Suicide: Ẹ wo ọkùnrin tó dáná sún ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ nítorí kó gbà látí jẹ́ aya rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii ti fihan pe arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ, Nicodemus Nomyange ti dana sun ara rẹ ati ọrẹbinrin rẹ, Shininenge Pam nitori o kọ lati jẹ aya afẹsile rẹ.
Iṣẹlẹ naa waye ni ile orẹbinrin rẹ naa to wa ni agbegbe Inikpi, ni Makurdi to jẹ olu ilu ipinlẹ Benue.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni arakunrin Nomyange naa lọ si ile afẹsọna rẹ pẹlu galọọnu epo bẹntiroo, to fi dana sun ile naa.
- BBC Africa Eye: Àwọn ajọ́mọgbé náà kò mọ̀ pé BBC ní wọ́n bá dòwò pọ̀
- Ìpínlẹ̀ Eko ní èèyàn 136 nínú èèyàn 152 lápapọ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Ọlọ́pàá fìyà jẹ mí lọ́dún 2014, mò wà lẹ́yìn àwọn ọ̀dọ́ lórí ìwọde EndSARS- Fayemi
- Awọn ọlọ́pàá gbòde kan ní Ajah, ọwọ́ tẹ àwọn afurasi tó ń jalè
Awọn ololufẹ mejeeji si ku si inu ile ọrẹbinrin naa.
Awọn ara adugbo ni o ti to igba diẹ ti awọn ololufẹ yii ti n fẹ ara wọn, amọ ija bẹrẹ nigba ti ọrẹbinrin naa kọ lati fẹ ẹ bi ọkọ nitori o ni o dagba ju oun lọ.
Nomyange yii ni awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ wipe o ti ni iyawo pẹlu ọmọ, amọ o bẹrẹ si ni fẹ orẹbinrin rẹ yii, to si gba ile to n gbe fun un pẹlu dukia.
Amọ, awọn ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni orẹbinrin Shininenge kọ lati fẹ ọkunrin naa gẹgẹ bi iyawo keji lẹyin ti awọn ọrẹ rẹ ni Nomyange ti dagba julọ, nitori ẹni ogoji ọdun o le ni.
Awọn ara adugbo ni iṣẹlẹ naa ya awọn lẹnu nitori orẹkunrin naa kii ṣe oni jagidijagan, amọ ṣaadede lo wa si ile ọrẹbinrin naa pẹlu galọọnu bẹntiroo, ti awọn si ro wipe wọn fẹ lo o fun ẹrọ alupupu wọn ni.
''Lẹyin ti ọrẹkunrin naa wọle ti obinrin ọhun ni wọn ti ilẹkun mọ ara wọn''
'' Ohun ti awọn ara adugbọ kọkọ ri ni eefin to n jade lati inu yara naa, ti gbogbo igbiyanju wọn lati pa ina ọhun jasi pabo.''
Ati wipe ki awọn panapana to pa ina naa, ẹmi ti bọ lara awọn ololufẹ mejeeji.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ naa, DSP Catherine Anene ni awọn ara adugbo naa ni awọn ri ọkunrin naa to gbe bẹntiroo wọle, ti awọn si rọ pe gẹnẹratọ ni wọn fẹ lo o fun.
Anane fikun pe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa, ati ohun to fa iṣẹlẹ naa gangan.
Bàbá àádọ́rin ọdún fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọdún mẹ́ẹ̀dógún lóyún, lọ̀rọ̀ bá pèsì jẹ
Ara meriri, mo ri ori olongbo lori atẹ ni ọna ti iwa ifipabanilopọ pẹlu awọn majesin tun gba yọ bayii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abi ki ni ka ti pe ti baba agba kan to n ba ọmọ ọmọ rẹ ni ajọsepọ, titi to fi di oyun.
Ileesẹ ọlọpaa ipnnlẹ Ogun lo fi ọrọ naa sita pe ọwọ ti tẹ baba agba naa, Hunsu Sunday, ẹni aadọrin ọdun, to fun ọmọ ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹẹdogun loyun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́fà tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe láti kékéré
- Wo iye obìnrin tó bá Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó kú àti obìnrin to ṣeéṣe kó jogún rẹ̀
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó ti ṣe àríyá aláṣọ funfun kó tó kú
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
- Ta ni olóògbé Jerry Rawlings, tí wọ́n fún ní àlàjẹ́ 'Junior Jesus'
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l‘Eko
Ọjọ Isẹgun ni ọwọ sinkun ọlọpaa tẹ baba akumọmojudi naa, nigba ti ẹgbọn ọmọ ọhun mu ẹjọ tọ ileesẹ ọlapaa lọ.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni ẹkun ileesẹ ọlọpaa to wa nilu Ado Odo ni wọn mu ẹsun naa lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọdebinrin naa lo ti n gbe lọdọ baba agba ọhun lati igba ti iya rẹ ti jade laye, to si ti n fi ẹjọ sun anti rẹ pe baba agba maa n ba oun lopọ ni gbogbo igba, ti ooyi si n kọ oun.
