Kenya Baby Stealer: Àwọn ajọ́mọgbé náà kò mọ̀ pé BBC ní wọ́n bá dòwò pọ̀

Àkọlé fídíò, Àṣírí tú! Ikọ̀ ìwádìí BBC ṣí àwọn tó ń jí ìkókó gbé sí gbangba

Ṣe bi wọn ni ọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni nu lọ.

Ko ri bẹẹ ni orilẹede ti wọn ni lọdọọdun ni ọmọ maa n poora loju titi ṣere ṣere.

Ikoko

Awọn ti ikọ iwadii ikọkọ ti BBC daa bi ọgbọn ba sọrọ ṣalaye ibanujẹ to maa n gba ọkan awọn eeyan nigba ti awọn ọmọ a wa lẹgbẹ wọn, ki wọn si to ṣẹju pẹrẹ, ọmọ ti poora.

Kayefi nla gbaa leyi jẹ. Bi BBC ṣe tu awọn to n ṣe iṣẹ laabi yii fo, awọn gan o mọ. Wọn kii mọ pe kamẹra n ka aworan awọn silẹ. Kii ṣe ohun ti wọn lee fura rẹ.

Afurasi Ajọmọgbe

BBC: Ṣe ẹnikẹni o ni wa beere awọn ọmọ yii?

Arabinrin A: Rara

BBC: Ọmọ ikoko melo lo ti ji gbe bayii?

Arabinrin A: Meji

Odidi ọdun kan o le ni ikọ oniroyin ọtẹlẹmuyẹ BBC fi ṣe iwadii owo jiji ọmọ ọlọmọ gbe ni orilẹede Kenya.