Àwọn ọmọ Nàìjíríà yarí lórí èròngbà ilé aṣòfin pé kí àjọ FRSC má a lo nkan ìjagun

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, paapa lori ayelujara Twitter, ti n bu ẹnu atẹ lu ipinnu ile igbimọ aṣoju-ṣofin, lati mu ki awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ ojupopo ma a lo ibọn.
Alaga igbimọ ajọ FRSC nile aṣofin naa, Akinfolarin Mayowa, lo sọ eyi nibi ipade agbeyẹwo owo iṣuna ọdun 2020, ati 2010, nilu abuja, pe awọn oṣiṣẹ ajọ Federal Road Safety Corps, FRSC, yoo bẹrẹ si ni lo nkan ija, lati le kapa aṣeju awọn awakọ l'orilẹ-ede Naijiria.
O ni "ofin ajọ FRSC, ti ọdun 1992, fi aaye gba awọn oṣiṣẹ ajọ na, lati maa lo nkan ija, ṣugbsn ofin naa ko jẹ lilo lati igba na".
- Wo èèyàn ogún tí ilé ẹ̀jọ́ sọ pé kí CBN gbẹ́sẹ̀ lé àsùnwọ̀n wọn ní bánkì nítorí ìwọ́de ENDSARS
- Ọkọ̀ táńkà agbépo tó gbiná lójú ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan dá súnkẹrẹ fàkẹrẹ sílẹ̀
- Àwọn ọmọ Nàíjíríà fèsì sí ìjọba àpapọ̀ tó ta Afam Power Plant
- A kò ní gba ẹnikẹ́ni láàyè láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn kankan mọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter
Pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria to sọrọ lori ayelujara lo n sọ pe o ṣe ni laanu pe awọn alaṣẹ n gbeero iru nkan bayii lasiko ti awuyewuye n waye lori iwakiwa ọpọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo.
Ẹnikan ni "iṣẹ gbooggi ti awọn oṣiṣẹ ajọ FRSCni kii ṣe mimojuto iwa ọdaran. Iṣẹ ọlọpaa ni, koda ọlọpaa gan-an ko gbọdọ ma a gbe ibọn kiri igbo ni gbogbo igba".

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ẹlomii, Samuel Mbah, sọ pe "ko si nkan ijagun fun awọn sọja ninu igbo Sambisam ṣugbọn ẹ fẹ ẹ fun FRSC nibọn?"

Oríṣun àwòrán, Busayo James-Olufade
Lara awọn to tun sọrọ lori iroyin naa ni gbaju-gbaja agbohunsafẹfẹ nipinlẹ Eko, Gbemi Olateru.
O sọ pe "fi fun awọn oṣiṣẹ ajọ FRSC ni ibọn kii ṣe nkan to dara. Ki lo de ti a ni awọn oṣiṣẹ alaabo to pọ to bẹ ẹ? LASTMa wa, VIO naa? Ṣe wọn o le ko wọn papọ ni i?

Oríṣun àwòrán, Busayo James-Olufade


















