Alaafin Oyo: Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Oyo táwọn èèyàn fi ń ki Alaafin ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?

Alaafin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alaafin Oba Adeyemi III

Ẹni ọdun ba laye, o yẹ ko ṣọpẹ. Ọgọọrọ eeyan lo ti n ki Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta ku ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejilelelọgọrin loke eepẹ.

Lara awọn ọtọkulu to ti Alaafin ku ayẹyẹ ọjọ ibi ni oludije fun ipo gomina ipinlẹ Oyo fẹgbẹ oṣelu ZLP ninu idibo gbogbo ọdun 2019, Oloye Sharafadeen Alli.

Oloye Alli ni Oba Adeyemi yatọ ninu awọn ọba alaye nilẹ Yoruba nipa gbigbe aṣa ati iṣe Yoruba larugẹ.

Ninu iṣẹ ikini to fi ranṣẹ si baba, Oloye Alli sọ pe Alaafin jẹ ọba to n lepa alaafia, idagbasoke ati ilọsiwaju ilẹ Yoruba to fi mọ gbogbo orilẹede Naijiria.

O ni ko si ẹni ti ko mọ pe aṣaaju ni Alaafin ninu igbelarugẹ aṣa Yoruba nile, loko, lẹyin odi ati kaakiri gbogbo agbaye tawọn ọmọ Yoruba wa.

Bakan naa lo lu Oba Adeyemi lọgọ ẹnu lori ipa ti o n ko lati rii wi pe iran Yoruba ko gbẹyin lorilẹede Naijiria.

O gbadura pe ki Eledua fi ẹmi gigun ati alaafia ara jinki baba bi wọn ti pe ẹni ọdun mejilelọgọrin loke eepẹ.

Alaga ajọ to ri si eto ibaraẹnisọrọ ni Nigeria Communications Commission, NCC, Ọjọgbọn Adeolu Akande naa ko gbẹyin ninu awọn to n ki Oba Alaafin ku ọdun ọjọ ibi wọn.

Ọjọgbọn sọ pe ninu awọn ọlọgbọn eeyan ni Alaafin, koda o ni ẹbun nla ni Oba Adeyemi jẹ fun ilẹ Afirika.

O ni ọpọ igba ni Kabiyesi Adeyemi ti ba oun sọrọ ọgbọn laafin Oyo nigba nigba ti oun fi jẹ akọroyin fun ileeṣẹ iroyin Tribune.

Àkọlé fídíò, EndSars, EndSwat: Ọlọ́pàá ti fi ìbọn lù mí láyà rí torí mó ní 'extra tyre' méjì- afẹ́hònúh

Ọjọgbọn Akande ni anfaani lo jẹ fun oun pe oun naa bu mu ninu omi ọgbọn Alaafin.

Oun naa gbadura ilera to peye ati ẹmi gigun fun Kabiyesi Alaafin.

Àkọlé fídíò, Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní