US presidential election 2020: Bí ààrẹ Trump kò ṣe gbé ipò sílẹ̀ yóò ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn

Idibo sipo aare ni Amerika

Oríṣun àwòrán, Google

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Amerika, Joe Biden ti ni o ṣeeṣe ki ẹmi ọpọ eniyan bọ ti aarẹ Donald Trump ko ba kuro ni ipo fun oun gẹgẹ bi aarẹ.

Biden ni Donald Trump gbọdọ fun oun ni aye lori bi yoo ṣe gbe ipo silẹ ni ọdun to n bọ lai si idẹna kankan.

O ni oun nilo ki Aarẹ Trump fi ipo silẹ ki awọn le gbogun ti arun Coronavirus to n gbẹmi awọn eniyan lọgọọrọ.

''O ṣeni laanu pe titi di asiko yii aarẹ Trump ṣi kọ lati gba wi pe oun kọ lo wọle gẹgẹ bi aarẹ lorilẹede naa''

Aibikita aarẹ Trump yii yoo jasi iku ọpọlọpọ awọn eniyan to n koju arun Coronavirus lọwọ''

Ti a ko ba gbagbe, aarẹ Donald Trump ti lọ si ileẹjọ lati tako awọn esi idibo to jade ni awọn ipinlẹ jankan-jankan lorilẹede naa.

Kini ileẹjọ n sọ nipa ẹjọ ti aarẹ Trump n pe lori esi idibo to gbe Joe Biden wole?

Ajọ to n risi ọrọ idibo nipinlẹ Wisconsin ti ni awọn ikọ ipolongo aarẹ Trump yoo san iye owo to to miliọnu mẹjọ dọla ilẹ okeere lati tun ibo ka nipinlẹ naa.

Joe Biden lo bori ni Wisconsin pẹlu ibo to lẹ ni 20,000 ju ti aarẹ Trump lọ.

Ipinlẹ Georgia yoo tun idibo ka lati agbegbe kan si omiran

Amọ, ikọ eleto idibo ni Georgia ti ni awọn ti ri ibo 2,600 ti wọn ko ka mọ esi idibo naa, ti won si ṣetan lati tun ibo ka.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ eleto idibo naa ni awọn kan kuna lati ka ibo naa nitori aimọ iṣẹ ṣe wọn.

Bakan naa ni ipinlẹ Gorgia yoo ma ka idibo naa lati agbegbe kan si omiran nitori ida 0.3% to wa laarin aarẹ Donald Trump ati Joe Biden.

Donald Trump ní Joe Biden wọlé ìbò ààrẹ Amẹrika ṣùgbọ́n...

Aarẹ Donald Trump ti sọ pe alatako rẹ tii ṣe oludije ẹgbẹ oṣelu Democrat, Joe Biden wọle.

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Facebook/Donald J. Trump

Ṣugbọn to wa nibẹ ni wo pe Trump to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu Rupublican ni Biden wọle ibo aarẹ nitori wọn ṣe eeru ninu eto idibo naa.

Loju opo Twitter rẹ lo ti fi ọrọ yii lede lọjọ Aiku, ọjọ kẹẹdogun oṣu kọkanla ọdun 2020 yii.

''Ko si awọn oluṣọ ibo tabi awọn onwoye nibi eto idibo naa, ileeṣẹ ti ko lorukọ to dara, Dominion lo tun wa ṣe agbatẹru eto idibo ọhun to fi mọ ayederu ileeṣẹ iroyin,'' Trump lo sọ bẹẹ.

Aarẹ ni gbogbo kudiẹ kudiẹ to ṣẹlẹ lalẹ ọjọ eto idibo ṣẹlẹ ki ẹgbẹ Democrat le jale ibo ni.

O ni wọn jale ibo naa ko si ẹni to ko kawọn mọ bẹ, Trump ṣalaye pe awọn to dibo pẹlu ẹrọ ifọrọranṣẹ iyẹn Mail-in pa ni lẹrin.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Loju awọn ileeṣẹ iroyin ayederu ni Biden ti wọle ibo aarẹ Amẹrika.

''Emi ko gba pe o wọle. Ọna si jin lori ọrọ ibo yii. Eeru ni Biden fi wọlẹ,'' Trump lo sọko ọrọ yii.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Trump ni o da oun loju pe oun yoo pada wọle ibo aarẹ ilẹ Amẹrika.

Ìdí rèé tí Donald Trump ṣe fìdí rẹmi nínú ìbò ààrẹ Amẹrika

Donald Trump sọrọ pẹlu igboya ṣaaju ibo aarẹ orilẹede Amẹrika ọdun 2020 pe oun yoo wọle lẹẹkeji gẹgẹ bi aarẹ ilẹ Amẹrika.

Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ lẹyin ti oludije ẹgbẹ oṣelu Democrat, Joe Biden fẹyin rẹ gbolẹ ninu eto idibo naa.

Amọ ki lo ṣe okunfa ijakulẹ Trump ninu eto idibo tawọn ọmọ ilẹ Amẹrika ti tu yaaya ta yaaya jade dibo?

Trump ni ibo to le ni aadọrin miliọnu eyi to jẹ eleyi to pọ julọ sikeji ninu itan oṣelu orilẹede Amẹrika.

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣugbọn o fidi rẹmi, eyi to jẹ ko di aarẹ Amẹrika ẹlẹẹkẹrin to kuna lati wọle saa keji.

Awọn onwoye nipa ọrọ oṣelu sọ pe Trump wọle ibo aarẹ lọdun 2016 nitori o sọ ọrisiiriṣii ọrọ ti ko baku gbe.

