UTAS, ASUU, IPPIS, FGA kó ní sanwó oṣú ASUU láìjẹ́ pé wọ́n gba IPPIS- Ìjọba Àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, @Unilag
Ijọba Apapọ ti ni, ibi ti oun wa lori ọrọ sisanwo owo oṣiṣẹ ijọba ninu asunwọn kan naa (IPPIS) loun duro si paapaa julọ lori sisan owo oṣu awọn olukọ fasiti
Minisita isuna, Zinab Ahmed salaye pe IPPIS ni awọn yoo maa lo titi eto UTAS ti awọn fasiti n se yoo fi yanju.
Minisita sọ ọrọ naa niwaju igbimọ tẹẹkoto lori ọrọ isuna nile igbimọ asoju sofin nilu Abuja.
Saaju ni awọn ẹgbẹ ASUU ti gba lati se agbe dìde UTAS ti o fi ara pẹ IPPIS ti wọn si rọ ijọba lati gba wọle fun sisan owo awọn olukọ fasiti.
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo jáwée lọ sinmi nílé fún alága ìgbìmọ̀ mẹ́tàlá káàkiri ìjọba ìpínlẹ̀
- Wo ọ̀nà àbáyọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àjọ WAEC gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò wọn
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, tó ń kojú Trump nínú ìbò America
- 'Ìdí tí kámẹ́rà táa rí ní Lekki Tollgate kò fi ká gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé rè é'
Ni ana ode yii ni ẹgbẹ ASUU ni iyansẹlodi awọn olukọ to n lọ lọwọ yii nikan lọna abayọ lati ri daju pe ijọba ko doju awọn ile ẹkọ fasiti Naijiria bọlẹ patapata.
Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ, ni olu ile ẹgbẹ ASUU ni Fasiti Olabisi Onabanjo Ago Iwoye nipinlẹ Ogun ni adari ẹkun Eko ọjọgbọn Olusiji Sowande sọ pe ijọba apapọ jẹ awọn fasiti ni owo ti le ni igba biliọnu naira fun atunto awọn fasiti.
O ni kaka ti ijọba yoo fi wa ọna abayọ si isoro yii, o tẹwọn lọrun ki awọn akẹkọọ wa nile titi di ọdun to n bọ.
O ni nkan to ku ti ijọba n ṣe ni lati ba ẹgbẹ ASUU lorukọ jẹ, idunkoko mọni ati pipa irọ fun ara ilu lati ri ẹgbẹ ASUU bi alaseju.
Sowand ni ASUU o ni yẹba kuro lori ipinu rẹ titi yoo fi gba gbogbo nkan to to fun atunto awọn ile ẹkọ ijọba apapọ jakejado Naijiria.
Ẹgbẹ ASUU ni a fi dandan ki awọn tun adehun se lori ifẹnuko wọn ti se lọdun 2009 laarin ijọba ati ASUU, bi wọn se n ṣe owo oṣiṣẹ mọwọ ati awọn owo miran to tọ si wọn, yiyan awọn igbimọ abẹwo si fasiti
O rọ ara ilu ati awọn tọrọkan ni Naijiria lati ba ijọba Naijiria sọrọ nibi ti wọn ti n gbọ ki wọn le di opin si ọrọ iyanṣẹlodi yii. Osu Keje ree ti awọn akẹkọọ ti wa nile.
- Wo àfipábánilòpọ̀ ẹni ọdún 51 tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tú làṣirí ní gbangba
- "Àwọn sójà ní mo káàbò sí ilé ìṣerun àgbáyé tí wọ́n tí ń ṣerun bó ṣe wu wọ́n"
- Sanitáísa leé ba ìwé ìtẹ̀ka ìbò jẹ́ - Àjọ CDC kìlọ̀
- Ẹ fún wa lówó oṣù wa tàbí kí a gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ- Àwọn dokita ìpínlẹ̀ Ondo
- Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin he lẹ́yìn tó jí ẹ̀rọ ìléwọ́ iPhone ní ìpínlẹ̀ Ogun
















