Petrol tanker accident: Èèyàn méjì àti ọkọ̀ 29 ló jóná níbi ìṣẹ̀lẹ̀ táńkà agbépo tó gbiná ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan

Ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC to ṣalaye ni kiku ohun to ṣe okunfa ijamba ọkọ agbepo bẹntiro to ṣẹlẹ loju ọna mọrosẹ ilu Eko si Ibadan.
Ninu atẹjade ti ajọ FRSC fi sita, alukoro ajọ naa Bisi Kazeem ṣalaye pe taya tanka naa lo fọ lori ere eyi to mu ṣubu ti o si gbina.
Ọgbẹ Kazeem tun fidi rẹ mulẹ pe eeyan meji lo ba iṣẹlẹ naa lọ nigba ti ọkọ mọkadinlọgbọn ti wọn gbe si ẹgbẹ titi jona raurau.
- Bí ọwọ́jà ìjọba mi kò bá tíì dọ́dọ̀ yín, ẹ ṣe sùúrù pẹ̀lú wa- Ààré Buhari bẹ̀bẹ̀
- Nígbà tí mo dàgbà ní mo rí i pé oore ńlá ní Olorun ṣe mi pẹ̀lú aàbọ̀ ara mi- Bose Okeowo
- Afẹ́fẹ́ gáàsì tí gbiná ní Ijora ìpínlẹ̀ Eko, bó ṣe n ṣẹlẹ̀ rèé
- Nítorí pọpọ́ọ̀fù #200 ní Alaba ilé Sàlámàlékù ṣe da òróró gbígbóná sórí mi- Qudus
Ajọ FRSC tun fikun ọrọ rẹ ninu atjade naa pe awọn janduku kan kọju ija sawọn ẹṣọ oju ọna atawọn panapana pẹlu oriṣiiriiṣi ohun ija oloro.
''Niṣe lawọn ẹṣọ oju ọna atawọn panapana sa asala fun ẹmi wọn lọ si agọ ọlọpaa to wa ni tosi ni Isheri.
Ọga agba ajọ FRSC, Ọmọwe Boboye Oyeyemi bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, @Stanley
Ọmọwe Oyeyemi ni ajọ FRSC n ṣe akitiyan lati bawọn tọrọ kan sọrọ ki opin le de ba awọn ọkọ tanka agbepo to n gbina loju ọna kiri.
Ajọ FRSC ti wa sọ fawọn araalu pe lilọ bibọ ọkọ ti n ja geere bayii loju ọna mọrosẹ Eko si Ibadan lẹyin tawọn ti ko awọn ọkọ to jona ninu iṣẹlẹ ọhun kuro loju popo.
Ajẹ eṣọ oju popo ti wa rọ awọn awakọ loju ọna ọhun pe ki wọn ṣe jẹjẹ loju popo.
Ọkọ̀ táńkà agbépo tó gbiná lójú ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan dá súnkẹrẹ fàkẹrẹ sílẹ̀
Sunkẹrẹ fakẹrẹ ti di ọna mọrosẹ ilu Eko si Ibadan pa lẹyin ti ọkọ tanka agbepo bẹntiro kan gbina loju popo naa.
Agbegbe afara Kara loju ọna Eko si ilu Ibadan ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

Iroyin ti a gbọ ni pe ina ọhun si n jo to fi di deedee aago kan oru ọjọ Abamẹta, ọjọ keje oṣu kọkanla ọdun 2020 lai si awọn oṣiṣẹ panapana nibẹ.
Awọn ero ti wọn n rinrin ajo kuro niluu Eko ni iṣẹlẹ ọhun ti dena mọ lẹyin ti wọn ko ri ọna kọja.
Ẹni to wa nibi iṣẹlẹ naa sọ pe ọpọ awakọ ti n kuro loju popo wọn ti wọn si kọju si awọn to n bọ wa si ilu Eko eleyi ti wọn n pe ni ''one way.''
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.













