Coronavirus cases in Ngeria today: ₦50 bílíọ́nù ni a fún ìpínlẹ̀ kààkan ní Naijiria láti kojú àrùn Covid-19 - Ìjọba àpapọ̀

NCDC

Oríṣun àwòrán, @NCDCgov

Igbimọ amuṣẹya lori ọrọ Covid-19 ti ijọba apapọ gbe kalẹ, PTF, ti sọ pe awọn ipinlẹ kaakiri Naijiria ti gba owo ti iye rẹ ko din ni aadọta biliọnu naira lati koju arun naa.

Adari PTF, dokita Sani Aliyu lo kede bẹẹ nibi ipade awọn akọroyin to waye niluu Abuja.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iye to kere ju ti ipinlẹ kọkan gba lati koju Covid-19 ko din ni biliọnu kan naira.

O ni awọn ipinlẹ ni agbara lati koju arun naa nitori iye owo ti wọn ti gba lọwọ ijọba apapọ to ṣe nnkan.

Aliyu ni "a ti fun awọn ipinlẹ ni owo gọbọi lati koju Covid-19, ko sì sí ipinlẹ to gba owo ti iye rẹ kere ju biliọnu kan naira lọ."

NCDC

Oríṣun àwòrán, @NCDCgov

O tẹsiweaju pe "Bi a ṣe n sọrọ lọwọ yii, 50 biliọnu ni a ti fi ranṣẹ si gbogbo ipinlẹ ni Naijiria ati Abuja, nitori naa, a ní gbogbo nnkan ti yoo gba lati le Coronavirus jina si awujọ wa."

Àkọlé fídíò, Orlando Owoh: Èmí àti Oladipupo Owomoyela jọ lọ ẹ̀wọ̀n Alágbọn- Caroline Owoh, aya Orlando

Dokita ọhun ni afujusun ijọba apapọ ni lati ri daju pe arun Covid-19 di ohun igbagbe ni Naijiria.

Lẹyin naa lo ni ijọba apapọ yoo tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ijọba ipinlẹ lati lo owo naa gẹgẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

Aliyu pari ọrọ rẹ pẹlu arọwa pe ki awọn ijọba ipinlẹ má na owo naa si awọn nnkan miran bi ko ṣe lati koju Coronavirus nikan.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa lórí BBC Yorùbá: Mọ̀ síi nípa ẹ̀kún ìyàwó níbí