Emmanuella: Ohun mẹ́wàá tó yẹ kóo mọ̀ nípá Emmanuella tó kọ́ ilé ńlá fún ìyá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, officialemanuella
Ọpọlọpọ awọn ilumọọka lo ti n gboriyin fun adẹrinpoṣonu, Emmanuella lẹyin to kọ ile nla fun iya rẹ.
Ọjọ Satide ni ọmọbinrin naa fi awọn aworan ile naa lede lori ẹrọ ikansiraẹni, Instagram.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kó mọ̀ nípá ọmọ ọdún mẹ́wàá Emmanuella tó kọ́ ilé ńlá fún ìyá rẹ̀
- Apeja orukọ rẹ ni Emmauella Samuel ti wọn bi ni Ọjọ Kejilelogun, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2010.
- Ọmọ ọdun mẹwaa ni Emmanuella Samuel.
- Ipinlẹ Imo, to wa ni ẹkun Ila Guusu orilẹede Naijiria lo ti wa.
- Ni ọdun 2016, Afro-Australia Music and Movie Awards for Australia fun Emmanuella ni ami ẹyẹ adẹrinpoṣonu tuntun ati ọmọbabinrin adẹrinpoṣonu.
- Ọdun 2016 naa lo gba ami ẹyẹ Top Subscribed Creator lori oju opo ikansiraẹni YouTube
- Ohun lo kọkọ gba ami ẹyẹ lati ọwọ Sub-Saharan African YouTube Awards.
- Emmanuella Samuel jẹ ọmọde adẹrinpoṣonu fun ikọ Mark Angel YouTube to ni awọn eniyan to le ni miliọnu mẹfa to n wo o.
- Ere to jẹ ki Emmanuella di ilumọọka ni "This Is Not My Real Face Oh" nibi to ti fi adari ileewe rẹ ṣe yẹyẹ pẹlu ọrẹ rẹ, lai mọ pe iya rẹ ni adari ileewe ọhun.
- Awọn ileeṣẹ nla nla ti bẹrẹ si ni lo Emmanuella lati polongo iṣẹ wọn.
- Ọdun 2020 ni o kọle akọkọ fun iya rẹ, to si ni ọdun to n bọ ni oun a ṣi ile alawoṣifila fun iya oun.
Mo fi ilé yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyá mí fún àtìlẹyìn àti àdúrà rẹ̀ - Emmanuella
Yoruba ni ọmọ ti yoo jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samusamu.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọmọde to jẹ gbajugaja adẹrin posonu lori ayelujara, ti ọpọ eeyan mọ si Emmanuella.
O ti to bii ọdun melo kan ti ọmọde naa ti maa n dẹrin pa ẹẹkẹ awọn eeyan, ti ọpọ si maa n wo fidio rẹ lori ayelujara nitori ọrọ iwuri ati adanilaraya to maa n sọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́fà tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe láti kékéré
- Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà lára ọkọ̀ tó ń lo bátìrì tó sẹ̀sẹ̀ dé Nàíjíríà
- Buhari, a rántí ìjọba rẹ̀ fún ìyà, ìṣẹ́ àti ebi tó peléke - Araàlú faraya
- Bàbá àádọ́rin ọdún fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọdún mẹ́ẹ̀dógún lóyún, lọ̀rọ̀ bá pèsì jẹ
- Wo iye obìnrin tó bá Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó kú àti obìnrin to ṣeéṣe kó jogún rẹ̀
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó ti ṣe àríyá aláṣọ funfun kó tó kú
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
Emmanuella, to bẹrẹ awada sise lori ayelujara lọmọ ọdun marun, ti wa kede loju opo Instagram rẹ pe, oun ti ra ile awodamiẹnu kan fun iya oun.
O wa kede pe oun n fi ile mọriri ọpọ atilẹyin, adura ati iwuri ti iya oun n se fun oun ni.

Oríṣun àwòrán, officialemanuella
"Iya mi, mo mọ pe ile kekere lẹ n fẹ, ile naa niyi, sugbọn ẹ darijin mi, maa pari ile nla fun yin lọdun to n bọ, ẹ ma paya, eyi ko ni mu koju wa ri mabo."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ọdun 2010, eyiun ọdun mẹwa sẹyin ni wọn bi Emmanuela, to si ti pe ọdun marun to ti bẹrẹ awada sise lawọn oju opo ayelujara.
Emmanuella, tii se ọmọ bibi ipinlẹ Imo, ni wọn bi silu Portharcourt, to si ti gba oniruuru ami ẹyẹ nilẹ yii ati loke okun,