Nigba ti wọn fi ọrọ wa baba agba naa lẹnu wo, se lo jẹwọ pe lootọ ni oun maa n jẹ dodo lara ọmọ ọmọ oun amọ oun ko tiẹ mọ pe o ti fẹraku.
Ileesẹ ọlọpaa ni iwadi ti n tẹsiwaju lori isẹlẹ naa.
Afurasí afipábánilópọ̀ kàgbákò, obìnrin tó jà lólè fi eyín gé nǹkan ọkùnrin rẹ̀ jábọ́ lásìkò 'Blow Job'

Obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, ti fi eyin ge okó ọkunrin kan, to fi ipa ba a lopọ jabọ, lẹyin ti ọkunrin naa sọ pe ko fi ẹnu fa okó rẹ.
Agbegbe Obuasi, ni ẹkun Ashanti lorilẹede Ghana ni iṣẹlẹ naa ti waye ni ọjọ Satide.
Iroyin sọ pe, ẹni ti wọn fi ẹsun ifipabanilopọ kan, deede wọ yaara Juanita laarin oru.
- Ẹ wo ìṣẹ̀lẹ̀ nípa ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kan D'banj ní sísẹ̀-n-tẹ̀lé
- Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn alágbara ló ń fi agbára hàn lórí arábìnrin tó fẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kan kọmíṣọ́nà Kogi -Agbẹjọ́rò
- Bíbéèrè fún ìbálòpọ̀ gbogbo ìgbà sọ ìyàwó ilé dèrò ilé ìwòsàn
- Wo àfipábánilòpọ̀ ẹni ọdún 51 tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tú làṣirí ní gbangba
- Ìdí rèé tí mo fi ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fipá bámi lopọ̀ lọ́mọ ọdún méje lọ́gọ́ta ọdún sẹ́yìn-Eli
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni agbagbe naa, ASP Godwin Ahianyo si fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC.
Obinrin naa kọ silẹ ninu iwe akọsilẹ ileeṣẹ ọlọpaa pe "ọkunrin ọhun, lẹyin to fipa ba mi lopọ tan, tun ni ki n mu okó rẹ, ti mo si ge oko naa jabọ".
Ọkunrin ọhun, Emmanuel Ankron, ẹni ọdun mẹtalelogun, wọ yara akẹkọọ obinrin naa pẹlu àdá lọwọ, ati ibọn agbelẹrọ pelebe, to si fi tipa ba lopọ.
Lẹyin to ji owo rẹ tan, o tun gbe tẹlifisan, ati foonu, lo ba tun beere pe ko fi ẹnu fa nkan ọmọkunrin oun, irufẹ ere ibalopọ ti wọn n pe ni 'blow job'.
Bi ọmọbinrin naa ṣe ge okó rẹ jẹ niyẹn o, ti ẹjẹ si bẹrẹ si ni i tu jade, eyi lo si mu ki afurasi naa sa jade ninu yara naa.

Ninu ibẹru ṣi ni Juanita wa, to fi lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti. Lẹyin naa lo lọ sileewosan Anglogold Ashanti, fun itọju.
Nibi to ti n gba itọju lo ba ri pe ileewosan ọhun ni afurasi to fi ipa balopọ naa wa fun itọju, lo ba bẹrẹ si ni pariwo pe ki wọn o ba oun mu u.
Awọn ọlọpaa pada ri ageku okó naa to fi eyin ge jabọ, wọn si ti mu lọ sileewosan fun itọju.
Iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii.
Awọn alaṣẹ sọ pe obinrin naa ge e afurasi naa jẹ, lẹyin to ti kọkọ fi ipa ni ibalopọ pẹlu rẹ, to tun wa a sọ pe ti ko ba fun oun ni 'blow job', oun ko ni i kuro ni ile rẹ.


