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣugbọn awọn onwoye naa sọ pe Trump kun a ninu ibo aarẹ ọdun 2020 nitori awọn ọrọ alufansa to n sọ naa.

Ọpọ to dibo fun Trump lọdun mẹrin sẹyin lo yi ọkan wọn pada nitori ihuwasi rẹ.

Ọpọ ọmọ ilẹ Amẹrika lo koro oju si bi Trump ṣe n sọrọ ko bakungbe ni gbogbo igba.

Ọgọọrọ awọn to n gbe igberiko lorilẹede Amẹrika ni ko gba ti Trump mọ rara.

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican gan an to jẹ ẹgbẹ oṣelu Trump papaajulọ awọn to kawe gan an ko nifẹsi si bi o ṣe n sọrọ sawọn ẹya mii yatọ si awọn alawọ funfun l'Amẹrika.

Wọn o fẹran bi koṣe bawọn alawọ funfun wi nigba ti wọn ba ṣe aṣemọṣe.

Bakan naa ni inu wọn ko dun pẹlu bi Trump ṣe di ọrẹ awọn olori apaṣẹ waa bii Vladimir Putin.

Ohun kan to daju ni pe awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ko le gbagbe Trump laelae gẹgẹ bi ilẹ naa..

US Election 2020: Ṣé èsì ìdìbò Ààrẹ Amẹrika yóò jáde lálẹ́ ọjọ́ ìdìbò?

Ọpọ awọn oludibo nilẹ Amẹrika ni yoo maa retin esi ibo ti wọn di lọjọ ti idibo naa ba waye, ṣugbọn ibeere ti ọpọ eeyan maa n bereni pe igba wo gan ni esi na yo jade?

Idibo nipasẹ ileeṣẹ ifiweranṣẹ

Lọdun 2016, miliọnu mẹtalelọgbọn awọn ọmọ ilẹ Amẹrika lo di ibo wọn nipasẹ awọn ileeṣẹ ifiweranṣẹ.

Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nitori ajakalẹ arun Coronavirus lọdun yii, miliọnu mejilelọgọrin eeyan lo ti fi erongba wọn lede lati dibo nipase awọn ileeṣẹ ifiweranṣẹ.

Ṣugbọn ọpọ ileeṣẹ ifiweranṣe ni ko tii bẹrẹ iṣẹ ni kikun nitori ajakalẹ arun naa.

Delaware

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fun apẹẹrẹ, ni ipinlẹ Michigan, nnkan bii miliọnu mẹta eeyan lo ṣeṣe ko dibo nipasẹ ileeṣẹ ifiweranṣẹ, ṣugbọn wọn ko ni bẹrẹ si ni ka ibo naa titi di ọjọ ibo gangan, to n tumọ si pe yoo to ọjọ diẹ si akoko naa ki wọ to ka ibo ọhun tan.

Oregon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọwọ yii obitibiti iwe ti awọn eeyan fi ranṣẹ ni ko tii tẹ awọn ti wọn fi ranṣẹ si lọwọ nitori ajakalẹ arun Coronavirus.

Iwadii nipa eto idibo to to waye sẹyin fi han pe, iye awọn ọmọ ẹgbẹ Democrat to n dibo nipasẹ ileeṣẹ ifiweranṣẹ pọ ju ti Republican lọ.

Bẹẹ ni wọn ni o ṣeṣe ki pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Republican ti yoo dibo lojukoju pọ ju ti Democrat lọ.

Michigan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣoro keji ti idibo Amẹrika maa ń ní ni ipẹjọ

Nigba ti ko ba si alafo to lamilaaka laarin esi awọn oludije, o ṣeṣe ki ipẹjọ wa lori awọn ibo ti wọn ko ka, eyii to le fa ki esi ibo naa falẹ.

Idi kan pataki ti wọn kii fi ka awọn ibo kan ni bi iwe idibo naa ba pẹ de lati ọdọ awọn ileeṣẹ ifiweranṣẹ.

Ni ọdun yii ti wọn sọ pe o ṣeṣe ki awọn iwe idibo ti yoo wa lati ọwọ awọn ileeṣẹ ifiweranṣẹ pọ ju ti tẹlẹ lọ, wọn ti sọ pe o ṣeṣe ki iwe idibo ti wọn ko ni ka pọ ju ti atẹyinwa.

Pennsylvania

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Njẹ o ṣeṣe ki esi idibo jade lalẹ ọjọ idibo?

Bẹẹni. Awọn onimọ nipa eto idibo naa ti sọ pe o ṣeṣe ki esi ibo waye lalẹ ọjọ idibo, ki awọn eeyan si mọ ẹni to jaweolubori lọjọ kan naa.

Ki ẹnikẹni ninu awọn oludije memeji to lee pegede ninu idibo ọhun, o ni lati rekọja ibo 270 ti awọn "electoral college" yoo di.

Joe BidenNorth Carolina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Njẹ awọn ileeṣẹ tẹlifiṣọn Amẹrika lagbara lati kede esi ibo lalẹ ọjọ kan naa?

Ayẹwo awọn idibo to ti kọja fi han pe awọn ileeṣẹ tẹlifiṣọn Amẹrika ti kede esi ibo ri, bo tilẹ jẹ pe ajọ to n ri si eto idibo naa ṣi n ka ibo ọhun lọwọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ni yoo joko ti ẹrọ amohunmaworan lalẹ ọjọ idibo ti a n sọrọ rẹ yii, o ku sọwọ suura awọn ileeṣẹ amohunmaworan lati ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ.