James Bond: Gbajúgbajà òṣèré, Sean Connery tó ṣe fíìmù James Bond tí jáde láyé lẹ́ní ọdún 90

Oríṣun àwòrán, PA Media
Gbajugbaja oṣere, Sean Connery ti gbogbo eniyan mọ si James Bond gẹgẹ bi orukọ ere to ṣe ti jade laye ni ẹni aadọrun ọdun.
Oṣere Ilẹ Gẹẹsi naa ni o di ilumọọka nitori ipa to ko ninu fiimu James Bond to si kaakiri agbaye nitori ipa akọni to ko ninu ere naa.
Awọn ẹbi rẹ ni o sun ni ko ji mọ ni ile rẹ to wa ni Bahamas.
Amọ iroyin kan gbe e pe o ti n saarẹ fun igba diẹ sẹyin.
- Baldness: Àwọn tí irun wọ́n ti gbá rìfáàsì sọ ìrírí wọn àti àǹfàní tí wọ́n ń jẹ
- Alága ìjọba ìbílẹ̀ Iganna, Jacod Adeleke ti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn ajínígbé - Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo
- Wumi Toriọla ti sọ̀rọ̀ sóke láti fi idí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun àti ọ̀rẹ́ òun níjà
- Ọlọ́pàááá! Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ kíá bí bẹ́ẹ̀ kọ́... Àmọ́ ẹ ríi pé ẹ dáàbò bo ẹ̀mí yín - Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
- Wo ojú àwọn òṣèré yìí láì lo "Make-up" orí ìtàgé bó ṣe rí gẹ́lẹ́
Ọpọlọpọ ọdun lo ti fi kopa ninu awọn fiimu to lamilaaka, to si ti gba ami ẹyẹ Oscar, ami ẹyẹ Bafta lẹẹmeji ati Ami ẹyẹ Golden Globe ni ẹẹmẹta.
Lara awọn fiimu to ti kopa ninu rẹ ni "Diamonds are Forever," ''Hunter for red'' , ''October'', ''Indiana Jones'' , ''Last Crusader'' ati ''Rock''.
Titit di oni ni awọn eniyan ṣi n ri gẹgẹ bi oṣere to datọ julọ lati se bii oṣere 007.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọdun 1988 ni o gba ami ẹyẹ Oscar gẹgẹ bi oṣere to jẹ oluranlọwọ pataki ninu fiimu '' The Untouchables'', to si se bi ọlọpaa ile Ireland nibẹ.
Ọdun 2000 ni Ọbabinrin Ilẹ Gẹẹsi fun un ni Ami Ẹ̀yẹ ''Knight'' ti aafin Holyrood Palace.
Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 yii ni Sean Connery ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ẹni aadọrun ọdun lori ilẹ aye ko to di wi pe o di oloogbe.












