US election 2020: Olórí àwọn òṣìṣẹ́ Trump sọ pé ìjọba ilẹ̀ America kò le kápá coronavirus

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Donald Trump/Twitter

Ọkan Pataki lara awọn amugbalẹgbẹ Aarẹ Donald Trump ti sọ pe orilẹ-ede Amẹrika ko lagbara lati koju ajakalẹ arun Covid-19.

Olori oṣiṣẹ Aarẹ ni White House, Mike Meadows lo kede ọrọ naa nigba to sọ pe abẹrẹ ajẹsara nikan nii ọna abayọ.

Ọrọ ti Meadows sọ ọrọ naa n waye lasiko ti arun naa n gbilẹ si l'Amẹrika, paapaa bo eto idibo aarẹ ṣe ku ọjọ mẹsan.

Ṣaaju ni oludije sipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Democrat, Joe Biden ti sọ pe ẹgbẹ Republican ti n ṣafihan ijakulẹ ninu idibo naa to n bọ laipẹ.

Biden ni ọrọ ti ọgbẹni Meadows sọ n ṣapẹrẹ pe, ijọba Trump ti gba kadara pe wọn ti kuna lori ojuṣe wọn lati daabo bo awọn eeyan ilẹ Amerika.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin CNN, Meadows sọ pe, o soro lati mojuto arun naa nitori o rọrun fun lati tan kalẹ bi ọfinkin.

Ko din ni 225,000 eeyan ilẹ Amẹrika to ti dagbere faye nitori arun Covid-19, eyi to jẹ iye eeyan to pọ ju lagbaye.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ti fasiti John Hopkins fi sita, o le ni ẹgbẹrun mẹtalelọgọrin eeyan to lo fara kasa arun ọhun lọjọ Abamẹta nikan ṣoṣo.

Ṣaaju akoko naa, iye eeyan to ni arun naa to pọ ju lọjọ kan ṣoṣo jẹ ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin, ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje ọdun 2020.