EndSARS aftermath: Iléeṣẹ́ kò ní gba ẹnikẹ́ni láàyè láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn kankan mọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter/Babajide Sanwo-Olu
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣeleri pe ohun ko ni faye gba iwọde tabi ifẹhonuhan kan mọ kaakiri ipinlẹ naa.
Ikilọ yii jade lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn kan n gbero lati ṣe iwọde miran ki wọn le fi ẹhonu wọn han daadaa lori iwa ifiyajẹni awọn ọlọpaa, eto aabo to mẹhẹ ati iṣejọba ti ko rọ araalu lọrun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni idi ti ohun ko fi ni faye gba iwọde mii ni pe ipinlẹ Eko ko tii bọ ninu ofo ko laarọ to tẹle iwọde EndSARS to lọ.
- Nítorí pọpọ́ọ̀fù #200 ní Alaba ilé Sàlámàlékù ṣe da òróró gbígbóná sórí mi- Qudus
- A ó ṣèrànwọ́ fáwọn ẹbí ọlọ́pàá tó bá rògbòdìyàn EndSARS lọ láti inú N500m tí a yà sọ́tọ̀- Makinde
- Kàyééfì! Tọkọ taya kú lọ́jọ́ kan náà l'Abeokuta lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún méjìléláàdọ́rin 72
- Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.
- Sunny Ade (KSA) máa ń bá Orlando Owoh kó "Gloves" tó fi ń ja ẹ̀ṣẹ́ dání nígbà ayé rẹ̀- Folarin, àbúrò Orlando Owoh
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejobi fi sita ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ti fi to awọn leti pe awọn kan tun fẹ da rogbodiyan lati tẹsiwaju aawọ to ṣẹlẹ lasiko iwọde EndSARS.
''Idi eyi lo jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa maa kilọ fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kẹgbẹ kan to ba n gbero lati ṣe iwọde yala ifẹhonuhan wọọrọwọ tabi lile pe ileeṣẹ ọlọpaa atawọn eṣọ aabo mii ko ni gba fun wọn,'' Adejobi lo sọ bẹẹ.
O ni ẹnikẹni to gbimọ lati da alaafia ilu ru lasiko yii ti ipinlẹ ifẹhonuhan EndSARS ṣẹṣẹ lọọlẹ tan yoo jẹ iyan rẹ ni iṣu.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa kilọ fawọn obi ninu atẹjade naa lati kilọ fawọn ọmọ wọn pe ki wọn maa jẹ ki ẹnikẹni lo awọn ọmọ wọn fun ifẹhonuhan kankan nitori awọn janduku ni yoo ja iru iwọde bẹẹ gba.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Eko lati kọ eti ikun si ẹnikẹni to ba pe wọn si ibi iwọde kankan.
- A ti gbé ìwádìí dìde lórí ìpànìyàn tó wáyé lásìkò ìwọ́de EndSARS- Ilé ẹjọ́ àgbáyé, ICC
- Afẹ́fẹ́ gáàsì tí gbiná ní Ijora ìpínlẹ̀ Eko, bó ṣe n ṣẹlẹ̀ rèé
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Oyinkan Abayomi, akọni obìnrin tó fi ìfẹ́ pa orúkọ ọkọ kejì dà sí ti ọkọ àárọ̀















