Fayose @ 60: Tí mi ò bá fẹ́ ìyàwó mi, n ó tí di àgbégbìn- Ayodele Fayose

Oríṣun àwòrán, olumide
Gómìnà ìpińlẹ̀ Ekiti nígbà kan rí, Ayodele fayose, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Osokomọlẹ Peter the Rock" ní àsìkò yìí gan ló yẹ láti jòkó láti dúẹ́ lọ́wọ́ Ọlórun àti láti súnmọ́ síi.
Gẹ́gẹ́ bí òní ṣe jẹ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ekiti Ayodele Fayose sàlàyé ìrìnàjò rẹ̀ títí di àsìkò yìí àti ìpa ribirribi tí ìyàwò rẹ̀ kó nínú ìrìnàjò rẹ̀.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánílẹ̀wò ní fayose ti sàlàyé pé, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ìyáwó òun ní ìrùmi tó ń lùlù lábẹ́ odó tí emi fi n jó lọ́bẹ́ omi.
"Sùgbọ́n lásìkò àyẹyẹ ọgọ́ta ọdún yìí, ó ṣe pàtàkì láti súnma Ọlọ́run, kí ènìyàn sì máa ṣètò àti ló ìgbẹ̀yìn àyé."
" Bí Ọlọrun ṣe fún mi ni ẹmi gígùn, ó ṣe pàtàkì láti fi ayé wa fún , láti wwo àwọn ọ̀nà ti kò ta tí à ń rìn àti láti máa wá ọ̀nà láti wà ni snà àláfíà pẹ̀lú Ọlọ̀run.

Oríṣun àwòrán, olumide
Ó ní tíì kìí bá ṣe pé ìyàwó tí òun fẹ́ ni, óṣéeṣe kí òun ti dí ẹni àgbégbìn nítorí ọ̀tá yóò tí ké òun kúrò.
'"Ìyàwó mi ni alárínà láàrín èmi àti Ọlọ́run " Láàrín òru yóò ji, yóò di ẹsẹ̀ mi mú yóò si máa gba àdúrà"
" Mó fí ọjọ́ ìbí yìí ji ìyàwò mi àti Ọlọ́run "

Oríṣun àwòrán, olumide
Ayodele Fayose tún sàlàyé pé òun ní ìgbàgba láti di ààrẹ orílẹ̀-èdè Naijiria lọ́jọ́ kan.
Ó mẹ́nu ba awuyewuye to wà láàrín rl àti gómìnà ìpińlẹ̀ Oyo Seyi Makinde. Fayose ni òun kò ni yée sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nígbà tí ó bá yẹ
"Kò sí ǹkankan ti èmi àti Makinde ń fa, sùgbọ́n ó ṣe pàtàkì kí olúkùlùkù kọjú mọ́ agbègbè rẹ̀ nìkan gẹ́gẹ́ bi oofin ẹgbẹ́ Makinde ni olórí adari PDP ni ẹkùn, sùgbọ́n kìí ṣe gómìnà àwọn ìpínlẹ̀ tó [wa ní abẹ́ rẹ̀.
Ní ti ààrẹ àná lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà Olusegun Obasanjọ, Fayose ni kò sí ìjà láàrín òun ati Obasanjo, sùgbọ́n ni ọ̀ps ìgbà, ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì máa n ta ko ara wọ́n nítori bákan náà ka ni ìwòye àwọn.
"Kò sí ìdí tí mnó fi fẹ̀ tọ́ra àforijì lọ́wọ́ Obasanjo, nítori kò sí ǹkan kan tó wà láàrín àwọn gẹ́gẹ́ bi ọlọ́danni.












