Nazir Sarkin Waka: 'Mo ṣetán láti lo gbogbo ayé mi tókù lẹ́wọ̀n'

Oríṣun àwòrán, Nazir Sarkin Waka
'Mo ṣetán láti lo gbogbo ayé mi tókù lẹ́wọ̀n'
Arakunrin olorin ọmọ Naijiria kan, Nazir Sarkin ti ni oun ṣetan lati lo gbogbo igbesi aye oun lẹwọn nitori ohun to gbagbọ.
O jẹ ohun ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ ko ni fẹ gbọ seti ṣugbọn gbajugbaja olorin ọmọ iha Ariwa Naijiria naa, Nazir Ahmed ti ọpọlọpọ mọ si Sarkin Waka ti lo wakati mẹrinlelogun bayii ni ọgba ẹwọn Kurmawa ni ipinlẹ Kano.

Oríṣun àwòrán, @Nazir
Ni ọjọbọ ni ile ẹjọ kan ni Kano dajọ pe ki wọn gbe olorin naa lọ si ẹwọn titi yoo fi le ṣe ohun ti wọn bere fun gẹgẹ bii beeli rẹ.
Iṣoro ti Sarki Waka ni jẹ pẹlu ajọ to n bojuto aṣẹ gbigba lorii awọn orin ati ere sinma to n jade latari awo orin meji to gbe jade lai gba lansẹẹsi lọwọ wọn iyẹn "Gidan Saratu ati "Sai Hakuri".
Ṣugbọn awọn eeyan ni toriipe o bu ẹnu atẹ lu iṣesi gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ninu ọkan ninu awọn orin naa ti awọn olorin mii naa si bẹrẹ si ni ṣe ohun to ṣe.
Bi wọn ṣe n gbe e lọ sẹwọn lo sọ ọrọ sorii Whatsapp to si ka ohun ara rẹ silẹ pe oun ṣetan lati lo gbogbo aye oun lẹwọn fun ohun ti oun gbagbọ ninu rẹ.
Aburo rẹ toun funrarẹ jẹ olootu to n gbe ere sinima sita ba BBC sọrọ pe ohun to wa nidi ọrọ yii gangan ni pe ijọba kanlẹ ni nkan lodi si Sarkin Waka ni biko ṣe bẹẹ, ko yẹ ki eyi ṣẹlẹ.
Ibi ti gbajugbaja olorin yii ti gba orukọ rẹ, Sarkin Waka eyi to tumọ si "Ọba Orin" wa latọdọ Emir ana ipinlẹ Kano, Sanusi Lamido Sanusi.
Wọn ni orin naa ti jade to si ti n tan ka ki Ganduje to di gomina.
Aminu ni awọn yoo tẹsiwaju lati maa ja fun Nazir ki wọn le tu u silẹ.
Koda o ni awọn fẹ ṣe lara ohun ti ileẹjọ beere fun ni Ọjọbọ ṣugbọn adajọ ti kuro nile ẹjọ nigba naa.
Ọkan lara ohun ti wọn beere fun ni ki wọn wa ọgagun Hisbah kan lati ijọba ibilẹ Kano to ba wu wọn eyi ti wọn si ti ṣe.
O sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo pe nigba ti wọn kọkọ mu Sarkin Waka nibẹrẹ ọdun yii, alaga ajọ to n fun awọn olorin ati elere ni lansẹẹsi ni ko si ọwọ oṣelu kankan ninu ohun to ṣe bikoṣe riru ofin.
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Afẹ́fẹ́ gáàsì tí gbiná ní Ijora ìpínlẹ̀ Eko, bó ṣe n ṣẹlẹ̀ rèé
- Oṣú mẹ́fà ni òṣìṣẹ́ ìjọba tó bá bímọ yóò máa lò nílé kó tó wọṣẹ́ padà- Seyi Makinde
- A ti gbé ìwádìí dìde lórí ìpànìyàn tó wáyé lásìkò ìwọ́de EndSARS- Ilé ẹjọ́ àgbáyé, ICC

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigeria Police Force
'Àwọn ọlọ́pàá tó farapa nínú ìwọ́de EndSARS yóò gba ìgbéga, a ó ṣèrànwó f'ẹ́bí àwọn tó kú'
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe koriya fun awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria, eyi wa lara ohun ṣuyọ lẹyin rogbodiyan to tẹle ifẹhonuhan #EndSARS.
Ọga agba ọlọpaa ni Naijiria Mohammed Adamu lo ṣalaye pe gbogbo ẹbi ọlọpaa to ba rogbodiyan iwọde EndSARS lọ nijọba yoo ṣeranwọ fun.
Ọgbẹni Adamu tun ni awọn agbofinro to farapa ninu iṣẹlẹ naa yoo gba igbega lẹnu iṣẹ.
Niluu Benin nipinlẹ Edo ni Adamu ti sọrọ yii nigba to ṣabẹwo si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Benin.
Ọga agba ọlọpaa tun ṣabẹwo si awọn agọ ọlọpaa ti awọn janduku kan dana sun niluu Benin.
- Wo àfipábánilòpọ̀ ẹni ọdún 51 tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tú làṣirí ní gbangba
- Oyinkan Abayomi, akọni obìnrin tó fi ìfẹ́ pa orúkọ ọkọ kejì dà sí ti ọkọ àárọ̀
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Oṣú mẹ́fà ni òṣìṣẹ́ ìjọba tó bá bímọ yóò máa lò nílé kó tó wọṣẹ́ padà- Seyi Makinde
Agọ ọlọpaa meje ati ọpọ ọkọ tawọn ọlọpaa fi n ṣiṣẹ ni wọn dana sun lasiko rogbodiyan to bẹ silẹ lẹyin ifẹhonuhan EndSARS.
''Ijọba ko gbagbe awọn ọlọpaa ni Naijiria. Ọpọ atunṣe lo n lọ lọwọ lati rii pe awọn agbofinro gbaye gbadun,'' ọga ọlọpaa lo sọ bẹẹ.
Adamu ni awọn ọlọpaa to ti fẹhinti lẹnu iṣẹ gan an yoo ri owo ifẹyinti wọn gba.
O ni oun n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ to n ri si ọrọ ọlọpaa lati rii pe gbogbo eto yii di ṣiṣe.
- Diego Maradona ṣiṣẹ́ abẹ lórí ẹ̀jẹ̀ tó dì sí i lọ́pọlọ lẹ́yìn ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún
- Àlàyé rèé lóríi ìdí tí wọ́n fi ń pe aya ní ìyàwó
- Ẹ wo ẹyẹ ayékòótọ́ tó kó olówó rẹ̀ yọ lọ́wọ́ ikú gbígbóná
- Ọ̀rọ̀ ìjókòó ìgbìmọ̀ ìwádìí #EndSARS náà dé ìpínlẹ̀ Ogun
- Àwọn agbébọn kọlu iléèwé, wọn bọ́ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò














