Joe Biden: Ṣé ó lè fẹ̀yìn Trump kó di ààrẹ America tó kàn?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Joe biden ni ọkunrin naa to ta a tan siwaju aarẹ Donald Trump ati saa ọdun mẹrin kan sii to fẹ lo ni Ile nla funfun White House gẹgẹ bi wọn ṣe n pe e lorilẹede Amẹrika.
Oun ni egungun ẹja to n ha Trump lọrun ninu eto oṣelu Amẹrika lọwọ lọwọ bayii.
Igbakeji aarẹ Barack Obama tẹlẹ ri yii ni wọn yan gẹgẹ bi oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Democratic fun idibo inu oṣu kọkanla.
Loju awọn alatilẹyin rẹ, o jẹ akọṣẹmọṣ ninu aatọ ọrọ ilẹ okere pẹlu iriri ọlọdun gbọrọ ni ilu Washington, ẹnu rẹ dun mọran-mọran pẹlu ọrọ sisọ nita gbangba eyi to n fa oju eeyan mọra to fi mọ koda ẹni ti ko rọwọ họri lawujọ o si tun jẹ eeyan kan toun funrarẹ ti jẹya ri laye.
Loju awọn alatako rẹ, o jẹ oni gale gale eniyan to ko maa n sọ ọrọ to lee doju ti ni gidi gan atawọn ọr alufansa si eeyan (koda wọn ni o fẹran ko maa fa oorun ara irun obinrin simu).
Ṣe o wa to gbangbaa sun lọyẹ lati yẹ aga mọ aarẹ Trump nidii ni White House?
Ẹlẹ́nu yíyá lọ́rọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty
Biden kii ṣe ajoji lawọn ibi ipolongo idibo - o kara bọ eyi niluu Washington lọdun mẹ́tadinlaadọta sẹyin - 1973, ipolongo rẹ akọkọ fun ipo aarẹ lọdun 1987.
Bo ṣe lee ko ifẹ rẹ sori awọn oludibo naa lo ṣe jẹ eeyan to lee ma pẹ da wahala silẹ.
Bi o ṣe gbagbe ara nigba to n sọrọ niwaju ero pupọ lo mu opin de ba ipolongo akọkọ rẹ fun ipo aarẹ (eyi si ni igbakẹta) ki o tilẹ to bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Nibi awọn iwọde ṣe lo br si nii bọ: "awọn baba nla baba mi ṣiṣẹ ni ile iṣẹ eedu north-east Pennsylvania" ati pe inu tun bi i pe wọn ko ri iru anfani to wu wọn jẹ laye.
Ṣugbọn ko si baba nla rẹ kankan to jẹ awa eedu - o kan ji ọrọ yẹn ati ọpọlọpọ mii lo ni latinu ọrọ oloṣelu ilẹ Britain kan, Neil Kinnock, eyi ti awọn mọlẹbi rẹ jẹ awa eedu.
Iyẹn dẹ lo jẹ akọkọ ninu ọpọlọpọ ti wọn wa n pe "awọn ado oloro ti Joe".
Nigba to fi iriri ara rẹ ninu oṣelu yangan lọdun 2012, o sọ fun awọn ero ti o da bii pe ọrọ ko ye pe "ẹyin eeyan mi, mo le sọ fun yin pe mo ti mọ aarẹ mẹjọ, mo si mọ mẹta ninu wọn denu denu", ohun to si n sọ nibi ni pe o ti ba wọn lopọ ri dipo pe wọn kan jọ jẹ ọrẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Gẹgẹ bi igbakeji aarẹ Obama lọdun 2009, ori kan yan an ni lo fi jẹ eeyan alawọdudu akọkọ to jọ dije dupo gẹgẹ bi aarẹ ati igbakeji pẹlu Obama.
Lai wo eyi, atilẹyin ti Biden n ri laarin awọn oludibo alawọdudu pọ jọjọ lasiko idibo aarẹ ti o fẹ waye yii ṣugbọn laipẹ yii , tun sọ ọrọ to da ilẹ ru lori eto ori rdio kan to ti sọ pe "iwọ too ba niṣoro pe o fẹ mọ boya emi ni waa dibo fun tabi Trump, iyẹn nipe oo ki n ṣe alawọdudu.

