Child Right Act: Àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlá tí kò tíì ṣàmúlò òfin ẹ̀tọ́ àwọn èwe láti 2003 ní Nàìjíríà rèé

Oríṣun àwòrán, Child right Act/Twitter
Minisita ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin, Pauline Tallen, ti sọ pe ipinlẹ mọkanla ni ko tii bẹrẹ si n ṣamulo ofin to n dabo bo ẹtọ awọn ọmọde, eyii ti ile igbimọ aṣofin agba buwọlu lọdun 2003.
Pauline lo kede bẹẹ nibi ipade ita gbangba kan to waye ni ilu Abuja.
O ni lati igba ti oun ti de ipo minisita ni oun ti bẹrẹ si n kan si awọn gomina atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ki wọn le e bẹrẹ si n ṣamulo ofin naa.
- Àwọn orílẹ̀-èdè kan tún ti kéde kó nílé-ó-gbélé nítorí coronavirus
- Wo ìdí márùn-ún tí Biden fi bórí nínú ìdìbò ààrẹ America
- Agbẹjọ́rò wọ́ ìjọba lọ sílé ẹjọ́ pé kó yọ kéú kúrò lára owó Náírà
- Ìṣúná 2021 yóò ṣíjú ọ̀dọ́ kúrò nínú ìwá Yahoo-Yahoo - Sanwo-Olu
- Aṣaájú olùwọ́de EndSARS 50 dèrò iléẹ́jọ́ lórí ìfẹ̀hónúhàn àti ìdàlúrú
Pauline tẹsiwaju pe lootọ ni ipinlẹ marundinlọgbọn ti bẹrẹ si n ṣamulo ofin ọhun, ṣugbọn iná ipinlẹ mọkanla ṣi n jo ajorẹyin ni lilo rẹ.
O ni "Ko dun mọ mi ninu pe a ṣi ri ipinlẹ mọkanlan ti ko tii bẹrẹ si n lo ofin ọhun."
Minisita naa tẹsiwaju pe "Mo ṣẹṣẹ de lati Adamawa, Bauchi ati Gombe ni, wọn si ti fi da mi loju pe wọn yoo bẹrẹ si n ṣamulo ofin naa lẹyin ipade ti mo ṣe pẹlu awọn ile igbimọ aṣofin wọn."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ofin naa ṣe pataki nitori yoo gba ọpọlọpọ awọn ọmọde la lọwọ iku paapaa lasiko yii ti awọn ọmọ wẹwẹ wa ninu ewu ifipabanilopọ ati iwa ipa si awọn obinrin.

Oríṣun àwòrán, Child right act
O ni awọn iṣẹlẹ to waye lasiko ajakalẹ arun Covid-19 ti la ijọba loju si awọn ohun to lee ṣẹlẹ si awọn ọmọde ti ko lagbara lati gba ara wọn silẹ.
Minisita ọhun pari ọrọ rẹ pe Gbagbo pe gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria ni yoo bẹrẹ si ni ṣamulo ofin naa ko to di opin ọdun 2020.
















