kan ni awon ipinle Naijiria.

Laipẹ yii ni ipinle bii Eko, Ondo, Ekiti, Edo, Delta ati Plateau paṣẹ ki ofin konile o-gbele gberasọ nibẹ nitori jagidijangan to bẹẹsilẹ kaakiri, ti wọn si bẹrẹ si ni pa awọn eniyan pẹlu awọn dukia ti wọn bajẹ kaakiri ipinlẹ naa.Àwọn Jàǹdùkú yabo ilé ìkó-ǹkan-pamọ́ sí, wọ́n kò 'Covid 19 Palliative" lọ ní Eko

Nibayii, ipinlẹ Edo ati Plateau ti jẹ ki ofin konile o-gbele rọlẹ si ni awọn ipinlẹ naa.

Wo awọn ipinlẹ̀ naa:

Ipinlẹ Plateau:

Ni ipinlẹ Plateau, ijọba ipinlẹ naa ti ni ki ofin konile o-gbele o rọlẹ si nipinlẹ naa, paapaa ni agbegbe ijọba ibilẹ Ariwa ati Guusu Jos nipinlẹ naa.

Gomina Simon Lalong ti wa paṣẹ pe ofin konile o-gbele naa yoo wa lati aago mẹjọ alẹ, ki awọn eniyan ba le raye lọ si ibi iṣẹ wọn lai si idaduro lori rẹ.

Gomina Lalong wa rọ awọn ọmọ ipinlẹ naa lati gba alaafia laye, ki eto ijọba tiwantiwa le gbooro si lagbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

Ipinlẹ Edo:

Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti paṣẹ ki ofin konile o-gbele ọlọjọyipo o rọlẹ si ni ipinlẹ naa lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ.

Nibayii, aago mẹrin irọlẹ si aago mẹfa aarọ ni ofin konile-o gbele naa yoo ma waye lati Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹwaa fun ọjọ mẹta gbako.

Ijọba ipinlẹ Edo wa rọ awọn ara ipinlẹ Edo lati gba alaafia laaye , ẹmi ati dukia awọn eniyan le wa lalaafia kaakiri ipinlẹ naa.

Mo fura pé ẹ fẹ́ da Nàíjíríà rú, ń kò ṣe ìwọ́de mọ́ - Segalink, agbátẹrù ìwọ́de yọwọ́

End SARS Protest: Segalink yọ ara rẹ̀ kúrò nínú ìfẹ̀họ́núhàn EndSARS

Ajafẹtọ ọmọniyan, Segun 'Segalink' Awosanya ti yọ ara rẹ kuro ninu ifẹhọnuhan EndSars to n lọ lọwọ.

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti bẹrẹ si ni fesi si igbeṣẹ Segun Awosanya to bu ẹnu atẹ lu ifẹhọnuhan EndSARS to n lọ lọwọ.

Segalink ni ọpọ eeyan gba pe o jẹ ọkan lara awọn ọdọ to n se agbatẹru iwọde EndSARs, to si tun jẹ adari fun awọn afẹhọ̀nuhan to tako ifiyajẹni awọn ọlọpaa ni ọdun 2017,

Segalink loju opo Twitter rẹ ni aarọ ọjọ Aje, lo kede pe oun ko lọwọ ninu iwọde naa mọ nitori oun n fura pe awọn eeyan kan ti n gbe igbesẹ lati da orilẹede Naijiria ru.

Segalink ni awọn to n sagbẹtẹru fun Endsars naa, paapaa awọn to wa ni oke okun, kọ lati gbọ ọrọ lẹnu ijọba, eleyii ti oun ri gẹgẹ bi iditẹ mọ ijọba.

O fikun wi pe ki awọn afẹhọnuhan murasilẹ lati koju ijọba lori igbesẹ ti wọn gunle.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Amọ, igbesẹ rẹ yii ko dun mọ awọn afẹhọnuhan ninu nitori wọn ri gẹgẹ bi ọkan gboogi ninu awọn ti wọn n wo bi awokọṣe ni awujọ.