Oríṣun àwòrán, THE BREAKFAST CLUB ON POWER 105.1/Via Reuters
Ẹwẹ, iha to daa to wu ni lori naa wa ninu ọrọ sisọ rẹ, laarin agbami bi awọn oloṣelu ṣe maa n ka ọrọ jade ninu iwe, Biden ni iranti igba ewe oun fihan pe oun kii fẹran lati maa ka ọrọ lati inu iwe dipo bẹẹ atinu ọkan loun ti maa n sọrọ.
Oloṣelu to ni ọgbọn alumọkọrọyi pupọ ni, o o lee fi ọrọ ẹnu so ọta pọ di ọrẹ ṣugbọn iru imọlara rẹ si nkan naa lo maa n di iṣoro.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹsun
Obinrin mẹjọ lo jade sita lọdun to kọja lati fi ẹsun kan Biden pe o fi ọwọ kan awọn, o di mọ wọn tabi fi ẹnu ko wọn lẹnu bkẹ si ni ileeṣk iroyin ilẹ Amẹrika ṣafihan bi o ṣe maa n ki awọn obinrin timọ timọ nita gbangba eyi to maa n fi han ni ọpọ igba bo ṣe n fi imu fi irun wọn.
Ninu idahun rẹ, Ọgbẹni Biden ṣeleri lati maa fi eyi sọkan ninu iṣesi rẹ sawọn eniyan.
Ẹwẹ, ninu oṣu kẹta, Tara Reade fi ksun kan an pe o fi agiditi oun mọ ara ogiri to si fipa ba a lopọ ni ọgbọn ọdun sẹyin nigba to n ṣiṣẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ oluranlọwọ ni ọfiisi rẹ.
Biden ti ni irs ni ẹsun naa ti ikọ olupolongo ibo rẹ si ti fi ọrọ sita pe: "eyi ko ṣẹlẹ rara ati rara".
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to jade laipẹ, Reade sọ pe "awọn to bimọ fun un ti n sọ ọpọlọpọ ọrọ buruku lori ayelujara.
Bo tilẹ jẹ pe oun funra rẹ ko tii fesi, ṣugbọn o fẹ da bii pe aiṣootọ wa ninu ipolongo rẹ ti wọn n sọ pe ko tii si ewu kankan tabi boya o wa.
Ẹwẹ, ikọ olupolongo rẹ ṣi tun bu ẹnu atẹ lu eyi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yiyago fun aṣiṣe
Eleyi fẹ fa iṣoro dani ṣugbọn atẹyin wa lo ti ṣẹlẹ, awọn alatilẹyin Biden n gbero pe iṣọwọ ṣe si rẹ bayii yoo ran an lọwọ lati ma jabọ sinu panpẹ kan naa to ti awọn aarẹ labẹ ijọba awaarawa ko si lọpọ igba.
Biden ti ni ọpọlọpọ iriri ni Washington. O lo ọdun mẹjọ nile aṣoju-ṣofin, mẹjọ nile aṣofin agba, mẹjọ gẹgẹ bii igbakeji aarẹ.
Lọpọ igba, awọn ara Amẹrika ti ni ẹni to ba ni oun kii ṣe ara inu ile nla funfun White House eyi si jẹ ohun to nira fun Biden lati sọ ni ti ara rẹ lẹyin to ti fẹẹ lo aadọtun nipo giga ninu oṣelu wọn si le lo iriri ọlọdun gbọọrọ yi lodi si i.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nipa Iriri gigun ti Biden ni
Biden ti kopa ninu ọpọlọpọ nkan ro nii ṣe nipa awọn eto pataki ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin ti awan ipinu yii si le maa fibẹẹ dun wo ninu oṣelu aye ode oni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajalu inu idile
O ṣe ni laanu fun Biden pe ọkan lara ohun to fi jk ko da bii pe o fẹ jina diẹ si ọpọ oloṣelu ni pe ohun kan to kan gbogbo eeyan ti sun gbọngbọn kan oun naa ri - iku.
