US presidential election 2020: Iye owó tí ìjọba Amẹrika ń ná sí ìdìbò Ààrẹ rèé

Graphic showing Capitol building with price tag

Ara ọtọ ni idibo Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika ọdun yii yoo gba nitori ajakalẹ arun Coronavirus, ṣugbọn orilẹ-ede naa naa yoo na obitibiti owo si eto idibo ti yoo waye lọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.

Ni ọdun 2016, $6.5 biliọnu ni wọn fi ṣeto idibo l'Amẹrika.

Gẹgẹ bi iwadii ti BBC Reality Check ṣe, ninu idibo ọdun 2000, 2004, 2008 ati 2016, awọn oludije owo ti iye rẹ ko din ni biliọnu meji dọla lori eto idibo Aarẹ.

Idaji owo ọhun ni wọn na lati fi ṣe ipolongo lori ẹrọ tẹlifiṣọn ati lori awọn ikani miran.

Iroyin sọ pe ikọ ipolongo Aarẹ Donald Trump na obitibiti owo fun ipolongo lori Super Bowl loṣu keji ọdun 2020.

Ẹwẹ, awọn oludije naa tun maa n na owo fun ipolongo lori ayelujara lati lee kan si awọn eeyan to wa lori itakun ikansiraẹni bii Twitter, Facebook, Instagram, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Trump MAGA hat

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nibo ni awọn owo wọnyii ti n wa?

Pupọ ninu awọn owo naa lo n wa lati ọwọ eeyan to maa n gbe owo kalẹ gẹgẹ agbatẹru oludije.

Iwadii fi han pe awọn eeyan bi igba lo gbe nnkan biliọnu kan dọla kalẹ fun idibo Aarẹ ọdun 2016.

Trump and Joe Biden

Oríṣun àwòrán, Reuters

Bakan naa ni awọn baba olowo miran maa n pe apejẹ lati fi ko owo jọ fun oludije ti wọn nifẹ si.

Lara awọn ilana to rọ mọ ikowojọ fuun oloṣelu ni pe ọmọ ilẹ Amẹrika nikan lo ni anfani lati lọwọ si irufẹ ikowojọ bẹẹ.

Bẹẹ ni eeyan kan ṣoṣo ko lee gbe ju $2,800 silẹ lọ.