Divorce: Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìléẹjọ́ tú ìgbéyàwo'ọdún 11 ká nítórí ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
Ileejọ magisreti ni ilu Ibadan ti tu igbeyawo ọdun mọkanla ka laarin Nurudeen Mabinuori ati Zainab lori ẹsun pe iyawo n fi ibalopọ dun ọkọ rẹ.
Aarẹ ileẹjọ, Henry Agbaje sọ wi pe ileẹjọ ti sa gbogbo ipa wọn lati jẹ ki igbeyawo naa duro, amọ igbeyawo naa ti daru patapata.
Agbajẹ wa tu igbeyawo naa ka ki alaafia le jọba laarin wọn.
Ileejọ si gba ki Zainab gbe ọmọ ẹyọkan ṣoṣo ti wọn jọ nipo si ọdọ rẹ.
Ileẹjọ naa si paṣẹ ki Mabinuori san ẹgbẹrun marun un Naira ni oṣooṣu lati ma a fi tọju ọmọ rẹ.
Mabinuori ni oun ko fẹ iyawo oun mọ nitori iwa ipa ati wi pe ọlọkan lile lo jẹ.
''Ọkọ mi ti ko arun ibalopọ nitori alagbere ni, bi o ṣe n gbe dudu lo n gbe pupa.''
''Mo kọ lati ni ibalopọ pẹlu rẹ mọ lẹyin ti mo ti ko arun naa lara rẹ, ti mi o si fẹ ko ṣẹlẹ mọ.''
''Mo si rọ ọ ko lọ fun iwosan, amọ o kọ, mi o si fẹ ko ko arun ran mi.''
Bakan naa, Zainab kọju si ọkọ rẹ lati sọ otitọ ninu ile ẹjọ lẹyin to ni awọn ana rẹ mọ idi ti oun fi n bere fun ki ileẹjọ tu igbeyawo awọn ka.














