Pneumonia in Nigeria: Ó kéré tán ọmọdé 142,000 sí 160,000 ní àìsàn otútú àyà ń pa lọ́dọọdún ní Nàìjíríà

Ó kéré tán ọmọdé 142,000 sí 160,000 ní àìsàn otútú àyà ń pa lọ́dọọdún ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ẹka ijọba to n risi ọrọ eto ilera lorilẹede Naijiria ti ni o kere tan ọmọde ti ọjọ ori wọn ko i ti pe ọdun marun un ni aisan otutu aya n mulọ ni ọgọọro.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ eto ilera naa gbe jade ni, ọmọde to to ẹgbẹrun mejilelogoji si ẹgbẹrun lọna ọgọta ni aisan naa n mulọ lorilẹede Naijiria ni ọdọọdun.

Atẹjade yii ni wọn fi lede ni Ọjọ Ayajọ Aisan otutu-aya lagbaye (World Pneumonia Day).

Wọn ni ohun to n fa ni aisi eto abẹrẹ ajẹsara fun awọn ọmọde, paapaa ni fun awọn ọmọde ti wọn bi si igberiko.

Aisi ounjẹ ati imọtoto naa wa lara ohun to mu ki aisan yii wọpọ laarin awọn ọmọde.

Bakan naa ni jijo igi ni igbo n ṣe akoba fun ọna ọfun, eleyii ti aisan yii ma n kọlu.

Ijọba ni bio tilẹ jẹpe awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn koju ọdun marun lọ naa n ku nitori aisan iba, ohun to ba ni lẹru ni wi pe aisan otutu-aya ṣi n pa awọn ọmọde ju aisan iba lọ nitori itọju tete wa fun aisan iba ju aisan otutu aya lọ.

Àkọlé fídíò, Sickle Cell In Nigeria: Makinde ní ìgbàgbọ́ ninú ìdílé òun ṣèdíwọ́ láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀

Ajọ to n risi ọrọ awọn ogo wẹẹre lagbaye, UNICEF ninu atẹjade sọ wi pe o kere miliọnu mẹrin o le ni awọn ọmọde ti aisan otutu aya n da ẹmi wọn legbodo ni Naijiria.

Nigba ti awọn ọmọde to le lẹgbẹgbẹrun miliọnu ni aisan naa mu ẹmi wọn lọ ni awọn orilẹede ti ọrọ aje wọn ko kẹsẹjari lagbaye.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Ajọ UNICEF fikun pe arun Coronavirus to tun wa lode ko jẹ ki ijọba o ibi ara si aisan otutu aya naa mọ, eleyii ti yoo mu ki ọpọlọpọ ṣe kongẹ aisan naa ni Naijiria.

Bakan naa ni wọn fikun pe arun Coronavirus naa yoo fi miliọnu kan o le kun awọn ogo wẹẹre ti arun otutu aya yoo mu lọ ninu ọdun 2020 yii.

Nitori naa ni wọn parọwa si ijọba lati pese abẹrẹ ajẹsara fun awọn ọmọde kaakiri orilẹede Naijiria, ki wọn si mu imọtoto ati omi mimọ ni ọkunkundun.