Electronic Car in Lagos: Sanwo-Olu ní ìbùdó fún gbígbé bátìrì ọkọ̀ kaná yóò wà yíká Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter/LAGOS STATE GOVERNMENT
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sisọ loju ọkọ kan ti wọn se labẹle, to n lo batiri ina ọba lai lo epo pẹtiro.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ọkọ ayọkẹlẹ naa nileesẹ Volkswagen nilu Eko, Sanwo-Olu ni ibudo naa yoo tubọ pese isẹ oojọ si labẹle fawọn araalu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́fà tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe láti kékéré
- Buhari, a rántí ìjọba rẹ̀ fún ìyà, ìṣẹ́ àti ebi tó peléke - Araàlú faraya
- Bàbá àádọ́rin ọdún fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọdún mẹ́ẹ̀dógún lóyún, lọ̀rọ̀ bá pèsì jẹ
- Wo iye obìnrin tó bá Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó kú àti obìnrin to ṣeéṣe kó jogún rẹ̀
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó ti ṣe àríyá aláṣọ funfun kó tó kú
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l‘Eko
O ni ijọba ipinlẹ Eko yoo ba ileesẹ naa dowopọ nidi ipese ọkọ naa nipa pipese awọn ibudo ti awọn ọlọkọ yoo ti maa gbe batiri ọkọ wọn le ori ina, jakejado ipinlẹ Eko.
"Iran ta n ri nipa ọjọ iwaju ni pe imọ ẹrọ yoo lu ilẹ pa, o si yẹ ki ijọba ipinlẹ pese ayika to jiire fun eyi, ki awọn ọdọ wa le ri isẹ oojọ se."

Oríṣun àwòrán, Twitter/LAGOS STATE GOVERNMENT
Sanwo-Olu ni o ti foju han bayi pe gbogbo agbaye ati Naijiria ti n gbara kuro lori epo rọbi, eyi si ni ọjọ ọla ta n ri.
Ọkọ igbalode naa, lo le sare daada laisi eefin, ti eeyan si le gbe batiri rẹ le ina lati gba agbara ninu ile abi nibi isẹ.








