Covid 19 Update: Àwọn orílẹ̀-èdè kan tún ti kéde kó nílé-ó-gbélé nítorí coronavirus

Covid

Oríṣun àwòrán, others

Àwọn orílẹ̀-èdè kan tún ti kéde kó nílé-ó-gbélé nítorí coronavirus

Orilẹ-ede Germany, lo kọkọ tun kede isede coronavirus nilẹ Europe, eyi to ti fa awuyewuye jakejado ilẹ naa.

Bi arun ọhun ṣe n ṣoro ni Europe, lo n pọ si ni America.

Eeyan to le ni miliọnu mẹrindinlaadọta ni arun coronavirus ti ràn ni agbaye. Àwọn to fẹ ẹ to miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba lo si ti kú.

Bo ṣe n pọ si ni America ati Europe, si ti n mu ki iporuru ọkan wá, nipa eto ọrọ aje agbaye to ti dẹnu kọlẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Lati le mu adinku ba itankalẹ rẹ, Olootu ijọba orilẹ-ede Germany, Angela Merkel, tun kede isede miran, bẹrẹ lati ọjọ Aje titi di ipari oṣu Kọkanla.

Bo tilẹ jẹ pe ko ni i si igbele, titi pa ni awọn ile oúnjẹ, ile igbafẹ, ile ọtí, ati sinima yoo wa.

Yatọ si Germany, orilẹ-ede England naa ti n gbaradi fun ofin konile-o-gbele tuntun, lẹyin ti awọn alasẹ Austria, France, ati Ireland, kede ti wọn.

Ọpọlọpọ lo si ti n foya, nitori ipa ti isede ọlọsẹ mẹrin ọhun yoo ni lara ọrọ aje.

Ofin konile o gbele to l'agbara yoo tun bẹrẹ lọjọ Aje ni Belgium.

Portugal naa si ti kede konile o gbele, bẹrẹ lati Ọjọru.

coronavirus

Oríṣun àwòrán, others

Ni France, Olootu ijọba, Jean Castex, sọ pe wọn yoo fi ofin de awọn ile itaja, lati ma ta àwọn nkan to ṣe koko, bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, lati le doola àwọn onile itaja keekeeke to ti ko gba wọlé.

Orilẹ-ede Spain ti kede isede alaalẹ, pupọ ninu awọn ẹkùn lo si ti ti ẹnu ibode wọn pa.

Ireti wa pe ijọba orilẹ-ede Italy naa yoo kede ilana tuntun lọjọ Aje.

Àkọlé fídíò, Shomolu gbajúmọ̀ fún ìwé títẹ̀