Lara awọn to fun lesi ni oju opo Twitter naa ni, Segun fẹran lati jẹ gaba lori awọn eniyan, nitori naa ni wọn ko ṣe gbọran si i lẹnu.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bẹẹ ni awọn kan rọ Segun Awosanya lati tun ero rẹ pa nitori awọn ni igbagbọ ninu rẹ, ti awọn ko si fẹ ki o yipada kuro lẹyin awọn.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Amọ, awọn miran kesi awọnn afẹhọnuhan naa lati gbọ ọrọ si Sega lẹnu, nitori pe adari wọn ni.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Bakan naa ni awọn kan rọ awọn eniyan lati maṣe kẹgan ohun ti Sẹgun sọ, nitori o ṣeeṣe ki ijọba ti dunkoko mọ nitori pe o ṣe agbatẹru fun EndSars.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Awọn afẹhọnuhan naa ri iwọde ti wọn n ṣe gẹgẹ bi ọna lati fi opin si ifiyajẹni ati iṣekupani awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria.

Bi o tilẹjẹpe ijọba ni awọn ti gbọ ọrọ si awọn ọdọ lẹnu, amọ awọn oluwode naa ni kii ṣe igba akọkọ niyii ti ijọba yoo gbesẹle ikọ ọlọpaa, amọ ti wọn yoo ṣi mọ ọ ṣọṣẹ.

Jàǹdùkú ló fẹ́ pa mí, kìí ṣàwọn ọ̀dọ́ tó dìbò yàn mí bíi gómìnà - Oyetola

Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti sọ pe, awọn janduku kan lo gbiyanju lati gba ẹmi oun, nibi rogbodiyan iwọde End SARS to waye ni ilu Osogbo lọjọ Satide.

Oyetola lo fi ọrọ naa lede ninu igbohunsafẹfẹ to ṣe laarọ ọjọ Isinmi to tẹlẹ iwọde ọhun.

Awọn ọkọ ti wọn bajẹ

Oríṣun àwòrán, Ismaila Omipidan x Asp Seyi /Facebook

Gomina ọhun sọ pe, bi ikọlu naa ṣe waye fihan pe awọn janduku naa mọọmọ kọlu oun ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo ni iwadii ti ijọba ṣe ti fihan pe, ibọn tabi gaasi tajutaju ko ba ikankan lara awọn janduku naa.

O ni "Wọn ko yin ibọn tabi tajutaju si awọn janduku ọhun, nitori naa, ẹmi ẹnikẹni ko sọnu nibi ti iwọde ọhun ti waye."

Bo tilẹ jẹ pe Oyetola ni ootọ ni pe ẹmi eeyan meji bọ lọjọ naa, ṣugbọn o fi kun pe, ko si otitọ ninu iroyin to sọ pe eeyan meji ku nibi iwọde ti wọn ti kọlu oun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "Ẹni akọkọ gbẹmi mi ninu ijamba alupupu ni nnkan bi aago mejila ọsan, ki n to de ibi ti iwọde naa ti waye."

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ọ̀nà tí o lè gbà láti di ọjọ́ ogbó pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ

"Nigba ti iku ẹni keji waye ni nnkan bii kilomita marun un si agbegbe iwọde ọhun."

Oyetola ni oun gbagbe pe kii ṣe awọn ọdọ to dibo yan oun sipo gomina, ni yoo tun gbiyanju lati gba ẹmi oun, nitori kii ṣe igba akọkọ ti wọn yoo ṣe iwọde ree.

Gomina naa ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lati mọ bi awọn janduku ṣe ri aye wọ aarin awọn to n ṣe iwọde alaafia wọn.

Oyetola pari ọrọ rẹ pe ijọba oun wa lẹyin awọn oluwọde naa digbi lati igba ti wọn ti bẹrẹ fehonu han wọn.

Lẹyin naa lo wa rọ awọn ọmọ ipinlẹ ọmọluabi lati maa ṣe ohun gbogbo ni ẹsọ pẹlẹ, ati pe ijọba yoo mu eto abo awọn eeyan naa ni ọkunkundun.

