End SARS protest: Nítorí "Access Bank" gbẹ́sèlé owó àwon olùwọ́de EndSARS ni a ṣe kó owó wa kúrò níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, @JoeJoeSegun
Awọn ọmọ Naijiria kan ti bẹrẹ si n ti apo ifowopamọ wọn nile ifowopamọ Access lẹyin ti banki naa gbẹsẹle owo awọn onibara wọn to lọwọ ninu iwọde EndSARS.
Igbesẹ naa bẹrẹ lopin ọsẹ lẹyin ti awọn kan bẹrẹ si n ke pe awọn ọdọ Naijiria lati lọ fopin si idunadura laarin wọn ati ile ifowopamọ naa.
Ṣaaju ni banki apapọ Naijiria, CBN, ti kọkọ gba aṣẹ lọwọ ile ẹjọ lati kan an nipa fun awọn ile ifowopamọ pe ki wọn gbẹsẹle apo gbogbo awọn eeyan to ṣagbatẹru iwọde ọhun.
- Kò tọ́ sí Ọlọ́pàá láti ti ọmọ mi mọ́lé tórí ore tó ṣe lásìkò ìwọ́de EndSARS - Iya Eremosele
- Èmi ni mò ń jóko sórí ìtẹ́ Ọlọrun alààyè nílé ayé - Oluwo
- Wo ìdí tí wọ́n fi ta ẹyẹlé kan ṣoṣo ní ₦724,000,000
- 'Banji Akintoye kìí ṣe adarí àwọn ọmọ Yorùbá mọ́, a ti ní ẹgbẹ́ tuntun'
- Ọpẹ́ o! Wo bí agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀, Christian Obodo tí wọ́n jígbé lẹ́ẹ̀kejì ṣe móríbọ́
- Ààrẹ ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí èèyàn méjì t'ọ́lọ́pàá pa níbi ìfẹ̀hónúhàn lòdì sí ìjọba
- Wo ọkùnrin tó dáná sun ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ torípé kó gbà látí jẹ́ aya rẹ̀
Lara awọn to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe ko si idi miran ti wọn fi n ti apo wọn ni banki ọhun bi ko ṣẹyin bo sẹ tẹ ẹtọ awọn onibara rẹ loju mọle nitori wọn ṣe iwọde.
Ọkan lara awọn eeyan naa, Allen Olusegun ni "mo maa gbe owo mi kuro nile ifowopamọ Access, mo si maa gbe lọ sile ifowopamọ olokowo kekeke."
Olusegun ni oun ko ni igbagbọ ninu banki naa mọ nitori o le gbẹsẹle owo oun lọjọ iwaju ti oun ba gbiyanju lati ja fẹtọ oun gẹgẹ bi ọmọ Naijiria.
- Ìpínlẹ̀ Eko ní èèyàn 136 nínú èèyàn 152 lápapọ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Ọlọ́pàá fìyà jẹ mí lọ́dún 2014, mò wà lẹ́yìn àwọn ọ̀dọ́ lórí ìwọde EndSARS- Fayemi
- Awọn ọlọ́pàá gbòde kan ní Ajah, ọwọ́ tẹ àwọn afurasi tó ń jalè
- Iléeṣẹ́ ológun ní ó bàwọn lọ́kàn jẹ́ bí Sanwo-Olu ṣe ni kìí se òun ló pe sójà si Lekki
O tẹsiwaju pe ọna ti awọn ọmọ Naijiria le fi sọ fun banki naa pe ohun to ṣe ko dara to ni ki wọn ko owo wọn kuro nibẹ.
O tun sọ pe oun ko ni bojuwẹyin mọ bi banki ọhun ba tilẹ yi ipinu rẹ pada lori awọn apo to tipa.

Oríṣun àwòrán, @slay_jimmy
Ẹlomiran to ti fopin si ibaṣepọ rẹ pẹlu banki Access ṣugbọn ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ fun BBC pe, oun ko owo oun kuro ni banki naa nitori o gbẹsẹle owo awọn oluwọde EndSARS.
Ọkunrin naa ni "mi o lo Access Bank mọ nitori Access bank ti ja ara rẹ kulẹ gẹgẹ ile ifowopamọ, o si tun ja ara rẹ kulẹ niwasju awọn ọmọ Naijiria lapapọ."
O tẹsiwaju pe "to ba jẹ niti emi ni o, Access bank ti di oku si mi, mi o si fẹ ni nnkankan ṣe pẹlu wọn mọ."
Ni ti Farida Adamu, o ni oun ko ni ba banki naa dowopọ mọ nitori bo ṣe fiya jẹ awọn olufẹhonuhan EndSARS lodi si ofin.

Oríṣun àwòrán, Twitter:thefaridaadamu/slay_jimmy
Farida sọ pe oun ko ni pada ba banki naa dowopọ lẹyin ti oun ti gbe agadagodo sẹnu apoti oun to wa nileeṣẹ ọhun.
O pari ọrọ rẹ pe "kii ṣe igba akọkọ ree ti banki naa yoo ṣe ohun to lodi si ofin, ti wọn ba si n tẹsiwaju lati maa tẹ ẹtọ awọn onibara wọn loju mọle, o tumọ si pe ko si abo fun owo mi to wa lọwọ wọn."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ẹwẹ, ninu atẹjade kan ti banki ọhun fi lede loju opo Twitter rẹ, o ni ootọ ni pe oun gbeṣẹle apo awọn awọn onibara oun mẹjọ, ṣugbọn ki ṣe ẹbi oun nitori oun gbọdọ tẹlẹ aṣe banki apapọ Naijiria.















