Somalia rape death sentence: Ìdájọ́ ikú ló bá dé fáwọn méjì tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lò pọ̀

ifipabanilopo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ kan ni agbegbe Puntland lorileede Somalia ti dajọ iku fawọn okunrin meji kan.

Ẹsẹ ti adajọ tori rẹ ni ki wọn yẹgi fun wọn ni pe wọn fipa ba ọmọdebinrin ọdun mẹrinla kan lo pọ ti wọn si tun ṣeku pa a.

Mohamed Abdi Faray ati Abdirahman Mohamed Isaq jẹwọ iwa ọdaran yi leyin ti wọn ji ọmọdebinrin yi gbe ni ilu Bosaso ni ibẹrẹ ọdun yi.

Lẹnu lọọlọ yi, iwa ifipabanilopo iru eleyi ṣebi ẹni peleke kaakiri Somalia.

Awọn ọlọpaa n ṣe iwadii lọwọ lori awọn irufẹ ẹsẹ yi.

Ninu rẹ leyi ta ti gbọ pe awọn kan korajọ fipaba ọmọbìnrin ẹni odun mọkandinlogun kan lopọ ti wọn si re bọ lati oke ile alaja mẹfa ni Mogadishu loṣu Kẹsan an.