Oyo Politics: Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo jáwée lọ sinmi nílé fún alága ìgbìmọ̀ mẹ́tàlá káàkiri ìjọba ìpínlẹ̀

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti kede lọjọ Iṣẹgun pe wọn jawe lọ sinmi nile diẹ fun awọn alaga fidihẹ mẹtala lawọn ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Oyo.

Idaduro ti ko ni gbedeke yii da lori pe wọn ko tẹle ohun ti ile fẹnuko le lori nipa ipo ti kiko awọn irinṣẹ kọọkan lati sakani wọn pada lọ sile aṣofin.

Awọn ijọba ibilẹ ti igbesẹ yii ta ba ni:

Akinyele East LCDA; Ido LG; Oluyole LG; Ibadan North East LG; Lagelu West LCDA; Soro LCDA ati Ogbomosho Central LCDA.

Awọn to tun kan ni:

Ogbomosho South LCDA; Ajorosun LCDA; Ibarapa North West LCDA; Itesiwaju LG; Oyo East LG ati Oyo South East LCDA.

Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ afurasí mẹ́ta tó lọ́wọ́ nínú ìjínigbé alága Iganna l'Oyo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fi panpẹ wọn mu eeyan mẹta lara awọn ti wọn furasi pe wọn lọwọ ninu ijinigbe alaga kansu kan ṇi ipinlẹ Oyo.

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lo fi eyi hande nigba to n ba awọn lọga lọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa sọrọ ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Eleyele, Ibadan lọjọ Aje.

ctu

Oríṣun àwòrán, @Newsweek

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa o tii fi ẹkunrẹrẹ sita lori bi ọwọ ṣe tẹ̀ wọn, Gomina Seyi Makinde gboriyin fun awọn ọlọpaa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.

Bi ẹ ko ba gbagbe, wọn kede iroyin ijinigbe alaga kansu Iganna nipinlẹ Oyo, ọgbẹni Jacob Adeleke ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwaa.

Atoun ati dẹrẹba rẹ ni wọn jigbe nirọlẹ ọjọ Aiku loju ọna Iseyin-Ado nigba ti wọn n lọ si Ibadan fun ipade kan pẹlu Gomina Seyi Makinde lowurọ ọjọ Aje.

Àkọlé fídíò, EndSars, EndSwat Protest: Òbí agbábọ̀ọ̀lù Gbenga Tiamiyu Kaka àtàwọn míì tí ọlapàá pa sọ̀r

Ẹwẹ, ikede jade pe wọn ti gba itusilẹ lọjọ Ẹti, ọgbọnjọ Oṣu kẹwaa.

Ko si aridaju boya wọn san owo itanran kankan lati mu ki itusilẹ wọn ya kiakia.

soja meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kini o kọkọ ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ji alaga kansu gbe tẹlẹ?

Ẹ wo bí orílẹ̀èdè Amẹrika ṣe dóòlà ẹ̀mí ọmọ ilẹ̀ wọn tí wọ́n jígbé ní Naijiria

US Citizen Rescue: Ẹ wo bí orílẹ̀èdè Amẹrika ṣe dóòlà ẹ̀mí ọmọ ilẹ̀ wọn tí wọ́n jígbé ní Naijiria

Ọ̀sẹ yii ni wọn ji arakunrin Philip Walton gbe ni iha ariwa orilẹede Naijiria.

Ikọ ọmoogun orilede Amẹrika ti doola ẹmi ọmọ orilede wọn ti wọn jigbe ni iha ẹkun ariwa orilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bi atẹjade ti awọn alaṣẹ orilẹede Amerika fi lede, arakunrin ti wọn jigbe naa, ti orukọ rẹ n jẹ Philip Walton lo n ṣiṣẹ agbẹ lorilede Naijiria.

Awọn alaṣẹ naa ni awọn ajinigbe naa ko ṣiṣẹ fun ẹgbẹ agbesunmọmi kankan, amọn awọn agbebọn ti wọn n wa owo ni.

Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kẹtadinlọgbọn ni wọn ji arakunrin Walton gbe ninu ile rẹ ti ko jina si ibode Niger.

Orilẹede Amerika naa ni awọn ko ni kuna lati ma a da abo bo awọn ọmọ orilẹede wọn kaakiri ibi ti wọn ba wa ni agbaye.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa ni wọn dupẹ lọwọ ijọba orilẹede Naijiria fun ifọwọsowọpọ wọn to jẹ ki idoola ẹmi naa ṣeeṣe.

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Iganna, Jacod Adeleke ti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn ajínígbé - Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti fidi rẹ mulẹ pe alaga fidihẹ ijọba ibilẹ Iganna, Jacob Adeleke ati awakọ rẹ ti gba ominira lọwọ awọn ajinigbe.

Wọn ji awọn eeyan naa gbe nigba ti wọn n rinrin ajo lọna to wọ ilu Ibadan ni nnkan bi ọjọ mẹfa sẹyin.

IGP

Oríṣun àwòrán, @PulseNigeria247

Ṣaaju ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọmọ ẹgbe Vigilante Group of Nigeria ti n wa inu igbo ti wọn fura si pe awọn ajigbe ọhun ti n ṣọṣẹ.

Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sọ fun awọn akọroyin pe,l lootọ nio ọkunrin naa ti gba ominira, o si ti darapọ mọ awọn ẹbi rẹ.

ctu

Oríṣun àwòrán, @Newsweek

Wọn ji alaga ọhun ati awakọ rẹ gbe ni opopona Okeho-Ado Awaye, iyẹ ni ipinlẹ Oyo lasiko to n mura lati ṣe ipade pẹlu gomina Seyi Makinde.

Àkọlé fídíò, Tóo bá pá lórí, Mílíìkì sóyà àtàwọn ǹkan mẹ́ta yìí leè mú irun rẹ hù padà!

Iroyin ni awọn ajinigbe naa bere pe awọn yoo gba owo ti iye rẹ to igba miliọnu naira ki wọn to tu awọn eeyan naa silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeji ti gba ominira bayii, a ko lee fidi rẹ mulẹ boya alaga naa tabi awọn ẹbi rẹ san owo ọhun ki wọn to gba ominira.