Ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn l'àgbáyé, ICC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìpànìyàn tó wáyé lásìkò ìwọ́de EndSARS

EndSARS

Ile ẹjọ agbaye to n gbọ ẹsun iwa ọdaran, ICC, ti sọ fun BBC pe oun ti gbe iwadii dide lori ohun to ṣẹlẹ lasiko iwọde #EndSARS ni Naijiria.

Ninu atẹjade kan lati ọọfisi agbẹjọro rẹ, ile ẹjọ naa ni oun ti gba awọn iroyin kan nipa awọn iṣẹlẹ ifẹmiṣofo to waye nibi iwọde ọhun.

Wọn ni ayẹwo awọn yoo sọ boya awọn ṣe ẹjọ ọhun bii ẹjọ titẹ oju ẹtọ ara ilu mọlẹ, tabi iṣekupa ọpọ ero.

Fun nnkan bi ọsẹ meji ni awọn oluwọde fi fọ si igboro kaakiri Naijiria lati bere fun opin si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwa idigunjale, SARS, ki ijọba pana iwọde ọdhun.

Gẹgẹ bi ọrọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari sọ, ara ilu mọkanlelaadọta, ọlọpaa mọkanla ati ọmọ ologun meje ni ẹmi wọn sọnu nitori ifẹhonuhan naa.

EndSARS

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Amnesty International, sọ pe awọn ọmọ ologun Naijiria ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde ọhun lẹnu iloro Lekki Toll Gate, ti ọpọ ku, nigba ti awọn miran si farapa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣojumi koro sọ pe awọn ọmọ ileeṣẹ ologun Naijiria lo pa awọn eeyan naa, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ologun ti ni awọn ko mọwọ mẹsẹ ninu iṣẹlẹ ọhun.

ICC ti wa ni abajade iwadii oun yoo di mimọ fun gbogbo agbaye lati mọ ooto ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Orlando Owoh: Èmí àti Oladipupo Owomoyela jọ lọ ẹ̀wọ̀n Alágbọn- Caroline Owoh, aya Orlando