#EndSars Lagos Judicial Panel: Iléeṣẹ́ ológun ní òtítọ́ làwọn sọ́jà gbé ìbọn tó lọ́ta gidi nínú lọ sí Lekki Toll Gate

Awọn sọja

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian Army

Ileeṣẹ ologun oriilẹ ti sọ pe awọn sọja gba ibọn to ni ọta to le ṣekupa eeyan lọ si Lekki Toll Gate nibi tawọn oluwọde EndSARS ti n ṣe ifẹhonuhan ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020.

Ọgagun Brig. Gen. Ahmed Taiwo ṣalaye pe awọn sọja gbe ibọn pẹlu ọta gidi ninu rẹ dani lati baado bo ara wọn.

Amọ, o sọ pe kii ṣe ọta gidi lo wa ninu ibọn tawọn sọja yin soke ni Lekki lati tu awọn oluwọde EndSARS ka.

Ọgagun Taiwo fidi ọrọ yii mulẹ niwaju igbimọ to n ṣe iwadii ipaniyan to waye ni Lekki Toll Gate nipinlẹ Eko.

Ọrọ yii jẹ jade nigba tawọn agbẹjọro Adeyinka Olumide-Fusika (SAN) ati Adesina Ogunlana fi ọrọ wa ọgagun naa lẹnu wo.

Brig. Gen. Taiwo sọ pe nitori awọn janduku to wa laarin awọn olufẹhonuhan lo jẹ kawọn ologun gbe ibọn to ni ọta gidi ninu lọ sibẹ.

Ẹwẹ, igbimọ naa ti pari ayẹwo ohun ti kamẹra CCTV ka silẹ logunjọ oṣu kẹwaa ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, The New Pandemic: Kíni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ń sọ nípa rẹ̀?

Fọnran CCTV naa fihan pe ohun gbogbo si n lọ nirọwọ rọsẹ ni bii aago meje ku iṣẹju mẹtadinlogun lọjọ naa.

Ṣugbọn ni iṣẹju meji lẹyin naa lọrọ bẹyin yọ lẹyin ti ọkọ awọn sọja de ibẹ.

Ni deedee aago meje ku iṣẹju meje ni ina lọ ni Lekki Toll Gate, amọ Ọgagun Taiwo ni deedee aago meje ku iṣẹju mẹtadinlogun lawọn sọja bẹrẹ si ni yinbọn lẹyin tawọn janduku bẹrẹ si ni lẹ oko mọ wọn.

Iléeṣẹ́ ológun ní ó bàwọn lọ́kàn jẹ́ bí Sanwo-Olu ṣe ni kìí se òun ló pe sójà si Lekki

Àdari ẹka ọmọ ologún 81 Brigade ní Victoria Island Brig. Gen Ahmed Taiwo sọ lọ́jọ́ sátidé, pé àwọn olùfẹ̀hónú hàn #EndSars fẹ sọ ìpínlẹ̀ Eko di aláìlólórí.

Brig Taiwo sọrọ yìí níbi ìjòkò tó ń gbẹjọ ìwà ìpá ọlọ́paàá àti ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáye ni Lekki.

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Babajide Sabwo-Olu

Taiwo sàlàyè pé lẹ́yìn ti gbogbo ǹkan tó wáyé sááju ọjọ náà, àga ọlọ́pàá ti wọ́n jó, pipa àwọn ọlọ́pàá,. bi wọ́n ṣe dí ojú pópó ti àwọn jàndùkú sì bẹ̀rẹ̀ sí ni gba owó lọ́wọ́ ará ilú tó ǹkan ti gómìnà fi lé pé sójà láti wá ran oun lọ́wọ́

O ní sááju ni gọmìnà Babajide sanwo-Olu ti pé Commader 9 Brigade., sùgbọ́n nitori kò tẹ̀lé ìlànà tó yẹ ni wọ́n ó fi lọ síbẹ̀ tí o si ni kí ó kọ́ka pé olóri ọmo ologun pátápáta, Tukur Buratai

Lagos Judicial Panel: Sọja tú àsírí gbogbo ǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Lekki Toll Gate

O ní kóda gomina ko ni aago ìpè GOC bákan náà ni GOC ko ni ti Gómìnà ni àsìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ.

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ lẹ́yìn ìpàde tí ní GOC pe Gomina nítorí àwọn ìpè àjòjì tí ó ri lórí aago rẹ̀.

Lẹ́yìn èyí ló pàsẹ kí àwọn 81 Brigade lọ sí ibi #EndSars Lekki Toll Gate.

Ọga àwọn ologun náà bu ẹnu àtẹ lu gbogbo àwọn ẹri tó wà nígboro pé ìrọ́ lásán ni wọ́n.

Lagos Judicial Panel: Sọja tú asírí gbogbǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Lekki

O ní gbogbo ìbọ̀n ti wọ́n yìn níbẹ̀ kìí ṣe ìbọn gangan bíkose ọta ìbọn alátìkè

Ẹ̀wẹ̀, gbogbo ènìyàn ló tí n bẹ̀nu àtẹ́ lu gómìnà ìpińlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Shooting, nílẹ̀ yìí àti lókè Okun.

Àkọlé fídíò, Àṣírí tú! Ikọ̀ ìwádìí BBC ṣí àwọn tó ń jí ìkókó gbé sí gbangba

Yàtọ̀ sí ìpè gómìnà sí àwọn ọmọ ológun láti ràn òun lọ́wọ́. Ìwádìí níbi ìjòkó ìfẹ̀hónúhàn yii ní Brig. Gen Taiwo tí fi ẹnu rẹ̀ sọ pé olórí ilé ìtajà SPAR pe òun láti wá ran òun lọ́wọ́ ni agbègbè náà lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Shooting.

Olumide Fusika ló bèrè lọ́wa Brig. Gen ló ń bèrè ìbérè yiìí pé yàtọ̀ sí gómìnà ìpińlẹ̀ Eko ta tún lo bẹ Brig. Taiwo níṣk ni Lekki Toll gate

Àkọlé fídíò, 'Mo ní àṣírí ìyá tó fẹ́ ọmọ rẹ̀ láya fún Boko Haram torí ẹbí rẹ̀'