PENGASSAN Strike: Bí ìjọba bá dá wà lohùn lórí IPPIS láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún, a o so ìyanṣẹ́lódì rọ̀

Ọwọn gogo epo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iyanṣẹlodi ti awọn oṣiṣẹ agba to n ṣiṣẹ lẹka epo rọbi ni Naijiria, PENGASSAN, seleri lati gunle lọjọ Aje. ti gberasọ.

Fun idi eyi, o ṣeeṣe ki araalu tun fara gba ọwọn gogo epo bẹntiroo, bi ijọba ko ba tete da awọn oṣiṣẹ yi lohun.

Akọwe ẹgbẹ naa. Lumumuba Okugbawa lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Saaju ni o ti fi atẹjade kan sita nibi to ti paṣẹ pe ki gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ni gbogbo ẹka wọn ti gunle iyanṣẹlodi bẹrẹ lati ago mejila ọjọ Aiku mọjumọ ọjọ Aje.

Awọn ero to n ja lati ra epo

Oríṣun àwòrán, @chukwudi52

Gẹgẹ bi alaye ti o ṣe fun akọroyin wa, o ni lati ọdun 2014 lawọn ti n dunadura pẹlu ijọba lori ọrọ yii, ṣugbọn pabo ni gbogbo rẹ ja si.

Koda o ṣalaye pe, gbedeke ọlọjọ meje tawọn fun ijọba yii kii ṣe akọkọ iru rẹ.

''A ti kọkọ fun ijọba ni gbedeke ọlọjọ meje akọkọ, lẹyin naa la fun wọn lọjọ meje si, ṣugbọn ko so eso rere kankan''

O ni ijọba lẹtọ lati ṣagbekalẹ eto to ba wu lati maa fi san owo osu oṣiṣẹ rẹ ṣugbọn eto yii ni gbọdọ faye gba awọn owo ajẹmọnu kan tawọn ọmọ ẹgbẹ awọn gba.

Aworan atẹjade PENGASSAN

Oríṣun àwòrán, Lumumba Okugbawa

''A ko lodi si lilo IPPIS ṣugbọn ijọba ko fẹ seto bi yoo ti ṣe jẹ ki a ri gbogbo awọn ajẹmọnu ati owo miń to tọ si wa gba.''

''Ẹka wa yatọ nitori awọn oṣiṣẹ wa a maa wa lori omi fun ọjọ to pẹ, ti wọn a si maa san awọn owo ajẹmọnu kan fun wọn. IPPIS ti ijọba gbe kalẹ ko faye gba sisan owo yii.''

Lumumba ni awọn ṣi ṣe ipade pẹlu ijọba lọjọ meji ṣẹyin, ti wọn si ni igbesẹ yoo waye lati ṣatunṣe gbogbo ẹdun ọkan wọn.

O ni ẹka to n ṣeto owo oṣu oṣiṣẹ (Salaries and Wages Commission) lawọn reti ki wọn ṣe atunṣẹ to yẹ, ni ibamu pẹlu aṣẹ lati ọdọ akọwe agba fun ijọba apapọ (SGF).

ọmọ ẹgbẹ PENGASSAN

Oríṣun àwòrán, pengassanhq

''Bi wọn ba kesi wa laarin wakati mẹrinlelogun pe awọn ti ṣetan lati gbe wa pada si ori eto ti wọn ti n sanwo wa tẹlẹ, a ko ni kọ lati pada si ẹnu iṣẹ.

Bi o si jẹ ti IPPIS naa ni, ko ṣa ti faye gba owo ajẹmọnu wa. Ko buru.''

Iyanṣẹlodi lẹka epo rọbi ni Naijiria ti wọn gunle yii wa ni ajọṣepọ pẹlu awọn oṣiṣẹ awakọ epo rọbi, NUPENG, nitori naa, o ṣeeṣe ki awọn araalu ma ri epo bẹntiroo ra.

Àkọlé fídíò, Ifa Worshippers: Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń fẹ́ kíjọba pín èrè òṣèlú alágbádá yíká gbogbo ẹ̀sìn

''Bi awọn ile epo ba ti ta epo to wa ni akoto wọn tan, wọn ko ni ri omiran nitori awọn ọlọkọ epo bẹntiroo ati ọja miran ko ni gbe epo labẹ aṣẹ wa.''

O wa rọ ijọba lati tete wa wọrọkọ fi ṣada, ki ara ma ba ni ara ilu.

Ọrọ owo oṣu sisan nipasẹ IPPIS yii jẹ eleyi tawọn olukọ fasiti Naijiria naa fi tori rẹ fariga, ti wọn si ti kọ lati ṣiṣẹ fun nnkan bi oṣu mẹfa bayi.