Tinubu fún Makinde ní N50bn owó ìrànwọ́ lásìkò ìbúgbàmù Bodija, èròńgbà rẹ̀ láti di ààrẹ ló ń pín PDP yẹ́lẹyẹ̀lẹ - Fayose

Ayo Fayose wọ aṣọ buba, o si fọwọ lẹran, Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo n sọrọ pẹlu gbohungbohun lori ijokoo

Oríṣun àwòrán, Peter Ayo Fayose/X/Seyi Makinde/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayo Fayose, ti sọ fun Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo wi pe o ni lati sọ fun gbogbo ọmọ Naijiria wi pe o gba iranwọ aadọta biliọnu naira (N50bn) lati ọwọ Aarẹ Bola Tinubu lasiko iṣẹlẹ ibugbamu to wo ọpọ ile lulẹ lagbegbe Bodija niluu Ibadan.

Fayose sọrọ yii lori eto kan to waye nileeṣẹ tẹlifisan TVC niluu Eko.

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ni loootọ ni Tinubu ko fun Makinde lanfaani lati fa eeyan kalẹ fun ipo minisita, amọ, o ni gomina ipinlẹ Oyo ri awọn anfaani miran jẹ lati ọdọ Tinubu.

''Nnkan ti Makinde sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe ni pe Tinubu ni koun lọ ṣagbatẹru ifẹsẹmulẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, ṣugbọn oun kọ.

Amọ, Makinde ko sọ fawọn eeyan pe aarẹ foun ni N50bn nigba ti iṣẹlẹ ibugbamu to waye ni Bodija sọ ọpọ araalu di alainilelori n'Ibadan.

Mo ni ẹri to daju fun nnkan ti mo n sọ yii, to ba si jẹ pe iro ni mo n pa, mo fẹ ki Makinde wa sọ fun araye.

Nitori naa, bi Makinde ṣe n bu ẹnu ẹtẹ lu aarẹ ati ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣelu PDP, bakan naa lo yẹ ko maa ṣalaye fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo awọn iranwọ ati anfaani to n ri gba.''

Fayose ni nnkan to n fa faakaja laarin Makinde ati Nyesom Wike ati oun naa ni erongba Makinde lati dupo aarẹ Naijiria.

Gomina ipinlẹ Ekiti fikun ọrọ rẹ pe oun ti beere lọwọ Makinde nipa awọn to n pin iwe ilewọ kiri fun ipolongo ibo aarẹ fun un.

O ni idahun Makinde ni pe irọ nla ni ọrọ naa wi pe owo lawọn eeyan ọhun n wa.

Fayose ni gbogbo laaṣigbo to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ osẹlu PDP ko ṣẹyin erongba Makinde lati dupo aarẹ.

Makinde lo ba ẹgbẹ oṣelu PDP jẹ lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria - Fayose

Gomina ipinlẹ Ekiti tun fẹsun kan Makinde wi pe oun lo n ṣi agbara lo, ati pe oun lo n ba ẹgbe oṣelu PDP jẹ lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Fayose ni gbogbo awọn eeyan to ṣiṣẹ fun Makinde to fi di gomina lo ti gbe ti sẹgbẹ kan.

Bakan naa ni Fayose tun fẹsun kan gomina ipinlẹ Oyo wi pe oun naa ni ko jẹ ki ẹgbẹ PDP duro daadaa mọ kaakiri awọn ipinlẹ Yoruba.

O ni Makinde naa lo kọ awọn eeyan kan wi pe ki wọn tako oun nipinlẹ Osun.

Fayose ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bii agba oṣelu to mọ nnkan to n ṣe, o ni ọdun mẹjọ loun fi ṣakoso ipinlẹ Ekiti lai si ẹnikan kan to n la le oun lọwọ lati ibikibi.

O ni oun ko ni baba isalẹ kankan titi ti oun fi ṣe ijọba oun tan gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ekiti.

Fayose tun fidi rẹ mulẹ wi pe oun ko le kuro ninu ẹgbẹ PDP lailai darapọ mọ APC.

Nibi ti Wike ba wa ni emi naa wa - Fayose

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ tun fikun ọrọ rẹ pe ninu ẹgbẹ oṣelu ti minisita Abuja, Nyesom Wike, ba wa loun yoo wa.

Nigba to n ṣalaye wi pe oun ko le darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lailai ni Fayose fidi rẹ mulẹ pe, nibi ti Wike ba n lọ lagbo oṣelu loun naa n lọ.

Fayose wa lara ẹgbẹ G-5 tawọn Wike ati Makinde ṣagbatẹru rẹ ninu PDP lati ṣatilẹyin fun oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu mii yatọ si PDP ninu idibo aarẹ ọdun 2023.

Awọn to wa ninu igun G-5 pinnu lati ṣiṣẹ tako Atiku Abubakar to jẹ oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2023 tori a tako eto pinpin oludije nipasẹ ẹlẹkunjẹkun.

Fayose pẹlu Wike, Gomina Makinde, ati gomina Enugu tẹlẹ Ifeanyi Uguwanyi ṣiṣẹ fun Aarẹ Tinubu to jẹ oludije aarẹ fẹgbẹ oṣelu APC lasiko ibo aarẹ ọdun 2023 dipo Atiku.