Nelly Ating Photographer: Omíjé kún rọ́rọ́ lójú mi níbùdó àwọn tí Boko Haram dá lóró

Àkọlé fídíò, 'Mo ní àṣírí ìyá tó fẹ́ ọmọ rẹ̀ láya fún Boko Haram torí ẹbí rẹ̀'

Ẹ gbọ́ kí ló leè mú ìyá fi ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbèkùn?

Nellly Ating ni oun ko si lee da a lẹbi nitoripe ko sẹni to wọ bata ipo to wa lakoko yẹn sẹsẹ.

Ayàwòránkọ̀tàn ni Nelly to maa n ko iroyin jọ nipa aawọ ati awọn iroyin ti wọn bo mọlẹ ni Naijiria.

Ọtọ ni iroyin tawọn to sa kuro nile igbe wọn ati ilu tori ikọlu Boko Haram loju koroju ti wọn si ni iriri lati sọ.

Bii awọn mii to tun rin lati Goza lọ si Adamawa. "Awọn mii yoo sọ pe ori oke ni mo sun si..."

"Omije kun loju ọpọlọpọ wa nigba taa wọ ibudo awọn ti Boko Haram da loro".

Nelly kọ itan nipa iya kan to fi ọmọ rẹ obinrin silẹ ko fẹ Boko Hara lati lee doola ẹmi idile wọn.

"Títí dọ̀la, arábìnrin yìí ṣì ń kábamọ̀ ohun tó ṣe".

Nipasẹ aworan, awọn itan ti arabinrin yii n sọ bu ni lọkan so nipa gbogbo iṣẹlẹ ikọlu Boko Haram ni Naijiria.

Niṣe lo bẹrẹ si ni ko owo jọ lori ayelujara lati le san owo ileewe awọn ọmọ kan lara awọn awn ti idamu Boko Haram ba yii.