SWAT: Ìpínlẹ̀ Osun àti Nasarawa ni ẹ̀kọ́ ìgbáradì SWAT ti n wáyé

Gbagbagba ni ibudo àwọn agbofinro wà ní ní ilé ẹ̀kọ́ Olopaa tó wà ní Egbon, Ìpínlẹ̀ Nasarawa.
Àwọn aláṣẹ iléese ọlọ́pàá ṣe agbekale iko SWAT eyi to tumọ si Special Weapons and Tactics Unit ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 lati fi rọpo ikọ SARS.
Eyi waye lẹyin ti wọn tu wọn ka pe ki wọn ma ṣiṣẹ mọ lasiko iwọde EndSARS jakejado Naijiria iyẹn Special Anti-robbery Squad.
Eyi waye lẹyin ti awọn ọdọ Naijiria tu sigboro lati ja fun ki ijọba fi opin si iṣẹ awọn ikọ SARS ati iwa aidaa ti awọn ọlọpaa n hu si awọn araalu.
Ọga agba patapata awọn ọlọpaa, Muhammed Adamu sọ pe awọn ọlọpaa SWAT yoo bẹrẹ ẹkọ igbaradi ni kete ti wọn ba ti kede akojọ wọn lọsẹ to n bọ.
Awọn ikọ naa lati ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Guusu-Ila Oorun ati ẹkun Guusu-Guusu yoo ṣe ẹkọ igbaradi tiwọn ni ile ẹkọ igbogun ti iwa idunkoko mọ ni to wa ni Nonwa-Tai, ipinlẹ Rivers.
Awọn to ba wa lati ẹkun ariwa ati Guusu-Iwọ Oorun yoo ṣe tiwọn ni ile ẹkọ ọlọpaa Mopol to wa ni Ende, Nasarawa ati ni ile ẹkọ awọn ọlọpaa to wa ni ilu Ila Oragun, ipinlẹ Osun.
Ọfisa SWAT meloo lo wa ni Nasarawa?
Eeyan ẹẹdẹgbẹta o le aadọta lo wa fun iṣẹ naa ṣugbọn lẹyin ayẹwo ọpọlọ ati ilera, wọn yọ awọn igba o le ọgbọn kuro ti irinwo le ogun si yege.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ mẹtala ni ẹkọ igbaradi wọn yoo ti waye.
- Ẹ fún wa lówó oṣù wa tàbí kí a gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ- Àwọn dokita ìpínlẹ̀ Ondo
- Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin he lẹ́yìn tó jí ẹ̀rọ ìléwọ́ iPhone ní ìpínlẹ̀ Ogun
- ₦50 bílíọ́nù ni a pín fún gbogbo ìpínlẹ̀ ní Naijiria láti kojú àrùn Covid-19- Ìjọba àpapọ̀
- Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ọkọ̀ akérò tó ṣekúpa ọlọ́kadà ní Ibadan
- Oṣú mẹ́fà ni òṣìṣẹ́ ìjọba tó bá bímọ yóò máa lò nílé kó tó wọṣẹ́ padà- Seyi Makinde
Iru ẹkọ igbaradi wo gan an ni wọn n ṣe?
Koo to le darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa Naijiria, o gbudọ la ẹkọ igbaradi to gboro kọja.
Ohun taa gbọ ni pe igbaradi ti awọn ọlọpaa SWAT gan le ju toripe ati ti imọ ẹkọ ati ti iṣẹ ni wọn n ṣe papọ.

Wọn kọ wọn bi wọn ṣe n yinbọn ati lilo awọn nkan ijagun mii.
Ọsẹ mẹta gbako ni ẹkọ igbaradi wọn lẹyin rẹ si ni wọn o pin wọn kaakiri sẹnu iṣẹ wọn.
- A kó ní sanwó oṣú ASUU láìjẹ́ pé wọ́n gba IPPIS- Ìjọba Àpapọ̀
- Diego Maradona ṣiṣẹ́ abẹ lórí ẹ̀jẹ̀ tó dì sí i lọ́pọlọ lẹ́yìn ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún
- A ti gbé ìwádìí dìde lórí ìpànìyàn tó wáyé lásìkò ìwọ́de EndSARS- Ilé ẹjọ́ àgbáyé, ICC
- Oyinkan Abayomi, akọni obìnrin tó fi ìfẹ́ pa orúkọ ọkọ kejì dà sí ti ọkọ àárọ̀
Ṣe wọn yọọ ni ẹwu idanimọ?
Gẹgẹ bi ṣe gbọ, ikọ tuntun yii yoo ni oniruuru ẹwu ti wọn yoo maa wọ.
Ọga agba ọlọpaa nigba to ṣe ibẹwo si wọn sọ fun wọn pe ki opo ibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lo se pataki julọ ninu ninu iṣẹ wọn.
Ati pe gbogbo ẹkọ igbaradi wọn wa lati rii pe wọn koju iṣoro janduku atawọn iwa ọdaran mii to n gbogo lorilẹede Naijiria.

















