Yoruba World Assembly: Ìlú Ibadan ni wọ́n tí ṣe àgbẹ́kalẹ̀ ẹgbẹ́ ọmọ Yorúbá tuntun

Oríṣun àwòrán, Google
Olufilọlẹ ẹgbẹ ọmọ Yoruba tuntun, Comrade Victor Taiwo ti ni awọn gbe ẹgbẹ Yoruba World Assembly silẹ lati wa ọna abayọ si aisi ifẹ ati ifimọsọkan laarin awọn ọmọ Yoruba.
Victor Taiwo to sọrọ nibi ifilọlẹ to waye ni ilu Ibadan naa ni ilẹ Yoruba nilo idagbasoke.
Ẹgbẹ naa ni ilọsiwaju ọmọ Yoruba ninu ọrọ aje, ihuwasi, eto ẹkọ ati ẹsin gbọdọ wa ni ifimọsọkan fun ilọsiwaju.
- Ẹ wo ọkùnrin tó dáná bẹntiróò sún ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ torí kó gbà látí jẹ́ aya rẹ̀
- Ọpẹ́ o! Wo bí agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀, Christian Obodo tí wọ́n jígbé lẹ́ẹ̀kejì ṣe móríbọ́
- Ààrẹ ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí èèyàn méjì t'ọ́lọ́pàá pa níbi ìfẹ̀hónúhàn lòdì sí ìjọba
- Wo ọkùnrin tó dáná sun ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ torípé kó gbà látí jẹ́ aya rẹ̀
Taiwo ni ẹgbẹ awọn Yoruba to ku ti kuna lati ṣe ohun to tọ, eleyii to jẹ ki ifaṣẹyin wa fun ilẹ Yoruba.
'' Ẹ wo bi eto aabo ṣe dẹnukọlẹ ni ilẹ Yoruba, ti ijinigbe n waye loore-koore lai ka awọn ẹmi ti awọn ajinigbe n pa ni ilẹ Yoruba''
''Lẹyin ti wo gbogbo iṣẹlẹ yii ni a ṣe apero awọn agbagba ilẹ Yoruba, ki a to da ẹgbẹ Yoruba World Assembly silẹ''
''Otitọ si ni pe imọ awọn ọmọ Yoruba ko ṣe ọkan ni gbogbo igba, nitori aigbọraẹniye to wọpọ laarin awọn agbaagba''
''A ko nifẹ si iru ẹgbẹ ti ina wọn n jo ajorẹyin mọ, nitori naa ni ẹgbẹ ti yoo mu ifimọsọkan ni okunkundun ṣe koko, o ṣe pataki.''
- Ìpínlẹ̀ Eko ní èèyàn 136 nínú èèyàn 152 lápapọ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Ọlọ́pàá fìyà jẹ mí lọ́dún 2014, mò wà lẹ́yìn àwọn ọ̀dọ́ lórí ìwọde EndSARS- Fayemi
- Awọn ọlọ́pàá gbòde kan ní Ajah, ọwọ́ tẹ àwọn afurasi tó ń jalè
- Iléeṣẹ́ ológun ní ó bàwọn lọ́kàn jẹ́ bí Sanwo-Olu ṣe ni kìí se òun ló pe sójà si Lekki
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kóo mọ̀ nípá ọmọ ọdún mẹ́wàá Emmanuella tó kọ́ ilé ńlá fún ìyá rẹ̀
Lasiko ti ẹgbẹ tuntun naa n sọrọ lori ipo ti Ọjọgbọn Banji Akintoye wa gẹgẹ bi '' Adari ni ilẹ Yoruba, wọn ni Akintoye ti yọ ara rẹ kuro ninu ẹgbẹ ọmọ Yoruba nitori naa ki i se adari wọn mọ.
Yoruba World Assembly fikun pe Akintoye ti ja ọpọlọpọ ẹgbẹ to gbimọpọ yan an gẹgẹ bi adari, nitori naa kii ṣe adari wọn mọ.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, Ọjọgbọn Banji Akintoye ko tii fesi si igbesẹ ti awọn to fi ẹgbẹ yii lọọlẹ gbe.













