EndSARS Protes Updatet: Aláàfin Ọyọ ní ọ̀dọ́ ìwòyí kò gba gbẹ̀rẹ́, kíjọba yé halẹ̀ mọ́ wọn

Alaafin Oba Adeyemi III

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alaafin Oba Adeyemi III

Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi ti parọwa si ijọba lati jawọ ninu idukoko mọ awọn ọdọ lẹyin ti wọn ṣe ifẹhọnuhan EndSars ni oṣu to kọja.

Alaafin Oyo sọ eyi lasiko ti awọn gomina ni iwọ-oorun Naijiria, awọn minisita, awọn lọbalọba ni ilẹ Yoruba ṣe ipade pẹlu asoju Muhammadu Buhari. Ọjọgbọn Ibrahim Gambari.

Ipade naa waye lati jiroro lori ọna abayọ si eto aabo to dẹnukọlẹ lorilẹede Naijiria, lasiko ti awọn ọdọ ṣe ifẹhọnuhan tako ifiyajẹni lati ọwọ awọn ọlọpaa.

Ọba Adeyemi ni ko yẹ ki ijọba ma a dukoko mọ wọn, o yẹ ki ijọba fawọn mọra lati gbọ ẹdun ọkan awọn ọdọ ni.

Alaafin Oba Adeyemi III

Oríṣun àwòrán, acebook/Alaafin Oba Adeyemi III

'' Ijọba yẹ ko lo akoko yii lati fi gbọ ohun ti awọn ọdọ nii sọ, ki iru iṣẹlẹ to waye lasiko ifẹhọnuhan EndSars ma ba tun waye.''

''Ijọba gbọdọ woye pe igba yii yatọ si ọgbọn ọdun sẹyin, ti ijọba le e ṣe ohun to wu wọn, ti ko si si ẹni ti yoo beere lọwọ wọn.''

''Awọn ọdọ aye ode oni mọ ẹtọ wọn, wọn si n lo ẹrọ ayelujara lati fi aiṣedede ijọba han si gbangban''

''Nitori naa ni ijọba ṣe gbọdọ lo asiko yii lati fi pẹtu si awọn ọdọ ninu, kii ṣe ki wọn dukoko mọ wọn, tabi gbegile apo owo wọn ni banki, nitori ko bojumu.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi ni o ṣeni laanu pe awọn kan lo ifẹhọnuhan naa lati da rogbodiyan silẹ, ati ija ẹlẹyamẹya.

Ọba Adeyemi ni awọn dukia ẹya Yoruba nikan ni wọn bajẹ lasiko ifẹhọnuhan to waye ni ipinlẹ Eko, eleyii ti o le jasi ija ẹlẹyamẹya.

Alaafin ilu Oyo

Oríṣun àwòrán, others

O ni ki ijọba pada si bi iṣejọba ṣe wa ni saa isejọba tiwantiwa akọkọ lorilẹede Naijiria, ti ẹkun kọọkan n bojuto iṣejọba ara wọn, eleyii to jasi idagbasoke fun ilẹ Yoruba nigba naa.

Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi fikun wi pe, ki awọn lọbalọba ri wi pe alaafia jọba ni agbegbe wọn nitori ipa ti oun ko lasiko ifẹhọnuhan naa ni ko jẹ ki o jasi rogbodiyan ni agbegbe oun.

Oba Adeyemi ni oun ko awọn ẹsọ sita lati ma ṣe fun awọn janduku laaye lati ṣekọlu si awọn agọ ọlọpaa lasiko ifẹhọnuhan EndSars naa.

Bakan naa ni Alaafin ilu Oyo ni oun fun awọn to ji awọn nkan gbe lasiko naa ni gbedeke lati da wọn pada, eleyii ti o ni wọn tẹle to si jẹ ki alaafia jọba ni ipinlẹ Oyo.

Ọ̀rọ̀ ìjókòó ìgbìmọ̀ ìwádìí #EndSARS náà dé ìpínlẹ̀ Ogun

Ijoko akọkọ igbimọ iwadii lori iwa ifiyajeni eyi ti ijoba ipinlẹ Ogun gbe kalẹ yoo bẹrẹ lọjọ karun un, oṣu Kọkanla tii ṣe ọjọbọ.Igbimọ naa yoo maa gbọ ẹsun t'awọn eeyan ba gbe wa siwaju rẹ ni gbogbo ọjọ Aje, Ọjọru ati Ọjọbọ ni ile ẹjọ majisireti to wa ni Isabo Abeokuta.

Ogun

Oríṣun àwòrán, @OGSG

Atejade kan ti akọwe igbimọ naa Arabinrin Oluwatosin Ogundele fi sita ni igbẹjọ yi ko ni fi igba kan bọkan ninu ti yoo si mọlẹ kedere fara ilu.

Kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria ni irufẹ igbẹjọ yi ti n waye ni idahun si ipe arailu si iwa aitọ t'awọn agbofinro paapa ikọ SARS n hu si ara ilu.

Àkọlé fídíò, Orlando Owoh: Èmí àti Oladipupo Owomoyela jọ lọ ẹ̀wọ̀n Alágbọn- Caroline Owoh, aya Orlando