EndSARS: Fayemi ní ọlọ́pàá ti fìyà jẹ òun náà rí, gbọin-gbọin lòun wà lẹ́yìn àwọn ọ̀dọ́ lórí ìwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, facebook/Kayode Fayemi
Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayode Fayemi ti sọ pe oun ṣetan lati darapọ mawọn ọmọ Naijiria ti wọn to n beere fun atunṣe awọn ọlọpaa Naijiria nitori ọlọpaa ti fiya jẹ oun ri.
Fayemi sọrọ yii nibi ipade awọn tọrọ kan lori iwọde EndSARS to waye sẹyin niluu Ado Ekiti lọjọ Aiku ọjọ kẹẹdogun oṣu kọkanla ọdun 2020.
Gomina ipinlẹ Ekiti tun sọ fawọn eeyan to wa nibi ipade naa wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari ṣetan lati gba ọrọ awọn to n beere fun iyipada iwa awọn ọlọpaa Naijiria.
''Ọrọ iwa ifijẹni awọn ọlọpaa kan onile bẹẹ naa ni o kan alejo. Lọdun 2014 ti mo gbegba ibo gomina l'Ekiti lẹẹkeji ni mo ni iriri iwa ifiyajẹni awọn ọlọpaa,'' Fayemi lo sọ bẹẹ.
Fayemi to kuna ninu ibo ọhun to waye lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹfa ọdun 2014 ṣalaye pe lagbegbe Mugbagba niluu Ado Ekiti lawọn ọlọpaa ti yin tajataju fun oun ti ko si tun jẹ kawọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC wọ ipinlẹ Ekiti lati ṣe ipolongo ibo fun oun.
Amọ o ni awọn ọlọpaa mii naa wa ti wọn ṣe daadaa fun oun, nitorinaa, o ni kii ṣe gbogbo wọn ni ko dara.
Gomina Ekiti ni ko si ohun to buru ninu ifẹhonuhan EndSARS to waye nitori ohun ti yoo mu iyipada rere ba awujọ ni.
Ọmọwe Fayemi sọ pe awọn ọdọ ipinlẹ Ekiti ṣe iwọde naa nirọwọrọsẹ eleyi to si tọna labẹ ofin.
Fayemi ni ''awọn ọdọ Naijiria n binu nitori ajakalẹ arun coronavirus ko jẹ ki wọn ri ileewe lọ, bakan naa ni iyanṣẹlodi ẹgbẹ olukọ fasiti ASUU n mu inu bi wọn.''
''Ju gbogbo rẹ lọ, ebi n pa araalu ni Naijiria latari bi ọrọ aje orilẹede yii ti dẹnu kọlẹ,'' Fayemi lo sọ bẹẹ.
O ni ijọba ti ṣetan lati ṣe ohun gbogbo tawọn ọdọ n beere eyi to mu wọn ṣe iwọde EndSARS.