Àkọlé fídíò, Ogbomsho shooting, End Sars, End SWAT: Isiaka fi ọmọbìnrin kan àti ìyàwó tó lóyún sínú síl

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Davido sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Oyetola lẹ́yìn rògbòdìyàn tó wáyé níbi ìwọ́de End SARS Osogbo

Olorin takasufe, David Adeleke ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Davido ti sọ oko ọrọ si gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola lẹyin ti eeyan meji padanu ẹmi wọn nibi iwọde End SARS to waye ni ilu Osogbo.

Ṣaaju ni Oyetola ti kọkọ darapọ mọ awọn oluwọde naa lagbegbe Alekuwodo to si n ba awọn eeyan naa kọrin, pẹlu ileri pe gbogbo ẹdun wọn ni oun yoo gbe yẹwo ki awọn janduku to da iwọde ọhun ru.

Rogbodiyan to bẹ silẹ lojuko iwọde naa mu ẹmi eeyan meji lọ, koda ori lo ko gomina Oyetola ati awọn ẹmẹwa rẹ yọ nibi iwọde lọwọ oko ti awọnj eeyan ọhun n sọ si wọn.

Ko pẹ ti ti fọran rogbodiyan naa jade lori ayelujara ti Davido fi ọrọ ranṣẹ si Oyetola.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

O ni "Oyetola, o ti ja awọn eeyan ipinlẹ Osun ti o n ṣejọba le lori kulẹ lẹyin ti awọn janduku kọlu awọn to n ṣe iwọde."

Lẹyin naa lo sọ pe ko si idukoko kankan to le e da omi tuntun to n ru bo duro.

Oyetola/Davido

Oríṣun àwòrán, Davido/@SeyiTunbi

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Àwọn jàǹdùkú kọlu gómìnà Oyetola, 'èèyàn méjì kú' níbi ìwọ́de l'Osogbo

Ori lo ko gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla yọ lasiko to fi lọ darapọ mọ awọn oluwọde ENDSARS nilu Osogbo.

Ọpọlọpọ awọn ọkọ to baa kọwọrin ni wọn kọlu ti wọn si bajẹ kọja ala.

Gomina Oyetọla darapọ mọ awọn oluwọde naa lẹnu irin ti wọn n rin lati agbegbe Alekuwọdo si Ọlaiya to si n ba wọn kọrin pẹlu ileri pe gbogbo ẹdun wọn ni oun yoo gbe yẹwo.

O fi kun un pe ifẹhonu han alaafia ni oun fẹ eleyi to ni ko ṣajeji si ilana ijọba awarawa.

Amọṣa ọrọ ni gomina ṣi n ba awọn oluwọde naa sọ to fi di pe awọn janduku kan bẹrẹ si ni kọlu ti wọn si n yinbọn pẹlu okuta si ọkọ gomina naa.

Awọnamugbalẹgbẹ gomina ṣalaye fun BBC News pe gomina Oyetọla ati igbakeji rẹ ye iṣẹlẹ naa laifarapa ṣugbọn akọroyin kan atawọn amugbalẹgbẹ gomina naa kan fara ṣeṣe.

Bakan naa ni o fidi rẹ mulẹ pe awọn oluwọde naa kọ lo kọlu gomina Oyetọla ati iks rẹ bi ko ṣe awọn janduku.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan n gbe iroyin pe eeyan meji lo ku sinu ikọlu naa, ṣugbọn awọn agbẹnusọ fun ijsba ṣalaye pe, ijamba ọkada lo mu ẹmi wọn lọ ṣaaju ikslu naa.

Àkọlé fídíò, nnnnnn

Ṣaaju ikọlu naa lo ti jẹ ko di mimọ fun awọn ọdọ to n wọde naa pe gbogbo awọn to ba fara ṣeṣe lasiko ikọlu awọn janduku sawọn to ba n ṣewọde ENDSARS ni ipinlẹ naa ni ijọba yoo gbọ bukata owo itọju wọn.

Op si jẹ ko di mimọ pe aarẹ ti paṣẹ fun gbogbo awọn gomina lati da igbimọ oluwadi silẹ lati boju wo awọn ẹsun aṣemaṣe gbogbo ti wọn ba fi kan iks SARS ni ipinlẹ koowa wọn.

titi di bi a ṣe n sọrọ yii ileeṣẹ ọlọpaa ati ijọba ipinlẹ Ọṣun ko tii ṣọ̀ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.