2nd wave Coronavirus Update: England kéde ìséde ọ̀sẹ́ mẹ́rin níràn láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ Covid 19

Boris Johnson

Aṣoju ilẹ UK, Boris Johnson ti kede isede ẹlẹekeji ni England lati dẹkun itankalẹ ajakalẹ arun coronavirus.

O ni ọdun keresimesi ti 2020 yoo yatọ si ti awọn to ti n waye sẹyin.

Boris Johnson ni ikede yii yoo dola ẹmi to pọ nitori pe ẹni to ba wa laye lo maa n ṣọdun.

Koda, ijọba ni ile ounjẹ, ile ero, ibudo ere idaraya ati awọn ṣọọbu itaja ti ko ta nkan ko ṣe e malo yoo wa ni titi pa.

Sugbọn ile iwe yoo si wa ni sisi ki wọn si maa tẹle awọn ofin itankalẹ arun Covid 19.

Àkọlé fídíò, John Amanam: Ìfẹ́ tí mo ní sí àbúrò mi ló sọ mi dí ẹni tó ń ṣe 'Prosthetic' báyìí

Boris Johnson ni lati ọjọ keji, oṣu kejila ọdun 2020 ni wọn yoo dẹwọ isede naa

O si gbadura pe ki Olorun fi aanu han lagbaye bayii pẹlu imọran pe o san ki ọdun keresimesi yatọ pẹlu igbesẹ akin yii ki ẹbi le pada ṣajọyọ ọdun papọ.

Boris Johnson ni isede naa ko ni idije Premier League duro ṣugbọn ko ni si ero iworan nibẹ.

Àkọlé fídíò, Ogbomsho shooting, End Sars, End SWAT: Isiaka fi ọmọbìnrin kan àti ìyàwó tó lóyún sínú síl