Boko Haram Sponsors: Ẹbí àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́fa tó rí ẹ̀wọ̀n he ní UAE nítorí Boko Haram sọ pé àkóba ni ọ̀rọ̀ nàá

Mọlẹbi awọn kan lara ọmọ Naijiria mẹfa ti wọn dajọ ẹwọn fun l'orilẹ-ede United Arab Emirates, fun nitori ibaṣepọ wọn pẹlu ik Boko Haram ti sọ pe akoba ni ọrọ naa.
Ẹnikan to ba iwe iroyin Daily Trust sọrọ ni "iṣẹ paṣi-paarọ owo ati eto bibani fi owo ranṣẹ, ni awọn eeyan naa n ṣe ni Dubai, to si ṣe e ṣe ko jẹ aimọkan lo mu wọn ba onibaara wọn fi owo ranṣẹ si Naijiria laimọ pe ikọ Boko Haram ni wọn n fi ranṣẹ si."
Ati pe wọn ti n ṣe okoowo yii ki wọn o to bọ si pakute awọn to n ran wọn niṣẹ laimọ.
Ọjọ Aiku ni iroyin jade pe wọn ti dajọ ẹwọn fun ọmọ orilẹ-ede Naijiria mẹfa ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ ti ilu Abu Dhabi, nilẹ United Arab Emirate (UAE), fun ẹsin gbigbọ bukaata Boko Haram.
Iroyin naa ni idajọ ẹwọn laelae ni wọn fun meji lara wọn, Surajo Abubakar Muhammad ati Saleh Yusuf Adamu.
Awọn mẹrin to ku, Ibrahim Ali alhassan, AbdurRahman Ado Musa, Bashir Ali Yusuf, ati Muhammad Ibrahim Isa, gba idajọ ẹwọn ọdun mẹwaa.
Atẹjade kan ti olubadamọran fun aarẹ Buhari lori ọrọ ilẹ okeere, Abike Dabiri Erewa fisita loju opo Twitter rẹ lọjọ Aje, lo sisọ loju eleyi.
Dabiri ni o seese fun awọn ti wọn dajọ fun naa lati lọ sile ẹjọ to ga julọ lati tako idajọ naa to ba wu wọn.

Oríṣun àwòrán, @NigerianArmy
Idajọ naa fihan pe, awọn afurasi naa lọwọ ninu fifi owo toto $782,000 ranṣẹ si ikọ Boko Haram laarin ọdun 2015 si 2016, bo tilẹ jẹ pe awọn to sunmọ wọn sọ pe nnkan to ba ofin mu ni wọn fi owo naa ranṣẹ fun.
Ọjọ ti pẹ ti oriṣiriṣi ibeere ti n waye lori orisun ti ikọ Boko Haram ti n ri owo, igba akọkọ si niyii ti orukọ ẹnikẹni jade si gbangba nipa rẹ.
Bawo ni ọwọ ṣe tẹ wọn?

Oríṣun àwòrán, Daily Trust
Iroyin sọ pe, laarin ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2017, ni awọn ọlọpaa mu wọn , ti wọn si tu ile wọn wo.
Iroyin sọ pe, awọn meji akọkọ finnu-findọ darapọ mọ Boko Haram ni Naijiria, eyi to tako ofin igbesunmọmi ni UAE, to si le yọri si idajọ iku tabi ẹwọn gbere.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wọn fi ẹsun kan awọn mẹrin yoku pe wọn n pese iranlọwọ fun ikọ naa.
Amọ ṣa, mọlẹbi wọn sọ pe akoba ni ọrọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ojúlówó Shina Rambo yọjú sígboro lọ́jọ́ Àìkú, ó fi ìka hánu lórí ìpànìyàn tó ti ṣe
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Wàhálà míì dé! Nupeng àti Pengassan gùnlé ìyanṣẹ́lódì
- Làásìgbò ọ̀tun súyọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Báwo ni Joe Biden yóò ṣe mú ìyípadà bá òfin tí Trump fi de orílẹ̀èdè àgbáyé?
- Afurasí afipábánilópọ̀ kàgbákò, obìnrin tó jà lólè fi eyín gé nǹkan ọkùnrin rẹ̀ jábọ́ lásìkò ‘Blow Job’
- Àwọn ọba alayé, Mínísítà àti gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ṣèpàdé pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀, àbọ̀ rèé
- Iná ṣẹ́yọ nílé ìtajà aya Ajimobi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó jáde opó
Wọn ni iṣẹ paṣi-paarọ owo ati eto bibani fi owo ranṣẹ, ni awọn eeyan naa n ṣe ni Dubai, to si ṣe e ṣe ko jẹ aimọkan lo mu wọn ba onibaara wọn fi owo ranṣẹ si Naijiria laimọ pe ikọ Boko Haram ni wọn n fi ranṣẹ si.
Bakan naa ni iroyin sọ pe, awọn agbofinro ṣi n wa eeyan meji, to jẹ ọmọ Naijiria, ti wọn fi ẹsun kan pe awọn lo ma n gbe iṣẹ fifi owo ranṣẹ fun awọn eeyan naa.