Bo ṣe n mura lati ṣe iburawọle ipo sẹnetọ to wọle fun ni iyawo rẹ, Neilla ati ọmọbinrin rẹ, Naomi ku ninu ijamba ọkọ kan eyi to tun pa awọn ọmọkunrin rẹ meji, Beau ati Hunter lara.
Iṣoro inu ọpọlọ lo pada pa Beau lọdun 2015 lẹni ọdun mẹrindinlaadọta.
Torinaa bi o ṣe padanu eeyan pups layika rẹ fihan pe pẹlu gbogbo agbara to ni ninu oṣelu, oun naa ti ni ifọwọkan ajalu to kan awọn eeyan laye oun naa ri.
Ẹwẹ, iroyin nipa idile rẹ nipa ti ọmọ rẹ kan to ku, Hunter yatọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Agbara, iwa jẹgudujẹra ati irọ?
Hunter pada di agbẹjọro ko to di pe aye rẹ yiwọ.
Iyawo akọkọ rẹ ṣafihan aṣiri pe o n mu oogun oloro, ọti to si n lọ ile ti awọn aṣẹwo ti ma n jo nihoho ati pe wọn le e danu kuro nileeṣẹ awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika tori pe o n mu oogun oloro sinu iwe ikọsilẹ wọn
Lọdun to kọja o fẹ iyawo ẹlẹẹkeji lẹyin ọsẹ kan ti o pade rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iriri ilẹ Okere
Wọn lọ ẹsun kan mọ Biden lẹsẹ to tan kaakiri agbaye gẹgẹ bo ṣe jẹ pe lara iriri to ni ni nipa ọrọ ilẹ okere. Tẹlẹ, o ti jẹ alaga ile igbimọ aṣofin agba nipa ibaṣepọ ilẹ okere to si ti fi eyi yangan gan pe oun ti pade awan adari pataki lagbaye ni gbogbo ọdun marundinlaadọta sẹyin.
Nigba ti eleyi n fun awọn oludibo ni igboya pe o ni iriri lati di aarẹ sibẹ, o nira lati sọ bi itan rẹ lori eyi yoo ṣe baa mu pẹlu awọn oludibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninuu gbogbo ẹ tabi ko ma si nkankan
Ero awọn oludibo ti n gbe Biden ṣaaju Trump pẹlu nkan bii koko marun si mẹwa ninu idije aarẹ yii ṣugbọn idibo ti yoo waye ninu oṣu kọkanla ṣi jina to si jẹ wipe ọpọ ogun lo ṣi wa niwaju.
Awọn oludije mejeji ti baba forigbari lori ọrọ ṣiṣe atilẹyin fun awan afẹhonuhan to n bu ẹnu atk lu awọn ọlọpa nitori awọn alawọdudu ati bi ijọba ṣe n koju ajakalẹ arun Coronavirus.
Koda ọrọ ibomu lasan gan ti di ọrọ oṣelu, pẹlu bi wan ṣe maa n ri Biden ni gbogbo igba to n lo ibomu nigba ti Trump ni tirẹ mu ọna ida keji gba lori eyi.
Ṣugbọn yatọ fun eyi, aimọye ọrọ mii to wa nilẹ to pọ.
Bi Biden ba jawe olubori, yoo jẹ ewe oye ajẹpẹ amọ to ba fidi janlẹ, yoo pese anfani ọdun mẹrin mii fun ẹni to ro pe ko kun oju osuwọn rara lati jẹ aarẹ Amẹrika - "ẹni ti ko ṣee gbẹkẹle" gẹgẹ bo ṣe sọ.
Ni ọdun diẹ sẹyin nigba ti o n ṣe odiwọn boya yoo kara bọ idije aark lọdun 2016, Biden sọ pe "mo lee ku gẹgẹ bi eeyan ti inu rẹ dun bi mi o ba jẹ aarẹ".
Ọrọ ko ri bẹẹ mọ bayii.












